Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Ìfihàn

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Ìfihàn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù (1-3)

    • Ìkíni sí àwọn ìjọ méje (4-8)

      • “Èmi ni Ááfà àti Ómégà” (8)

    • Jòhánù wà ní ọjọ́ Olúwa nípasẹ̀ ìmísí (9-11)

    • Ìran Jésù tí a ṣe lógo (12-20)

  • 2

    • Iṣẹ́ tó rán sí Éfésù (1-7), Símínà (8-11), Págámù (12-17) àti Tíátírà (18-29)

  • 3

    • Iṣẹ́ tó rán sí Sádísì (1-6), Filadéfíà (7-13) àti Laodíkíà (14-22)

  • 4

    • Ìran nípa bí ìtẹ́ Jèhófà ṣe rí lókè ọ̀run (1-11)

      • Jèhófà jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ (2)

      • Àwọn àgbààgbà 24 wà lórí ìtẹ́ (4)

      • Ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà (6)

  • 5

    • Àkájọ ìwé tó ní èdìdì méje (1-5)

    • Ọ̀dọ́ Àgùntàn gba àkájọ ìwé náà (6-8)

    • Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ló yẹ kó ṣí àwọn èdìdì náà (9-14)

  • 6

    • Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣí èdìdì mẹ́fà àkọ́kọ́ (1-17)

      • Ẹni tó ń ṣẹ́gun jókòó sórí ẹṣin funfun náà (1, 2)

      • Ẹni tó gun ẹṣin aláwọ̀ iná mú àlàáfíà kúrò (3, 4)

      • Ẹni tó gun ẹṣin dúdú máa mú ìyàn wá (5, 6)

      • Ikú ni orúkọ ẹni tó gun ẹṣin ràndánràndán (7, 8)

      • Àwọn tí wọ́n pa wà lábẹ́ pẹpẹ (9-11)

      • Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára (12-17)

  • 7

    • Áńgẹ́lì mẹ́rin di atẹ́gùn tó ń fa ìparun mú (1-3)

    • A gbé èdìdì lé 144,000 (4-8)

    • Ogunlọ́gọ̀ èèyàn wọ aṣọ funfun (9-17)

  • 8

    • A ṣí èdìdì keje (1-6)

    • Kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́ dún (7-12)

    • A kéde ìyọnu mẹ́ta (13)

  • 9

    • Kàkàkí karùn-ún (1-11)

    • Ìyọnu kan kọjá, méjì míì ń bọ̀ (12)

    • Kàkàkí kẹfà (13-21)

  • 10

    • Áńgẹ́lì alágbára mú àkájọ ìwé kékeré dání (1-7)

      • “A ò ní fi falẹ̀ mọ́” (6)

      • Àṣírí mímọ́ wá sí òpin (7)

    • Jòhánù jẹ àkájọ ìwé kékeré náà (8-11)

  • 11

    • Àwọn ẹlẹ́rìí méjì (1-13)

      • Àsọtẹ́lẹ̀ fún 1,260 ọjọ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ (3)

      • Wọ́n pa wọ́n, àmọ́ wọn ò sin wọ́n (7-10)

      • Wọ́n pa dà wà láàyè lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ (11, 12)

    • Ìyọnu kejì kọjá, ìkẹta ń bọ̀ (14)

    • Kàkàkí keje (15-19)

      • Ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀ (15)

      • Ó máa run àwọn tó ń run ayé (18)

  • 12

    • Obìnrin náà, ọmọkùnrin náà àti dírágónì (1-6)

    • Máíkẹ́lì bá dírágónì náà jà (7-12)

      • A ju dírágónì náà sí ayé (9)

      • Èṣù mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun (12)

    • Dírágónì ṣe inúnibíni sí obìnrin náà (13-17)

  • 13

    • Ẹranko olórí méje jáde látinú òkun (1-10)

    • Ẹranko oníwo méjì jáde látinú ayé (11-13)

    • Ère ẹranko olórí méje náà (14, 15)

    • Àmì àti nọ́ńbà ẹranko náà (16-18)

  • 14

    • Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti 144,000 (1-5)

    • Iṣẹ́ tí àwọn áńgẹ́lì mẹ́ta jẹ́ (6-12)

      • Áńgẹ́lì tó ń fò lójú ọ̀run ń kéde ìhìn rere (6, 7)

    • Aláyọ̀ ni àwọn tó kú ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi (13)

    • Wọ́n máa kórè ayé lẹ́ẹ̀mejì (14-20)

  • 15

    • Áńgẹ́lì méje ní ìyọnu méje (1-8)

      • Orin Mósè àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn (3, 4)

  • 16

    • Abọ́ méje ti ìbínú Ọlọ́run (1-21)

      • Wọ́n dà á sórí ayé (2), sínú òkun (3), sínú àwọn odò àti ìsun omi (4-7), sórí oòrùn (8, 9), sórí ìtẹ́ ẹranko náà (10, 11), sínú odò Yúfírétì (12-16) àti sínú afẹ́fẹ́ (17-21)

      • Ogun Ọlọ́run ní Amágẹ́dọ́nì (14,16)

  • 17

    • Ìdájọ́ “Bábílónì Ńlá” (1-18)

      • Aṣẹ́wó ńlá náà jókòó sórí ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò (1-3)

      • Ẹranko náà ‘wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò sí, síbẹ̀ ó máa jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀’ (8)

      • Ìwo mẹ́wàá máa bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jà (12-14)

      • Ìwo mẹ́wàá máa kórìíra aṣẹ́wó náà (16, 17)

  • 18

    • “Bábílónì Ńlá” ṣubú (1-8)

      • “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi” (4)

    • Wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ìṣubú Bábílónì (9-19)

    • Wọ́n ń yọ̀ ní ọ̀run torí Bábílónì ṣubú (20)

    • A máa ju Bábílónì sínú òkun bí òkúta (21-24)

  • 19

    • Ẹ yin Jáà, torí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ (1-10)

      • Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn (7-9)

    • Ẹni tó gun ẹṣin funfun (11-16)

    • Oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run (17, 18)

    • A ṣẹ́gun ẹranko náà (19-21)

  • 20

    • A de Sátánì fún 1,000 ọdún (1-3)

    • Àwọn tó máa jọba pẹ̀lú Kristi fún 1,000 ọdún (4-6)

    • A tú Sátánì sílẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn náà, a pa á run (7-10)

    • A ṣèdájọ́ àwọn òkú níwájú ìtẹ́ náà (11-15)

  • 21

    • Ọ̀run tuntun àti ayé tuntun (1-8)

      • Ikú kò sí mọ́ (4)

      • Ohun gbogbo di tuntun (5)

    • Bí Jerúsálẹ́mù tuntun ṣe rí (9-27)

  • 22

    • Odò omi ìyè (1-5)

    • Ìparí (6-21)

      • ‘Wá! Gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́’ (17)

      • “Máa bọ̀, Jésù Olúwa” (20)