Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Nọ́ńbà

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Wọ́n forúkọ àwọn tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun sílẹ̀ (1-46)

    • Àwọn ọmọ Léfì ò ní wọṣẹ́ ológun (47-51)

    • Bí wọ́n á ṣe pàgọ́ wọn létòlétò (52-54)

  • 2

    • Wọ́n pàgọ́ bí wọ́n ṣe pín àwọn ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta (1-34)

      • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà wà ní apá ìlà oòrùn (3-9)

      • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì wà ní apá gúúsù (10-16)

      • Àgọ́ àwọn ọmọ Léfì wà ní àárín (17)

      • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Éfúrémù wà ní apá ìwọ̀ oòrùn (18-24)

      • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Dánì wà ní apá àríwá (25-31)

      • Iye gbogbo ọkùnrin tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ (32-34)

  • 3

    • Àwọn ọmọ Áárónì (1-4)

    • Wọ́n yan àwọn ọmọ Léfì láti máa ṣe ìránṣẹ́ (5-39)

    • Wọ́n ra àwọn àkọ́bí pa dà (40-51)

  • 4

    • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì (1-20)

    • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì (21-28)

    • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Mérárì (29-33)

    • Àròpọ̀ iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ (34-49)

  • 5

    • Yíya àwọn aláìmọ́ sọ́tọ̀ (1-4)

    • Ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti sísan nǹkan dípò (5-10)

    • Lílo omi láti mọ̀ bóyá ẹnì kan ti ṣe àgbèrè (11-31)

  • 6

    • Ẹ̀jẹ́ láti di Násírì (1-21)

    • Bí àwọn àlùfáà á ṣe máa súre (22-27)

  • 7

    • Àwọn ọrẹ tí wọ́n mú wá síbi ìyàsímímọ́ àgọ́ ìjọsìn (1-89)

  • 8

    • Áárónì tan fìtílà méje (1-4)

    • Wọ́n wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ (5-22)

    • Ọjọ́ orí àwọn ọmọ Léfì tó lè ṣiṣẹ́ (23-26)

  • 9

    • Ètò láti ṣe Ìrékọjá lẹ́yìn àkókò rẹ̀ (1-14)

    • Ìkùukùu àti iná wà lórí àgọ́ ìjọsìn (15-23)

  • 10

    • Kàkàkí tí wọ́n fi fàdákà ṣe (1-10)

    • Wọ́n kúrò ní Sínáì (11-13)

    • Bí wọ́n ṣe máa tò tẹ̀ léra tí wọ́n bá ń lọ (14-28)

    • Mósè ní kí Hóbábù fi ọ̀nà han Ísírẹ́lì (29-34)

    • Àdúrà Mósè tí wọ́n bá ń tú àgọ́ ká (35, 36)

  • 11

    • Iná bọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run torí wọ́n ń ráhùn (1-3)

    • Wọ́n ń sunkún torí wọ́n fẹ́ jẹ ẹran (4-9)

    • Mósè wò ó pé òun ò kúnjú ìwọ̀n (10-15)

    • Jèhófà fi ẹ̀mí sára 70 àgbààgbà (16-25)

    • Ẹ́lídádì àti Médádì; Jóṣúà ń jowú torí Mósè (26-30)

    • Àwọn ẹyẹ àparò wá; Ọlọ́run fìyà jẹ wọ́n torí ìwọra wọn (31-35)

  • 12

    • Míríámù àti Áárónì sọ̀rọ̀ sí Mósè (1-3)

      • Mósè ni oníwà pẹ̀lẹ́ jù (3)

    • Jèhófà gbèjà Mósè (4-8)

    • Ẹ̀tẹ̀ bo Míríámù (9-16)

  • 13

    • Wọ́n rán amí 12 lọ sí Kénáánì (1-24)

    • Amí mẹ́wàá mú ìròyìn tí kò dáa wá (25-33)

  • 14

    • Wọ́n fẹ́ pa dà sí Íjíbítì (1-10)

      • Jóṣúà àti Kélẹ́bù mú ìròyìn tó dáa wá (6-9)

    • Jèhófà bínú; Mósè bá wọn bẹ̀bẹ̀ (11-19)

    • Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn: 40 ọdún nínú aginjù (20-38)

    • Àwọn ọmọ Ámálékì ṣẹ́gun Ísírẹ́lì (39-45)

  • 15

    • Òfin nípa ọrẹ (1-21)

      • Òfin kan náà fún ọmọ ìbílẹ̀ àti àjèjì (15, 16)

    • Ọrẹ tí ẹni tó bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ máa mú wá (22-29)

    • Ìyà tó máa jẹ ẹni tó bá mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ (30, 31)

    • Wọ́n pa ẹni tó rú òfin Sábáàtì (32-36)

    • Kí wọ́n máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn (37-41)

  • 16

    • Kórà, Dátánì àti Ábírámù ṣọ̀tẹ̀ (1-19)

    • Ọlọ́run ṣèdájọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ (20-50)

  • 17

    • Ọ̀pá Áárónì tó rúwé jẹ́ àmì (1-13)

  • 18

    • Ojúṣe àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì (1-7)

    • Ìpín àwọn àlùfáà (8-19)

      • Májẹ̀mú iyọ̀ (19)

    • Kí àwọn ọmọ Léfì máa gba ìdá mẹ́wàá, kí wọ́n sì máa san án (20-32)

  • 19

    • Abo màlúù pupa àti omi ìwẹ̀mọ́ (1-22)

  • 20

    • Míríámù kú sí Kádéṣì (1)

    • Mósè lu àpáta, ó sì dẹ́ṣẹ̀ (2-13)

    • Édómù kò jẹ́ kí Ísírẹ́lì kọjá (14-21)

    • Áárónì kú (22-29)

  • 21

    • Wọ́n ṣẹ́gun ọba Árádì (1-3)

    • Ejò tí wọ́n fi bàbà ṣe (4-9)

    • Ísírẹ́lì lọ yí ká Móábù (10-20)

    • Wọ́n ṣẹ́gun Síhónì ọba àwọn Ámórì (21-30)

    • Wọ́n ṣẹ́gun Ógù ọba àwọn Ámórì (31-35)

  • 22

    • Bálákì rán Báláámù níṣẹ́ (1-21)

    • Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù sọ̀rọ̀ (22-41)

  • 23

    • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà àkọ́kọ́ (1-12)

    • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà kejì (13-30)

  • 24

    • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà kẹta (1-11)

    • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà kẹrin (12-25)

  • 25

    • Ísírẹ́lì bá àwọn obìnrin Móábù ṣèṣekúṣe (1-5)

    • Fíníhásì ṣe ohun tó tọ́ (6-18)

  • 26

    • Wọ́n ka àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kejì (1-65)

  • 27

    • Àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì (1-11)

    • Mósè fa iṣẹ́ lé Jóṣúà lọ́wọ́ (12-23)

  • 28

    • Ìlànà tó wà fún onírúurú ọrẹ (1-31)

      • Ọrẹ ojoojúmọ́ (1-8)

      • Ọrẹ ọjọ́ Sábáàtì (9, 10)

      • Ọrẹ oṣooṣù (11-15)

      • Ẹbọ Ìrékọjá (16-25)

      • Ọrẹ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (26-31)

  • 29

    • Ìlànà tó wà fún onírúurú ẹbọ (1-40)

      • Ọjọ́ tí wọ́n máa fun kàkàkí (1-6)

      • Ọjọ́ Ètùtù (7-11)

      • Àjọyọ̀ Àtíbàbà (12-38)

  • 30

    • Ẹ̀jẹ́ àwọn ọkùnrin (1, 2)

    • Ẹ̀jẹ́ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọbìnrin (3-16)

  • 31

    • Wọ́n gbẹ̀san lára Mídíánì (1-12)

      • Wọ́n pa Báláámù (8)

    • Ìtọ́ni nípa ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun (13-54)

  • 32

    • Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (1-42)

  • 33

    • Ìrìn àjò Ísírẹ́lì láti ibì kan síbòmíì nínú aginjù (1-49)

    • Ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe máa gba ilẹ̀ Kénáánì (50-56)

  • 34

    • Àwọn ààlà ilẹ̀ Kénáánì (1-15)

    • Wọ́n yan àwọn tó máa pín ilẹ̀ náà (16-29)

  • 35

    • Ìlú àwọn ọmọ Léfì (1-8)

    • Àwọn ìlú ààbò (9-34)

  • 36

    • Òfin nípa ẹni tí àwọn obìnrin tó ní ogún máa fẹ́ (1-13)