A7-GB
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Ṣe Kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù (Apá Kejì)
ÀKÓKÒ |
IBI |
ÌṢẸ̀LẸ̀ |
MÁTÍÙ |
MÁÀKÙ |
LÚÙKÙ |
JÒHÁNÙ |
---|---|---|---|---|---|---|
Nísàn 14 |
Jerúsálẹ́mù |
Jésù fi hàn pé Júdásì ni ọ̀dàlẹ̀, ó sì ní kó máa lọ |
||||
Ó dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ (1Kọ 11:23-25) |
||||||
Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun àti pé àwọn àpọ́sítélì máa fọ́n ká |
||||||
Ó ṣèlérí olùrànlọ́wọ́; àpèjúwe àjàrà tòótọ́; ó pàṣẹ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn; àdúrà tó gbà kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì |
||||||
Gẹ́tísémánì |
Ẹ̀dùn ọkàn bá a nínú ọgbà; Júdásì fi Jésù hàn, wọ́n sì mú Jésù |
|||||
Jerúsálẹ́mù |
Ánásì bi Jésù léèrè ọ̀rọ̀; ìgbẹ́jọ́ níwájú Káyáfà, Sàhẹ́ndìrìn; Pétérù sẹ́ Jésù |
|||||
Júdásì ọ̀dàlẹ̀ pokùn so (Iṣe 1:18, 19) |
||||||
Níwájú Pílátù, lẹ́yìn náà Hẹ́rọ́dù, ó tún pa dà sọ́dọ̀ Pílátù |
||||||
Pílátù wá bó ṣe máa dá a sílẹ̀ àmọ́ àwọn Júù ní kó dá Bárábà sílẹ̀; wọ́n dájọ́ ikú fún un pé kí wọ́n kàn án mọ́ òpó igi oró |
||||||
(n. aago mẹ́ta ọ̀sán, Friday) |
Gọ́gọ́tà |
Ó kú lórí òpó igi oró |
||||
Jerúsálẹ́mù |
Wọ́n gbé òkú rẹ̀ kúrò lórí òpó igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì |
|||||
Nísàn 15 |
Jerúsálẹ́mù |
Àwọn àlùfáà àtàwọn Farisí gba àwọn ẹ̀ṣọ́ láti máa ṣọ́ ibojì náà, wọ́n sì sé e pa |
||||
Nísàn 16 |
Jerúsálẹ́mù àti agbègbè rẹ̀; Ẹ́máọ́sì |
Jésù jíǹde; ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ẹ̀ẹ̀marùn-ún |
||||
Lẹ́yìn Nísàn 16 |
Jerúsálẹ́mù; Gálílì |
Ó tún fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn (1Kọ 15:5-7; Iṣe 1:3-8); ó fún wọn ní ìtọ́ni; ó ní kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn |
||||
Ííyà 25 |
Òkè Ólífì, nítòsí Bẹ́tánì |
Jésù pa dà sí ọ̀run, ogójì ọjọ́ lẹ́yìn tó jíǹde (Iṣe 1:9-12) |