Àìsáyà 28:1-29
28 Adé* ìgbéraga* àwọn ọ̀mùtípara Éfúrémù+ gbéÀti ìtànná ẹwà ológo rẹ̀ tó ti ń rọ,Tó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá tó jẹ́ ti àwọn tí wáìnì ti kápá wọn!
2 Wò ó! Jèhófà ní ẹnì kan tó lókun tó sì lágbára.
Bí ìjì yìnyín tó ń sán ààrá, ìjì apanirun,Bí ìjì tó ń sán ààrá tó ń fa àkúnya omi tó bùáyà,Ó máa fipá jù ú sílẹ̀.
3 Wọ́n máa fi ẹsẹ̀ tẹÀwọn adé ìgbéraga* ti àwọn ọ̀mùtípara Éfúrémù mọ́lẹ̀.+
4 Òdòdó ẹwà ológo rẹ̀ tó ti ń rọ,Èyí tó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá,Máa dà bí àkọ́pọ́n èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣáájú ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.
Tí ẹnì kan bá rí i, ṣe ló máa gbé e mì ní gbàrà tó bá ti wà lọ́wọ́ rẹ̀.
5 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa di adé ológo àti òdòdó ẹ̀yẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó ṣẹ́ kù.+
6 Ó máa di ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tó jókòó láti ṣe ìdájọ́, ó sì máa jẹ́ orísun agbára fún àwọn tó ń lé ogun sẹ́yìn ní ẹnubodè.+
7 Àwọn yìí náà ṣìnà torí wáìnì;Ohun mímu wọn tó ní ọtí ń mú kí wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́,Àlùfáà àti wòlíì ti ṣìnà torí ọtí;Wáìnì ò jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe,Ọtí wọn sì ń jẹ́ kí wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́;Ìran wọn ń mú kí wọ́n ṣìnà,Wọ́n sì ń kọsẹ̀ nínú ìdájọ́.+
8 Torí pé èébì ẹlẹ́gbin kún àwọn tábìlì wọn,Kò sí ibi tí kò sí.
9 Ta ni èèyàn máa fún ní ìmọ̀,Ta sì ni èèyàn máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún?
Ṣé àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gba wàrà lẹ́nu wọn ni,Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?
10 Torí ó jẹ́ “àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn, àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn,Okùn tẹ̀ lé okùn, okùn tẹ̀ lé okùn,*+Díẹ̀ níbí, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”
11 Torí náà, ó máa bá àwọn èèyàn yìí sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn tó ń kólòlò* tí wọ́n sì ń sọ èdè àjèjì.+
12 Ó ti sọ fún wọn rí pé: “Ibi ìsinmi nìyí. Ẹ jẹ́ kí ẹni tó ti rẹ̀ sinmi; ibi ìtura nìyí,” àmọ́ wọn ò fetí sílẹ̀.+
13 Torí náà, ohun tí ọ̀rọ̀ Jèhófà máa jẹ́ fún wọn ni pé:
“Àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn, àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn,Okùn tẹ̀ lé okùn, okùn tẹ̀ lé okùn,*+Díẹ̀ níbí, díẹ̀ lọ́hùn-ún,”
Kí wọ́n lè kọsẹ̀, kí wọ́n sì ṣubú sẹ́yìnTí wọ́n bá ń rìn,Kí wọ́n lè ṣèṣe, kí wọ́n lè dẹkùn mú wọn, kí ọwọ́ sì tẹ̀ wọ́n.+
14 Torí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin afọ́nnu,Ẹ̀yin alákòóso àwọn èèyàn yìí ní Jerúsálẹ́mù,
15 Nítorí ẹ sọ pé:
“A ti bá Ikú dá májẹ̀mú,+A sì ti bá Isà Òkú* ṣe àdéhùn.*
Tí omi tó ń ru gùdù bá ya kọjá lójijì,Kò ní dé ọ̀dọ̀ wa,Torí a ti fi irọ́ ṣe ibi ààbò wa,A sì ti fi ara wa pa mọ́ sínú èké.”+
16 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Wò ó, màá fi òkúta+ tí a ti dán wò ṣe ìpìlẹ̀ ní Síónì,Òkúta igun ilé+ tó ṣeyebíye, ti ìpìlẹ̀ tó dájú.+
Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ kò ní bẹ̀rù.+
17 Màá fi ìdájọ́ òdodo ṣe okùn ìdíwọ̀n,+Màá sì fi òdodo ṣe irinṣẹ́ tí a fi ń mú nǹkan tẹ́jú.*+
Yìnyín máa gbá ibi ààbò irọ́ lọ,Omi sì máa kún bo ibi ìfarapamọ́.
18 Májẹ̀mú tí ẹ bá Ikú dá ò ní fìdí múlẹ̀ mọ́,Àdéhùn tí ẹ sì bá Isà Òkú* ṣe ò ní lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.+
Tí omi tó ń ru gùdù bá ya kọjá lójijì,Ó máa pa yín rẹ́.
19 Ní gbogbo ìgbà tó bá ti ń kọjá,Ó máa gbá yín lọ;+Torí á máa kọjá ní àràárọ̀,
Ní ọ̀sán àti ní òru.
Ìbẹ̀rù nìkan ló máa jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbọ́ yé wọn.”*
20 Torí pé ibùsùn ti kéré jù láti na ara,Aṣọ tí wọ́n hun sì ti tẹ́ẹ́rẹ́ jù láti fi bora.
21 Torí Jèhófà máa dìde bó ṣe ṣe ní Òkè Pérásímù;Ó máa gbéra sọ bó ṣe ṣe ní àfonífojì* tó wà nítòsí Gíbíónì,+Kó lè ṣe ìṣe rẹ̀, ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì,Kó sì lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀.+
22 Ní báyìí, ẹ má fini ṣe yẹ̀yẹ́,+Ká má bàa tún mú kí àwọn ìdè yín le sí i,Torí mo ti gbọ́ látọ̀dọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogunPé a ti pinnu láti pa gbogbo ilẹ̀ náà* run.+
23 Ẹ gbọ́, kí ẹ sì fetí sí ohùn mi;Ẹ fiyè sílẹ̀, kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi.
24 Ṣé ẹni tó ń túlẹ̀ máa ń fi gbogbo ọjọ́ túlẹ̀ kó tó fúnrúgbìn ni?
Ṣé á máa túlẹ̀, tí á sì máa fọ́ ilẹ̀ rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ láìdáwọ́ dúró ni?+
25 Tó bá ti mú kí ilẹ̀ náà tẹ́jú,Ṣebí ó máa fọ́n kúmínì dúdú, kó sì gbin kúmínì,Ṣebí ó sì máa gbin àlìkámà,* jéró àti ọkà bálì sí àyè wọnÀti ọkà sípẹ́ẹ̀tì+ sí eteetí ilẹ̀?
26 Torí Ó ń kọ́ ọ* ní ọ̀nà tó tọ́;Ọlọ́run rẹ̀ ń fún un ní ìtọ́ni.+
27 Torí a kì í fi ohun tí wọ́n fi ń pakà fọ́ kúmínì dúdú,+A kì í sì í yí àgbá kẹ̀kẹ́ lórí kúmínì.
Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pá la fi ń lu kúmínì dúdú,Igi la sì fi ń lu kúmínì.
28 Ṣé èèyàn máa ń fọ́ ọkà kó lè fi ṣe búrẹ́dì ni?
Rárá, kì í pa ọkà náà láìdáwọ́ dúró;+Nígbà tó bá sì fi àwọn ẹṣin rẹ̀ fa àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀ lórí rẹ̀,Kò ní fọ́ ọ.+
29 Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni èyí náà ti wá,Ẹni tí ìmọ̀ràn* rẹ̀ jẹ́ àgbàyanu,Tó sì gbé àwọn ohun ńlá ṣe.*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó jọ pé Samáríà tó jẹ́ olú ìlú ló ń sọ.
^ Tàbí “ìyangàn.”
^ Tàbí “ìyangàn.”
^ Tàbí “Okùn ìdíwọ̀n lé okùn ìdíwọ̀n, okùn ìdíwọ̀n lé okùn ìdíwọ̀n.”
^ Ní Héb., “àwọn tí ètè wọn ń kólòlò.”
^ Tàbí “Okùn ìdíwọ̀n lé okùn ìdíwọ̀n, okùn ìdíwọ̀n lé okùn ìdíwọ̀n.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “A sì ti fìdí ìran kan múlẹ̀ pẹ̀lú Isà Òkú.”
^ Tàbí “okùn tí a fi ń mọ̀ bóyá nǹkan gún régé.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “Tó bá ti yé wọn, ìbẹ̀rù máa bò wọ́n.”
^ Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
^ Tàbí “gbogbo ayé.”
^ Tàbí “wíìtì.”
^ Tàbí “bá a wí.”
^ Tàbí “ète.”
^ Tàbí “Tí ọgbọ́n rẹ̀ tó gbéṣẹ́ sì ga lọ́lá.”