Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 13:1-18

  • Ẹranko olórí méje jáde látinú òkun (1-10)

  • Ẹranko oníwo méjì jáde látinú ayé (11-13)

  • Ère ẹranko olórí méje náà (14, 15)

  • Àmì àti nọ́ńbà ẹranko náà (16-18)

13  Ó* sì dúró jẹ́ẹ́ lórí iyanrìn òkun. Mo wá rí ẹranko kan+ tó ń jáde látinú òkun,+ ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje, adé dáyádémà* mẹ́wàá sì wà lórí àwọn ìwo rẹ̀, àmọ́ àwọn orúkọ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì wà ní àwọn orí rẹ̀.  Ẹranko tí mo rí sì dà bí àmọ̀tẹ́kùn, àmọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi ti bíárì, ẹnu rẹ̀ sì jọ ti kìnnìún. Dírágónì náà+ fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀, ó sì fún un ní àṣẹ tó pọ̀.+  Mo sì rí i, ó dà bíi pé ọgbẹ́ tó lè pa á wà ní ọ̀kan lára àwọn orí rẹ̀, àmọ́ ọgbẹ́ tó lè pa á náà ti jinná,+ gbogbo ayé tẹ̀ lé ẹranko náà, wọ́n sì ń kan sáárá sí i.  Wọ́n sì jọ́sìn dírágónì náà torí pé ó fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí jọ́sìn ẹranko yẹn pé: “Ta ló dà bí ẹranko náà, ta ló sì lè bá a jà?”  Ó fún un ní ẹnu tó ń sọ àwọn nǹkan ńláńlá àti ọ̀rọ̀ òdì, ó sì fún un ní àṣẹ tó máa lò fún oṣù méjìlélógójì (42).+  Ó la ẹnu rẹ̀, ó fi ń sọ̀rọ̀ òdì+ sí Ọlọ́run, kó lè sọ̀rọ̀ òdì nípa orúkọ rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀, títí kan àwọn tó ń gbé ní ọ̀run.+  A gbà á láyè láti bá àwọn ẹni mímọ́ jagun kó sì ṣẹ́gun wọn,+ a sì fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà, èèyàn, ahọ́n* àti orílẹ̀-èdè.  Gbogbo àwọn tó ń gbé ní ayé máa jọ́sìn rẹ̀. Látìgbà ìpìlẹ̀ ayé, a ò kọ orúkọ ẹnì kankan nínú wọn sínú àkájọ ìwé ìyè+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí wọ́n pa.+  Ẹnikẹ́ni tó bá ní etí, kí ó gbọ́.+ 10  Tí ẹnikẹ́ni bá yẹ fún oko ẹrú, ó máa lọ sí oko ẹrú. Tí ẹnikẹ́ni bá máa fi idà pani,* a gbọ́dọ̀ fi idà pa á.+ Ibi tó ti gba pé káwọn ẹni mímọ́+ ní ìfaradà+ àti ìgbàgbọ́+ nìyí. 11  Lẹ́yìn náà, mo rí ẹranko míì tó ń jáde látinú ayé, ó ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bíi dírágónì.+ 12  Ó ń lo gbogbo àṣẹ tí ẹranko àkọ́kọ́+ ní lójú rẹ̀. Ó sì ń mú kí ayé àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ jọ́sìn ẹranko àkọ́kọ́ náà, tí ọgbẹ́ rẹ̀ tó lè pani ti jinná.+ 13  Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó lágbára, kódà ó ń mú kí iná wá láti ọ̀run sí ayé lójú aráyé. 14  Ó ń ṣi àwọn tó ń gbé ayé lọ́nà, torí àwọn iṣẹ́ àmì tí a gbà á láyè láti ṣe lójú ẹranko náà, bó ṣe ń sọ fún àwọn tó ń gbé ayé pé kí wọ́n ṣe ère+ ẹranko tó ní ọgbẹ́ idà, síbẹ̀ tó sọjí.+ 15  A gbà á láyè pé kó fún ẹranko náà ní èémí,* kí ère ẹranko náà lè sọ̀rọ̀, kó sì mú kí wọ́n pa gbogbo àwọn tó kọ̀ láti jọ́sìn ère ẹranko náà. 16  Ó sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún gbogbo èèyàn—ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ẹni tó wà lómìnira àti ẹrú—pé kí wọ́n sàmì sí ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí iwájú orí wọn,+ 17  àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àfi ẹni tó bá ní àmì náà, orúkọ+ ẹranko náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.+ 18  Ibi tó ti gba ọgbọ́n nìyí: Kí ẹni tó ní òye ṣírò nọ́ńbà ẹranko náà, torí pé nọ́ńbà èèyàn ni,* nọ́ńbà rẹ̀ sì ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666).+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, dírágónì náà.
Tàbí “àwọn ìwérí ọba.”
Tàbí “èdè.”
Tàbí kó jẹ́, “Tí a bá máa fi idà pa ẹnikẹ́ni.”
Tàbí “ẹ̀mí.”
Tàbí “nọ́ńbà aráyé.”