Òwe 15:1-33
15 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́* máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀,+Àmọ́ ọ̀rọ̀ líle* ń ru ìbínú sókè.+
2 Ahọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ lọ́nà rere,+Àmọ́ ẹnu àwọn òmùgọ̀ máa ń tú ọ̀rọ̀ ẹ̀gọ̀ jáde.
3 Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo,Ó ń ṣọ́ ẹni burúkú àti ẹni rere.+
4 Ahọ́n pẹ̀lẹ́* jẹ́ igi ìyè,+Àmọ́ ọ̀rọ̀ békebèke máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.*
5 Òmùgọ̀ kì í ka ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀ sí,+Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń gba ìbáwí.*+
6 Ọ̀pọ̀ ìṣúra ló wà nínú ilé olódodo,Àmọ́ èso* ẹni burúkú máa ń fa wàhálà bá a.+
7 Ètè ọlọ́gbọ́n máa ń tan ìmọ̀ kálẹ̀,+Àmọ́ ọkàn àwọn òmùgọ̀ kì í ṣe bẹ́ẹ̀.+
8 Ẹbọ ẹni burúkú jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+Àmọ́ àdúrà àwọn adúróṣinṣin máa ń múnú Rẹ̀ dùn.+
9 Jèhófà kórìíra ọ̀nà ẹni burúkú,+Àmọ́ ó nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń wá òdodo.+
10 Ìbáwí dà bí ohun tí kò dára* lójú ẹni tó ń ṣìnà,+Ẹni tó bá sì kórìíra ìbáwí á kú.+
11 Isà Òkú* àti ibi ìparun* ṣí sílẹ̀ gbayawu lójú Jèhófà.+
Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ọkàn èèyàn!+
12 Ẹlẹ́gàn kì í fẹ́ràn ẹni tó ń tọ́ ọ sọ́nà.*+
Kì í fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọlọ́gbọ́n.+
13 Inú dídùn ló ń mórí yá,Àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.+
14 Ọkàn tó ní òye máa ń wá ìmọ̀,+Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ ni àwọn òmùgọ̀ fi ń ṣe oúnjẹ jẹ.*+
15 Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ,+Àmọ́ ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn* máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.+
16 Ó sàn kéèyàn ní díẹ̀, kó sì bẹ̀rù Jèhófà+Ju kó ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ pẹ̀lú àníyàn.*+
17 Oúnjẹ tí a fi nǹkan ọ̀gbìn sè níbi tí ìfẹ́ wà+Sàn ju akọ màlúù àbọ́sanra* níbi tí ìkórìíra wà.+
18 Onínúfùfù máa ń dá wàhálà sílẹ̀,+Àmọ́ ẹni tí kì í tètè bínú máa ń mú kí ìjà rọlẹ̀.+
19 Ọ̀nà ọ̀lẹ dà bí igbó ẹ̀gún,+Àmọ́ ipa ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin dà bí ọ̀nà tó tẹ́jú.+
20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ máa ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn,+Àmọ́ òmùgọ̀ èèyàn máa ń kórìíra ìyá rẹ̀.+
21 Ẹni tí kò ní làákàyè* máa ń fi ìwà òmùgọ̀ ṣayọ̀,+Àmọ́ ẹni tó ní òye máa ń rìn lọ tààrà.+
22 Láìsí ìfinúkonú,* èrò á dasán,Àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn,* àṣeyọrí á wà.+
23 Inú èèyàn máa ń dùn tí ìdáhùn rẹ̀ bá tọ̀nà,*+Ọ̀rọ̀ tó bá sì bọ́ sí àkókò mà dára o!+
24 Ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye ń tọ ọ̀nà ìyè tó lọ sókè,+Kí ó lè yẹra fún Isà Òkú* nísàlẹ̀.+
25 Jèhófà máa ya ilé àwọn agbéraga lulẹ̀,+Àmọ́ kò ní jẹ́ kí wọ́n sún ààlà opó sẹ́yìn.+
26 Jèhófà kórìíra èrò àwọn ẹni ibi,+Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára mọ́ lójú Rẹ̀.+
27 Ẹni tó ń jẹ èrè tí kò tọ́ ń fa wàhálà* bá agbo ilé rẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò máa wà láàyè.+
28 Ọkàn olódodo máa ń ṣe àṣàrò kí ó tó dáhùn,*+Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú máa ń tú ọ̀rọ̀ burúkú jáde.
29 Jèhófà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú,Àmọ́ ó máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olódodo.+
30 Ojú tó ń dán* máa ń mú ọkàn yọ̀;Ìròyìn tó dára máa ń mú kí egungun lágbára.*+
31 Ẹni tó ń fetí sí ìbáwí tó ń fúnni ní ìyè,Àárín àwọn ọlọ́gbọ́n ló ń gbé.+
32 Ẹni tó bá ń kọ ìbáwí kórìíra ẹ̀mí* rẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá ń gba ìbáwí ní òye.*+
33 Ìbẹ̀rù Jèhófà ń kọ́ni lọ́gbọ́n,+Ìrẹ̀lẹ̀ ló sì ń ṣáájú ògo.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ọ̀rọ̀ tútù.”
^ Tàbí “ọ̀rọ̀ tó ń dunni.”
^ Tàbí “Ahọ́n tó ń woni sàn.”
^ Ní Héb., “ń wó ẹ̀mí palẹ̀.”
^ Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”
^ Tàbí “owó tó ń wọlé fún.”
^ Tàbí “ohun tó le jù.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “àti Ábádónì.”
^ Tàbí “tó ń bá a wí.”
^ Tàbí “ń wá.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ̀ ń yọ̀.”
^ Tàbí “ìdàrúdàpọ̀.”
^ Ní Héb.,“tí wọ́n bọ́ ní ibùjẹ ẹran.”
^ Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”
^ Tàbí “pé àwọn èèyàn bára wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.”
^ Tàbí “olùdámọ̀ràn.”
^ Ní Héb., “nínú ìdáhùn ẹnu rẹ̀.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ń kó ìtìjú.”
^ Tàbí “ń fara balẹ̀ ro bó ṣe máa dáhùn; máa ń ronú kí ó tó sọ̀rọ̀.”
^ Ní Héb., “sanra.”
^ Tàbí “Ẹ̀rín músẹ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ọkàn.”