Òwe 26:1-28
26 Bíi yìnyín nígbà ẹ̀ẹ̀rùn àti òjò nígbà ìkórè,Bẹ́ẹ̀ ni ògo kò yẹ òmùgọ̀.+
2 Bí ẹyẹ kì í ṣeé fò láìnídìí, tí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ kì í sì í ṣàdédé fò,Bẹ́ẹ̀ ni ègún kì í dédé wá láìsí ìdí kan pàtó.*
3 Pàṣán wà fún ẹṣin, ìjánu wà fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,+Ọ̀pá sì wà fún ẹ̀yìn àwọn òmùgọ̀.+
4 Má ṣe fún òmùgọ̀ lésì gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀,Kí o má bàa fi ara rẹ sí ipò rẹ̀.*
5 Fún òmùgọ̀ lésì gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀,Kó má bàa rò pé òun gbọ́n.+
6 Bí ẹni tó dá ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀, tó sì ṣe ara rẹ̀ léṣe*Ni ẹni tó fa ọ̀ràn lé òmùgọ̀ lọ́wọ́.
7 Bí ẹsẹ̀ arọ tó ṣe jọwọrọ,*Bẹ́ẹ̀ ni òwe rí lẹ́nu àwọn òmùgọ̀.+
8 Bí ẹni ń so òkúta mọ́ kànnàkànnàNi téèyàn bá ń fi ògo fún òmùgọ̀.+
9 Bíi koríko ẹlẹ́gùn-ún tó dé ọwọ́ ọ̀mùtí,Bẹ́ẹ̀ ni òwe rí lẹ́nu àwọn òmùgọ̀.
10 Bíi tafàtafà tó ń ṣe ohun tó bá ṣáà ti rí léṣe,*Ni ẹni tó gbéṣẹ́ fún òmùgọ̀ tàbí àwọn tó ń kọjá lọ.
11 Bí ajá tó pa dà sídìí èébì rẹ̀,Bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ ṣe ń tún ìwà ẹ̀gọ̀ rẹ̀ hù.+
12 Ṣe o ti rí ẹni tó rò pé òun gbọ́n?+
Ìrètí wà fún òmùgọ̀ jù ú lọ.
13 Ọ̀lẹ ń sọ pé: “Ọmọ kìnnìún wà lójú ọ̀nà,Kìnnìún wà ní gbàgede ìlú!”+
14 Ilẹ̀kùn ń yí lórí ìkọ́* rẹ̀,Ọ̀lẹ náà ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.+
15 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú abọ́ oúnjẹ,Àmọ́, ó rẹ̀ ẹ́ débi pé kò lè gbé e pa dà sẹ́nu.+
16 Ọ̀lẹ rò pé òun gbọ́nJu àwọn méje tó lè fèsì tó mọ́gbọ́n dání.
17 Bí ẹni tó gbá etí ajá múNi ẹni tó ń kọjá lọ, tínú sì ń bí lórí* ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.+
18 Bíi wèrè tó ń ta ohun ọṣẹ́ oníná, ọfà àti ikú*
19 Ni ẹni tó tan ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ, tó wá sọ pé, “Eré ni mò ń ṣe!”+
20 Níbi tí kò bá sí igi, iná á kú,Níbi tí kò bá sì sí abanijẹ́, ìjà á tán.+
21 Bí èédú ṣe wà fún ẹyin iná, tí igi sì wà fún iná,Bẹ́ẹ̀ ni alárìíyànjiyàn ṣe máa ń dá ìjà sílẹ̀.+
22 Ọ̀rọ̀ abanijẹ́ dà bí òkèlè dídùn;*Tí a gbé mì sínú ikùn lọ́hùn-ún.+
23 Bíi fàdákà fẹ́ẹ́rẹ́ tó bo àfọ́kù ìkòkòNi ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tó ń jáde látinú* ọkàn búburú.+
24 Ẹni tó kórìíra ẹlòmíì máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu bò ó mọ́lẹ̀,Àmọ́ ẹ̀tàn ló fi sínú.
25 Bó tilẹ̀ ń sọ ohun rere, má gbà á gbọ́,Nítorí ohun ìríra méje ló wà lọ́kàn rẹ̀.*
26 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ẹ̀tàn bo ìkórìíra rẹ̀ mọ́lẹ̀,A ó tú ìwà burúkú rẹ̀ síta nínú ìjọ.
27 Ẹni tó gbẹ́ kòtò yóò já sínú rẹ̀,Ẹni tó bá sì yí òkúta kúrò, òkúta náà yóò pa dà sórí rẹ̀.+
28 Ẹni tó ní ahọ́n èké kórìíra àwọn tó fi ń bà jẹ́,Ẹnu tó ń pọ́nni sì ń fa ìparun.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “ègún tí kò tọ́ síni kì í mọ́ni.”
^ Tàbí “Kí o má bàa mú ara rẹ bá a dọ́gba.”
^ Ní Héb., “tó sì ń mu ìwà ipá.”
^ Tàbí “dirodiro.”
^ Tàbí “tó ń ṣe gbogbo èèyàn léṣe.”
^ Tàbí “ìkọ́ aláyìípo.”
^ Tàbí kó jẹ́, “tó sì ń dá sí.”
^ Tàbí “ọfà tó ń ṣekú pani.”
^ Tàbí “ohun téèyàn fẹ́ fi ojú kòkòrò gbé mì.”
^ Ní Héb., “ètè tó ń jó belebele pẹ̀lú.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ̀ jẹ́ ohun ìríra látòkèdélẹ̀.”