Kíróníkà Kejì 20:1-37

  • Àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Júdà ká gbógun tì í (1-4)

  • Jèhóṣáfátì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ (5-13)

  • Ìdáhùn tí Jèhófà fún un (14-19)

  • Ọlọ́run gba Júdà là lọ́nà ìyanu (20-30)

  • Òpin ìjọba Jèhóṣáfátì (31-37)

20  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn Ámónímù* wá láti bá Jèhóṣáfátì jà.  Àwọn kan wá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá láti agbègbè òkun,* láti Édómù,+ kí wọ́n lè bá ọ jà, wọ́n sì wà ní Hasasoni-támárì, ìyẹn Ẹ́ń-gédì.”+  Ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ba Jèhóṣáfátì, ó sì pinnu láti wá* Jèhófà. + Nítorí náà, ó kéde ààwẹ̀ fún gbogbo Júdà.  Àwọn èèyàn Júdà wá kóra jọ láti wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà;+ wọ́n wá láti gbogbo àwọn ìlú Júdà kí wọ́n lè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.  Nígbà náà, Jèhóṣáfátì dìde láàárín ìjọ Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù nínú ilé Jèhófà níwájú àgbàlá tuntun,  ó sì sọ pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọ́run ní ọ̀run;+ ṣebí ìwọ lò ń ṣàkóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè?+ Ọwọ́ rẹ ni agbára àti okun wà, kò sì sẹ́ni tó lè dojú kọ ọ́.+  Ìwọ Ọlọ́run wa, ṣebí ìwọ lo lé àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí kúrò níwájú àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí o sì wá fún àtọmọdọ́mọ* ọ̀rẹ́ rẹ Ábúráhámù pé kí ó jẹ́ ohun ìní wọn títí lọ?+  Wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà, wọ́n sì kọ́ ibi mímọ́ síbẹ̀ fún ọ, èyí tó wà fún orúkọ rẹ,+ wọ́n sọ pé,  ‘Tí àjálù bá dé bá wa, ì báà jẹ́ idà tàbí ìdájọ́ tí kò bára dé tàbí àjàkálẹ̀ àrùn tàbí ìyàn, jẹ́ ká dúró níwájú ilé yìí àti níwájú rẹ (nítorí orúkọ rẹ wà nínú ilé yìí),+ ká sì ké pè ọ́ pé kí o ràn wá lọ́wọ́ nínú wàhálà wa, kí o gbọ́ kí o sì gbà wá.’+ 10  Ní báyìí, àwọn èèyàn Ámónì àti Móábù pẹ̀lú agbègbè olókè Séírì+ ti wà níbí, àwọn tí o kò yọ̀ǹda fún Ísírẹ́lì láti gba ilẹ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn ò sì pa wọ́n rẹ́.+ 11  Ní báyìí, ohun tí wọ́n fẹ́ fi san án fún wa ni pé kí wọ́n wá lé wa jáde kúrò lórí ohun ìní rẹ tí o fún wa láti jogún. + 12  Ọlọ́run wa, ṣé o ò ní dá wọn lẹ́jọ́ ni?+ Nítorí a ò ní agbára kankan níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bọ̀ wá bá wa yìí; a ò sì mọ ohun tó yẹ ká ṣe,+ àmọ́ ojú rẹ là ń wò.”+ 13  Lákòókò yìí, gbogbo àwọn tó wá láti Júdà dúró níwájú Jèhófà, títí kan àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ* wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kéékèèké. 14  Ní àárín ìjọ náà, ẹ̀mí Jèhófà bà lé Jáhásíẹ́lì ọmọ Sekaráyà ọmọ Bẹnáyà ọmọ Jéélì ọmọ Matanáyà ọmọ Léfì látinú àwọn ọmọ Ásáfù. 15  Ó sọ pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo Júdà àti ẹ̀yin tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti Ọba Jèhóṣáfátì! Ohun tí Jèhófà sọ fún yín nìyí, ‘Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn yìí, torí ìjà náà kì í ṣe tiyín, ti Ọlọ́run ni.+ 16  Ní ọ̀la, ẹ lọ dojú kọ wọ́n. Ọ̀nà Sísì ni wọ́n máa gbà wá, ẹ ó sì rí wọn ní òpin àfonífojì tó wà níwájú aginjù Jérúélì. 17  Kò ní sídìí fún yín láti ja ogun yìí. Ẹ dúró sáyè yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́,+ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà lórí yín.*+ Ìwọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà.+ Ní ọ̀la, ẹ jáde sí wọn, Jèhófà á sì wà pẹ̀lú yín.’”+ 18  Ní kíá, Jèhóṣáfátì dojú bolẹ̀, gbogbo Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù sì wólẹ̀ níwájú Jèhófà láti jọ́sìn Jèhófà. 19  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn ọmọ Kóhátì+ àti àwọn ọmọ Kórà dìde láti fi ohùn tó ròkè yin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 20  Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì lọ sí aginjù Tékóà.+ Bí wọ́n ṣe ń lọ, Jèhóṣáfátì dúró, ó sì sọ pé: “Ẹ gbọ́ mi, Júdà àti ẹ̀yin tó ń gbé Jerúsálẹ́mù! Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run yín kí ẹ lè dúró gbọn-in gbọn-in.* Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀,+ ẹ ó sì ṣàṣeyọrí.” 21  Lẹ́yìn tó fọ̀rọ̀ lọ àwọn èèyàn náà, ó yan àwọn kan láti máa kọrin,+ kí wọ́n sì máa yin Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ níwájú àwọn ọkùnrin tó dìhámọ́ra, wọ́n ní: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”+ 22  Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin ìyìn tìdùnnútìdùnnú, Jèhófà mú kí àwọn kan lúgọ de àwọn èèyàn Ámónì, Móábù àti agbègbè olókè Séírì tí wọ́n ń ya bọ̀ ní Júdà, wọ́n sì ń ṣá ara wọn balẹ̀.+ 23  Àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn ọmọ Móábù dojú kọ àwọn tó ń gbé agbègbè olókè Séírì+ láti pa wọ́n run pátápátá; nígbà tí wọ́n yanjú àwọn tó ń gbé Séírì tán, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn.+ 24  Àmọ́ nígbà tí àwọn èèyàn Júdà dé ilé ìṣọ́ tó wà ní aginjù,+ tí wọ́n sì bojú wo àwọn èèyàn náà, wọ́n rí òkú wọn nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ;+ kò sẹ́ni tó yè bọ́. 25  Nítorí náà, Jèhóṣáfátì àti àwọn èèyàn rẹ̀ wá kó ẹrù ogun láti ara àwọn èèyàn náà, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù, aṣọ àti àwọn ohun èlò tó fani mọ́ra, ohun tí wọ́n bọ́ lára wọn pọ̀ débi pé wọn ò lè kó wọn tán.+ Ọjọ́ mẹ́ta ló gbà kí wọ́n tó lè kó àwọn ẹrù ogun náà, nítorí ó pọ̀ gan-an. 26  Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ sí Àfonífojì* Bérákà, ibẹ̀ ni wọ́n ti yin* Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Bérákà*+ títí di òní. 27  Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì darí gbogbo èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù pa dà sí Jerúsálẹ́mù tìdùnnútìdùnnú, nítorí Jèhófà ti mú kí wọ́n yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn.+ 28  Torí náà, wọ́n dé sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ pẹ̀lú kàkàkí, + wọ́n sì lọ sí ilé Jèhófà.+ 29  Ẹ̀rù Ọlọ́run ba gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà ti bá àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì jà.+ 30  Bí ìjọba Jèhóṣáfátì kò ṣe ní ìyọlẹ́nu mọ́ nìyẹn, Ọlọ́run rẹ̀ sì ń fún un ní ìsinmi níbi gbogbo.+ 31  Jèhóṣáfátì ń jọba lórí Júdà nìṣó. Ẹni ọdún márùndínlógójì (35) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ásúbà ọmọ Ṣílíháì.+ 32  Ó ń rìn ní ọ̀nà Ásà bàbá rẹ̀.+ Kò yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà.+ 33  Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò,+ àwọn èèyàn náà kò sì tíì múra ọkàn wọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 34  Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóṣáfátì, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Jéhù+ ọmọ Hánáánì,+ èyí tó wà nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì. 35  Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì ọba Júdà bá Ahasáyà ọba Ísírẹ́lì da nǹkan pọ̀, ẹni tó ń hùwà burúkú.+ 36  Nítorí náà, ó fi í ṣe alábàáṣiṣẹ́ láti máa ṣe àwọn ọkọ̀ òkun tí á máa lọ sí Táṣíṣì,+ wọ́n sì ṣe àwọn ọkọ̀ òkun náà ní Esioni-gébérì. + 37  Àmọ́, Élíésérì ọmọ Dódáfáhù láti Márẹ́ṣà sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Jèhóṣáfátì, ó ní: “Torí pé o bá Ahasáyà da nǹkan pọ̀, Jèhófà yóò pa iṣẹ́ rẹ run.”+ Nítorí náà, àwọn ọkọ̀ òkun náà fọ́,+ wọn kò sì lè lọ sí Táṣíṣì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “àwọn Méúnì.”
Ó ṣe kedere pé Òkun Òkú ni.
Ní Héb., “yíjú sí wíwá.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
Tàbí “kí ẹ sì rí bí Jèhófà á ṣe gbà yín là.”
Tàbí “kí ẹ lè fara dà á.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “fi ìbùkún fún.”
Ó túmọ̀ sí “Ìbùkún.”