Ìwé Kejì Pétérù 3:1-18

  • Àwọn tó ń fini ṣẹlẹ́yà kò ka ìparun tó ń bọ̀ sí (1-7)

  • Jèhófà kì í fi nǹkan falẹ̀ (8-10)

  • Ẹ ronú nípa irú ẹni tó yẹ kí ẹ jẹ́ (11-16)

    • Ọ̀run tuntun àti ayé tuntun (13)

  • Ẹ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa ṣì yín lọ́nà (17, 18)

3  Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, lẹ́tà kejì tí màá kọ sí yín nìyí, bíi ti àkọ́kọ́, mò ń rán yín létí kí n lè ta yín jí láti ronú jinlẹ̀,+  kí ẹ máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ṣáájú* àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì yín.  Lákọ̀ọ́kọ́, kí ẹ mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn tó ń fini ṣẹlẹ́yà máa wá, wọ́n á máa fini ṣẹlẹ́yà, wọ́n á máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn,+  wọ́n á máa sọ pé: “Ṣebí ó ṣèlérí pé òun máa wà níhìn-ín, òun wá dà?+ Ó ṣe tán, bí nǹkan ṣe rí gẹ́lẹ́ láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, bẹ́ẹ̀ náà ló rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá.”+  Torí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ gbójú fo òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí, pé nígbà àtijọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọ̀run àti ayé dúró digbí látinú omi, kí ó sì wà láàárín omi;+  ìyẹn la sì fi pa ayé ìgbà yẹn run nígbà tí ìkún omi bò ó mọ́lẹ̀.+  Ọ̀rọ̀ yẹn kan náà la fi tọ́jú àwọn ọ̀run àti ayé tó wà báyìí pa mọ́ de iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+  Síbẹ̀, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má gbàgbé pé lójú Jèhófà* ọjọ́ kan dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti pé ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí ọjọ́ kan.+  Jèhófà* kò fi ìlérí rẹ̀ falẹ̀,+ bí àwọn èèyàn kan ṣe rò pé ó ń fi falẹ̀, àmọ́ ó ń mú sùúrù fún yín torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.+ 10  Àmọ́ ọjọ́ Jèhófà*+ máa dé bí olè,+ nígbà yẹn àwọn ọ̀run máa kọjá lọ+ pẹ̀lú ariwo tó rinlẹ̀,* àmọ́ àwọn ohun ìpìlẹ̀ tó gbóná janjan máa yọ́, a sì máa tú ayé àti àwọn iṣẹ́ tó wà nínú rẹ̀ síta.+ 11  Bí gbogbo nǹkan yìí ṣe máa yọ́ báyìí, ẹ ronú nípa irú ẹni tó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, 12  bí ẹ ti ń dúró de ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà*+ máa wà níhìn-ín, tí ẹ sì ń fi í sọ́kàn dáadáa,* nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run máa pa run  + nínú iná, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ máa yọ́ nítorí ooru tó gbóná janjan! 13  Àmọ́ à ń retí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tó ṣèlérí,+ níbi tí òdodo á máa gbé.+ 14  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe ń retí àwọn nǹkan yìí, ẹ sa gbogbo ipá yín kó lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín láìní èérí àti àbààwọ́n àti ní àlàáfíà.+ 15  Bákan náà, ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà, bí Pọ́ọ̀lù arákùnrin wa ọ̀wọ́n náà ṣe lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un láti kọ̀wé sí yín,+ 16  ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí bó ti ṣe nínú gbogbo lẹ́tà rẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan kan nínú wọn ṣòroó lóye, àwọn nǹkan yìí sì ni àwọn aláìmọ̀kan* àti àwọn tí kò dúró ṣinṣin ń lọ́ po sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń ṣe sí àwọn ibi yòókù nínú Ìwé Mímọ́. 17  Torí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe mọ àwọn nǹkan yìí tẹ́lẹ̀, ẹ máa ṣọ́ra yín kí àṣìṣe àwọn arúfin má bàa ṣì yín lọ́nà pẹ̀lú wọn, tí ẹ ò sì ní dúró ṣinṣin* mọ́.+ 18  Àmọ́ ẹ túbọ̀ máa dàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi. Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ báyìí àti títí láé. Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ti sọ tẹ́lẹ̀.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ariwo tó ń yára kọjá lọ.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “tó sì ń wù yín gidigidi.” Ní Grk., “tí ẹ sì ń fẹ́ kó yára kánkán.”
Tàbí “aláìlẹ́kọ̀ọ́.”
Tàbí “fẹsẹ̀ múlẹ̀.”