Sámúẹ́lì Kejì 2:1-32

  • Dáfídì di ọba Júdà (1-7)

  • Íṣí-bóṣétì di ọba Ísírẹ́lì (8-11)

  • Ogun tó wáyé láàárín ilé Dáfídì àti ilé Sọ́ọ̀lù (12-32)

2  Lẹ́yìn náà, Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà+ pé: “Ṣé kí n lọ sínú ọ̀kan lára àwọn ìlú Júdà?” Jèhófà sọ fún un pé: “Lọ.” Dáfídì bá béèrè pé: “Ibo ni kí n lọ?” Ó fèsì pé: “Lọ sí Hébúrónì.”+  Torí náà, Dáfídì lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìyàwó rẹ̀ méjèèjì, Áhínóámù+ ará Jésírẹ́lì àti Ábígẹ́lì+ opó Nábálì ará Kámẹ́lì.  Dáfídì tún mú àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀+ lọ, kálukú pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní àwọn ìlú tó wà ní àyíká Hébúrónì.  Ìgbà náà ni àwọn ọkùnrin Júdà wá, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí ilé Júdà.+ Wọ́n sọ fún Dáfídì pé: “Àwọn ará Jabeṣi-gílíádì ló sin Sọ́ọ̀lù.”  Torí náà, Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ sí àwọn ará Jabeṣi-gílíádì, ó sọ fún wọn pé: “Kí Jèhófà bù kún yín, nítorí ẹ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Sọ́ọ̀lù, olúwa yín, ní ti pé ẹ sin ín.+  Kí Jèhófà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́ hàn sí yín. Èmi náà máa ṣojú rere sí yín nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí.+  Ẹ má ṣe dẹwọ́, ẹ jẹ́ onígboyà, nítorí pé Sọ́ọ̀lù olúwa yín ti kú, ilé Júdà sì ti fòróró yàn mí ṣe ọba lórí wọn.”  Àmọ́ Ábínérì+ ọmọ Nérì, olórí ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù ti mú Íṣí-bóṣétì,+ ọmọ Sọ́ọ̀lù sọdá sí Máhánáímù,+  ó sì fi jẹ ọba lórí Gílíádì+ àti àwọn Ááṣù, lórí Jésírẹ́lì  + àti Éfúrémù,+ lórí Bẹ́ńjámínì àti gbogbo Ísírẹ́lì. 10  Ẹni ogójì (40) ọdún ni Íṣí-bóṣétì, ọmọ Sọ́ọ̀lù nígbà tó jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì fi ọdún méjì ṣàkóso. Àmọ́ Dáfídì ni ilé Júdà ń tì lẹ́yìn.+ 11  Àkókò* tí Dáfídì fi jọba ní Hébúrónì lórí ilé Júdà jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.+ 12  Nígbà tó yá, Ábínérì ọmọ Nérì àti àwọn ìránṣẹ́ Íṣí-bóṣétì, ọmọ Sọ́ọ̀lù kúrò ní Máhánáímù+ lọ sí Gíbíónì.+ 13  Jóábù+ ọmọ Seruáyà+ àti àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì náà jáde lọ, wọ́n sì pàdé wọn ní adágún odò tó wà ní Gíbíónì; àwùjọ kan jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan adágún odò náà, nígbà tí àwùjọ kejì jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kejì adágún odò náà. 14  Níkẹyìn, Ábínérì sọ fún Jóábù pé: “Jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin dìde, kí wọ́n sì wọ̀yá ìjà* níwájú wa.” Jóábù bá sọ pé: “Kí wọ́n dìde.” 15  Nítorí náà, wọ́n dìde, àwùjọ méjèèjì sì yan iye àwọn tó máa sọdá, àwọn méjìlá (12) wá látọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì àti Íṣí-bóṣétì, ọmọ Sọ́ọ̀lù, àwọn méjìlá (12) sì wá látọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. 16  Kálukú gbá orí ẹnì kejì rẹ̀ mú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ti idà rẹ̀ bọ ẹni tó dojú kọ ọ́ ní ẹ̀gbẹ́, gbogbo wọn sì ṣubú pa pọ̀. Torí náà, wọ́n pe ibẹ̀ ní Helikati-hásúrímù, èyí tó wà ní Gíbíónì. 17  Ìjà tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn le gan-an, níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì ṣẹ́gun Ábínérì àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì. 18  Àwọn ọmọ Seruáyà+ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wà níbẹ̀, Jóábù,+ Ábíṣáì+ àti Ásáhélì;+ ẹsẹ̀ Ásáhélì sì yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín inú pápá. 19  Ásáhélì lé Ábínérì, kò sì yà sọ́tùn-ún tàbí kó yà sósì bó ṣe ń lépa Ábínérì. 20  Nígbà tí Ábínérì bojú wẹ̀yìn, ó ní: “Ásáhélì, ṣé ìwọ nìyẹn?” Ó dáhùn pé: “Èmi ni.” 21  Ábínérì wá sọ fún un pé: “Yà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì, kí o gbá ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin mú, kí o sì sọ ohun tí o bá bọ́ kúrò lára rẹ̀ di tìrẹ.” Àmọ́ Ásáhélì kò fẹ́ dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀. 22  Ábínérì bá sọ fún Ásáhélì lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi. Ṣé o fẹ́ kí n pa ọ́ ni? Kò yẹ kí n gbójú sókè wo Jóábù ẹ̀gbọ́n rẹ o.” 23  Àmọ́, ó kọ̀ kò dúró, torí náà Ábínérì fi ìdí ọ̀kọ̀ gún inú rẹ̀,+ ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀; ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú lójú ẹsẹ̀. Gbogbo ẹni tó dé ibi tí Ásáhélì ṣubú sí, tí ó sì kú sí, ló dúró tó sì ń wò. 24  Lẹ́yìn náà, Jóábù àti Ábíṣáì lépa Ábínérì. Bí oòrùn ṣe ń wọ̀, wọ́n dé òkè Ámà tó dojú kọ Gíà lójú ọ̀nà tó lọ sí aginjù Gíbíónì. 25  Ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ti kóra jọ sẹ́yìn Ábínérì, wọ́n di àwùjọ kan, wọ́n sì dúró sórí òkè kan. 26  Ábínérì wá nahùn pe Jóábù, ó ní: “Ṣé bí a ó ṣe máa fi idà pa ara wa lọ nìyí? Ṣé o ò mọ̀ pé ìkorò ló máa já sí ni? Ìgbà wo lo máa tó sọ fún àwọn èèyàn yìí pé kí wọ́n pa dà lẹ́yìn àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n ń lé?” 27  Ni Jóábù bá sọ pé: “Bí Ọlọ́run tòótọ́ ti wà láàyè, ká ní o ò sọ̀rọ̀ ni, àárọ̀ ọ̀la ni àwọn èèyàn náà ì bá tó pa dà lẹ́yìn àwọn arákùnrin wọn.” 28  Ni Jóábù bá fun ìwo, àwọn ọkùnrin rẹ̀ pa dà lẹ́yìn Ísírẹ́lì, ìjà náà sì dáwọ́ dúró. 29  Lẹ́yìn náà, Ábínérì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ gba Árábà+ kọjá ní gbogbo òru yẹn, wọ́n sọdá Jọ́dánì, wọ́n sì rin gbogbo ọ̀nà àfonífojì tóóró* jáde, níkẹyìn wọ́n dé Máhánáímù.+ 30  Lẹ́yìn ti Jóábù pa dà lẹ́yìn Ábínérì, ó kó gbogbo àwọn èèyàn náà jọ. Àwọn mọ́kàndínlógún (19) pẹ̀lú Ásáhélì ló dàwátì lára àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. 31  Àmọ́ àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì ti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì àti àwọn ọkùnrin Ábínérì, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta (360) lára àwọn ọkùnrin wọn ló sì kú. 32  Wọ́n gbé Ásáhélì,+ wọ́n sì sin ín sí ibojì bàbá rẹ̀ tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ Lẹ́yìn náà, Jóábù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ rìn láti òru mọ́jú, wọ́n sì dé Hébúrónì+ ní ìdájí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Iye ọjọ́.”
Tàbí “díje.”
Tàbí kó jẹ́, “Bítírónì.”