Sí Àwọn Hébérù 3:1-19

  • Jésù ju Mósè lọ (1-6)

    • Ọlọ́run ló kọ́ ohun gbogbo (4)

  • Ìkìlọ̀ nípa àìnígbàgbọ́ (7-19)

    • “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀” (7, 15)

3  Torí náà, ẹ̀yin ará tí ẹ jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin tí ẹ ní ìpè* ti ọ̀run,+ ẹ ronú nípa àpọ́sítélì àti àlùfáà àgbà tí a gbà,* ìyẹn Jésù.+  Ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ẹni tó yàn án,+ bí Mósè náà ṣe jẹ́ ní gbogbo ilé Ẹni yẹn.+  Torí a kà á* yẹ pé kó ní ògo+ tó ju ti Mósè lọ, nítorí ẹni tó kọ́lé máa ń ní ọlá ju ilé lọ.  Ó dájú pé, gbogbo ilé ló ní ẹni tó kọ́ ọ, àmọ́ Ọlọ́run ló kọ́ ohun gbogbo.  Mósè jẹ́ ìránṣẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ilé Ẹni yẹn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí* àwọn ohun tí a máa sọ lẹ́yìn náà,  àmọ́ Kristi jẹ́ olóòótọ́ ọmọ+ lórí ilé Ọlọ́run. Àwa ni ilé Rẹ̀,+ tí a bá rí i dájú pé a ò jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti máa sọ̀rọ̀ ní fàlàlà, tí a sì di ìrètí tí a fi ń yangàn mú ṣinṣin títí dé òpin.  Torí náà, bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe sọ pé,+ “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀,  ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bó ṣe rí nígbà tí ẹ fa ìbínú tó le gan-an, bíi ti ọjọ́ tí ẹ fa àdánwò ní aginjù,+  níbi tí àwọn baba ńlá yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì dẹ mí wò, láìka àwọn iṣẹ́ mi tí wọ́n rí fún ogójì (40) ọdún sí.+ 10  Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ ìran yìí fi kó mi nírìíra, tí mo sì sọ pé: ‘Àwọn èèyàn tó máa ń ṣìnà nínú ọkàn ni wọ́n, wọn ò sì tíì mọ àwọn ọ̀nà mi.’ 11  Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé, ‘Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.’”+ 12  Ẹ̀yin ará, ẹ ṣọ́ra, kí ẹnì kankan nínú yín má lọ ní ọkàn burúkú tí kò ní ìgbàgbọ́, tí á mú kó fi Ọlọ́run alààyè sílẹ̀;+ 13  àmọ́ ẹ máa fún ara yín níṣìírí lójoojúmọ́, tí a bá ṣì ń pè é ní “Òní,”+ kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ìkankan nínú yín di ọlọ́kàn líle. 14  Torí àfi tí a bá ní irú ìdánilójú tí a ní níbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, la máa fi lè ní ìpín pẹ̀lú Kristi.*+ 15  Bí a ṣe sọ ọ́ pé, “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bó ṣe rí nígbà tí ẹ fa ìbínú tó le gan-an.”+ 16  Torí, àwọn wo ló gbọ́, síbẹ̀ tí wọ́n mú un bínú gidigidi? Ní tòótọ́, ṣebí gbogbo àwọn tí Mósè kó jáde ní Íjíbítì ni?+ 17  Bákan náà, àwọn wo ni ọ̀rọ̀ wọn kó Ọlọ́run nírìíra fún ogójì (40) ọdún?+ Ṣebí àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, tí òkú wọn sùn nínú aginjù ni?+ 18  Àwọn wo ló sì búra fún pé wọn ò ní wọnú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn tó ṣàìgbọràn ni? 19  Torí náà, a rí i pé àìnígbàgbọ́ ò jẹ́ kí wọ́n lè wọnú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìkésíni.”
Tàbí “tí a jẹ́wọ́ rẹ̀.”
Ìyẹn, Jésù.
Tàbí “ẹlẹ́rìí.”
Tàbí “jẹ́ alábàápín pẹ̀lú Kristi.”