Jẹ́nẹ́sísì 50:1-26

  • Jósẹ́fù sin Jékọ́bù sí Kénáánì (1-14)

  • Jósẹ́fù fi dá àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú pé òun ti dárí jì wọ́n (15-21)

  • Jósẹ́fù darúgbó, ó sì kú (22-26)

    • Àṣẹ tí Jósẹ́fù pa nípa àwọn egungun rẹ̀ (25)

50  Jósẹ́fù sì ṣubú lé bàbá+ rẹ̀, ó sunkún lórí rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.  Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn oníṣègùn, pé kí wọ́n tọ́jú òkú bàbá òun kó má bàa jẹrà.+ Àwọn oníṣègùn náà wá tọ́jú òkú Ísírẹ́lì,  wọ́n sì fi ogójì (40) ọjọ́ gbáko tọ́jú rẹ̀, torí iye ọjọ́ tí wọ́n fi ń tọ́jú òkú nìyẹn, kó má bàa jẹrà. Àwọn ará Íjíbítì sì ń sunkún torí Jékọ́bù fún àádọ́rin (70) ọjọ́.  Nígbà tí wọ́n ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ tán, Jósẹ́fù sọ fún àwọn òṣìṣẹ́* Fáráò pé: “Tí mo bá rí ojúure yín, ẹ bá mi sọ fún Fáráò pé:  ‘Bàbá mi mú kí n búra,+ ó ní: “Wò ó! Mi ò ní pẹ́ kú.+ Kí o sin mí sí ibi ìsìnkú+ mi tí mo gbẹ́ ní ilẹ̀ Kénáánì.”+ Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n lọ sin bàbá mi, màá sì pa dà lẹ́yìn náà.’”  Fáráò fèsì pé: “Lọ sin bàbá rẹ, bó ṣe mú kí o búra.”+  Jósẹ́fù wá lọ sin bàbá rẹ̀, gbogbo ìránṣẹ́ Fáráò sì bá a lọ, pẹ̀lú àwọn àgbààgbà+ ilé rẹ̀ àti gbogbo àgbààgbà ilẹ̀ Íjíbítì,  gbogbo agbo ilé Jósẹ́fù, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti agbo ilé bàbá+ rẹ̀. Àwọn ọmọ wọn kéékèèké, agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn nìkan ni wọ́n fi sílẹ̀ ní ilẹ̀ Góṣénì.  Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti àwọn tó ń gẹṣin tún bá a lọ, àwọn èèyàn náà pọ̀ gan-an. 10  Wọ́n wá dé ibi ìpakà Átádì, tó wà ní agbègbè Jọ́dánì, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ gidigidi níbẹ̀. Ọjọ́ méje ni Jósẹ́fù fi ṣọ̀fọ̀ bàbá rẹ̀. 11  Àwọn ọmọ Kénáánì, tó ń gbé ilẹ̀ náà rí wọn tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà Átádì, wọ́n sì sọ pé: “Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ àwọn ará Íjíbítì yìí o!” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Ebẹli-mísíráímù,* tó wà ní agbègbè Jọ́dánì. 12  Àwọn ọmọ Jékọ́bù ṣe ohun tó sọ fún wọn+ gẹ́lẹ́. 13  Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì sin ín sínú ihò tó wà ní ilẹ̀ Mákípẹ́là, ilẹ̀ tó wà níwájú Mámúrè tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú.+ 14  Lẹ́yìn tó sin bàbá rẹ̀, Jósẹ́fù pa dà sí Íjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn tó tẹ̀ lé e lọ sìnkú bàbá rẹ̀. 15  Nígbà tí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù rí i pé bàbá àwọn ti kú, wọ́n sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé Jósẹ́fù ń dì wá sínú, tí yóò sì san wá lẹ́san gbogbo ibi tí a ṣe sí i.”+ 16  Wọ́n wá ránṣẹ́ sí Jósẹ́fù pé: “Kí bàbá rẹ tó kú, ó pàṣẹ pé: 17  ‘Ẹ sọ fún Jósẹ́fù pé: “Jọ̀ọ́, mo bẹ̀ ọ́, dárí àṣìṣe àwọn arákùnrin rẹ jì wọ́n, kí o sì gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá nígbà tí wọ́n ṣe ọ́ ní ibi.”’ Jọ̀ọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bàbá rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Jósẹ́fù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún. 18  Àwọn arákùnrin rẹ̀ náà wá, wọ́n wólẹ̀ síwájú rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Wò ó, a ti di ẹrú rẹ!”+ 19  Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni Ọlọ́run ni? 20  Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrò ibi lẹ ní sí mi,+ Ọlọ́run mú kó yọrí sí rere, kó lè dá ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn sí, bó ti ń ṣe lónìí.+ 21  Torí náà, ẹ má bẹ̀rù. Màá ṣì máa pèsè oúnjẹ+ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kéékèèké.” Bó ṣe tù wọ́n nínú nìyẹn, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. 22  Jósẹ́fù ń gbé ní Íjíbítì, òun àti agbo ilé bàbá rẹ̀. Ọjọ́ ayé Jósẹ́fù sì jẹ́ àádọ́fà (110) ọdún. 23  Jósẹ́fù rí ìran kẹta àwọn ọmọ+ Éfúrémù, pẹ̀lú àwọn ọmọ Mákírù,+ ọmọ Mánásè. Orúnkún Jósẹ́fù ni wọ́n bí wọn sí.* 24  Níkẹyìn, Jósẹ́fù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Mi ò ní pẹ́ kú, àmọ́ ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín,+ ó sì dájú pé yóò mú yín kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tó búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.”+ 25  Jósẹ́fù wá mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì búra, ó ní: “Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé yín. Kí ẹ kó egungun mi kúrò níbí.”+ 26  Ẹni àádọ́fà (110) ọdún ni Jósẹ́fù nígbà tó kú, wọ́n sì tọ́jú òkú rẹ̀ kó má bàa jẹrà,+ wọ́n wá gbé e sínú pósí ní ilẹ̀ Íjíbítì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “agbo ilé.”
Ó túmọ̀ sí “Àwọn Ará Íjíbítì Ṣọ̀fọ̀.”
Ìyẹn ni pé, ó ṣe wọ́n bí ọmọ, ó sì ṣojúure sí wọn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.