Àkọsílẹ̀ Jòhánù 12:1-50

  • Màríà da òróró sí ẹsẹ̀ Jésù (1-11)

  • Jésù gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú ìlú (12-19)

  • Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (20-37)

  • Àìnígbàgbọ́ àwọn Júù mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ (38-43)

  • Jésù wá gba ayé là (44-50)

12  Nígbà tí Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jésù dé sí Bẹ́tánì, níbi tí Lásárù+ wà, ẹni tí Jésù jí dìde.  Torí náà, wọ́n se àsè oúnjẹ alẹ́ fún un níbẹ̀, Màtá ń gbé oúnjẹ wá fún wọn,+ Lásárù sì wà lára àwọn tó ń bá a jẹun.*  Màríà wá mú ìwọ̀n pọ́n-ùn kan* òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì tó wọ́n gan-an, ó dà á sí ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ. Òórùn òróró onílọ́fínńdà náà wá gba inú ilé náà kan.+  Àmọ́ Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó máa tó dà á, sọ pé:  “Kí ló dé tí a ò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) owó dínárì,* ká sì fún àwọn aláìní?”  Kì í ṣe torí pé ọ̀rọ̀ àwọn aláìní jẹ ẹ́ lógún ló ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí o, àmọ́ torí pé olè ni, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àpótí owó wà, ó sì máa ń jí owó inú rẹ̀.  Torí náà, Jésù sọ pé: “Fi í sílẹ̀, kó lè ṣe èyí nítorí ọjọ́ ìsìnkú mi.+  Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín,+ àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín.”+  Ní àkókò yẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, wọ́n sì wá, àmọ́ kì í ṣe torí Jésù nìkan, wọ́n tún fẹ́ rí Lásárù, ẹni tí Jésù jí dìde.+ 10  Àwọn olórí àlùfáà wá gbìmọ̀ láti pa Lásárù náà, 11  ìdí ni pé torí rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù ṣe ń lọ síbẹ̀, tí wọ́n sì ń ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù.+ 12  Lọ́jọ́ kejì, èrò rẹpẹtẹ tó wá síbi àjọyọ̀ náà gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù. 13  Wọ́n wá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “A bẹ̀ ọ́, gbà là! Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà,*+ Ọba Ísírẹ́lì!”+ 14  Nígbà tí Jésù rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó jókòó sórí rẹ̀,+ bí a ṣe kọ ọ́ pé: 15  “Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Síónì. Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀, ó jókòó sórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”*+ 16  Àwọn nǹkan yìí ò kọ́kọ́ yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àmọ́ nígbà tí a ṣe Jésù lógo,+ wọ́n rántí pé a ti kọ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀ àti pé wọ́n ṣe àwọn nǹkan yìí sí i.+ 17  Àwọn èrò tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó pe Lásárù jáde látinú ibojì,*+ tó sì jí i dìde ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ ṣáá.+ 18  Ìdí nìyí tí àwọn èrò náà tún fi lọ bá a, torí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí. 19  Torí náà, àwọn Farisí sọ láàárín ara wọn pé: “Ṣé ẹ rí i pé ẹ ò ṣe àṣeyọrí kankan. Ẹ wò ó! Gbogbo ayé ti gba tiẹ̀.”+ 20  Àwọn Gíríìkì kan wà lára àwọn tó wá jọ́sìn níbi àjọyọ̀ náà. 21  Torí náà, àwọn yìí wá bá Fílípì,+ ẹni tó wá láti Bẹtisáídà ti Gálílì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “Ọ̀gá, a fẹ́ rí Jésù.” 22  Fílípì wá, ó sì sọ fún Áńdérù. Áńdérù àti Fílípì wá sọ fún Jésù. 23  Àmọ́ Jésù dá wọn lóhùn pé: “Wákàtí náà ti dé tí a máa ṣe Ọmọ èèyàn lógo.+ 24  Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé hóró àlìkámà* kan bọ́ sílẹ̀, kó sì kú, ó ṣì máa jẹ́ ẹyọ hóró kan ṣoṣo; àmọ́ tó bá kú,+ ìgbà yẹn ló máa so èso púpọ̀. 25  Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn ẹ̀mí* rẹ̀ ń pa á run, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá kórìíra ẹ̀mí* rẹ̀+ nínú ayé yìí máa pa á mọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.+ 26  Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìránṣẹ́ fún mi, kó máa tẹ̀ lé mi, ibi tí mo bá sì wà ni ìránṣẹ́ mi náà máa wà.+ Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìránṣẹ́ fún mi, Baba máa bọlá fún un. 27  Ní báyìí, ìdààmú bá mi,*+ kí sì ni kí n sọ? Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí.+ Síbẹ̀, torí èyí ni mo fi wá sí wákàtí yìí. 28  Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ni ohùn kan+ bá dún láti ọ̀run pé: “Mo ti ṣe é lógo, màá sì tún ṣe é lógo.”+ 29  Àwọn èrò tó dúró síbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé ààrá ti sán. Àwọn míì sọ pé: “Áńgẹ́lì kan ti bá a sọ̀rọ̀.” 30  Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe torí tèmi ni ohùn yìí ṣe dún, torí tiyín ni. 31  Ní báyìí, à ń ṣèdájọ́ ayé yìí; ní báyìí, a máa lé alákòóso ayé yìí + jáde.+ 32  Síbẹ̀, tí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé,+ màá fa onírúurú èèyàn sọ́dọ̀ ara mi.” 33  Ní tòótọ́, ó ń sọ èyí láti jẹ́ kí wọ́n mọ irú ikú tó máa tó kú.+ 34  Àwọn èrò náà wá dá a lóhùn pé: “A gbọ́ látinú Òfin pé Kristi máa wà títí láé.+ Kí ló dé tí o wá sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè?+ Ta ni Ọmọ èèyàn yìí?” 35  Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ìmọ́lẹ̀ máa wà láàárín yín fúngbà díẹ̀ sí i. Ẹ rìn nígbà tí ẹ ṣì ní ìmọ́lẹ̀ náà, kí òkùnkùn má bàa borí yín; ẹnikẹ́ni tó bá ń rìn nínú òkùnkùn kò mọ ibi tí òun ń lọ.+ 36  Nígbà tí ẹ ṣì ní ìmọ́lẹ̀, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú ìmọ́lẹ̀ náà, kí ẹ lè di ọmọ ìmọ́lẹ̀.”+ Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ fara pa mọ́ fún wọn. 37  Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì níwájú wọn, wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, 38  kí ọ̀rọ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: “Jèhófà,* ta ló ti nígbàgbọ́ nínú ohun tó gbọ́ lọ́dọ̀ wa?*+ Ní ti apá Jèhófà,* ta la ti ṣí i payá fún?”+ 39  Ìdí tí wọn ò fi gbà gbọ́ ni pé Àìsáyà tún sọ pé: 40  “Ó ti fọ́ ojú wọn, ó sì ti mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran, kí ọkàn wọn má sì lóye, kí wọ́n lè yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.”+ 41  Àìsáyà sọ àwọn nǹkan yìí torí pé ó rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+ 42  Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn alákòóso pàápàá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lóòótọ́,+ àmọ́ wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí àwọn Farisí, kí wọ́n má bàa lé wọn kúrò nínú sínágọ́gù;+ 43  torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo èèyàn pàápàá ju ògo Ọlọ́run lọ.+ 44  Àmọ́ Jésù gbóhùn sókè, ó sì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi, kò ní ìgbàgbọ́ nínú èmi nìkan, àmọ́ ó tún ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tó rán mi;+ 45  ẹnikẹ́ni tó bá sì rí mi, ó rí Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ 46  Mo wá sínú ayé bí ìmọ́lẹ̀,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú mi má bàa wà nínú òkùnkùn.+ 47  Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa á mọ́, mi ò ní dá a lẹ́jọ́; torí pé mi ò wá láti dá ayé lẹ́jọ́, àmọ́ láti gba ayé là.+ 48  Ẹnikẹ́ni tí kò bá kà mí sí, tí kò sì gba àwọn ọ̀rọ̀ mi ní ẹni tó máa dá a lẹ́jọ́. Ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ló máa dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn. 49  Torí èrò ara mi kọ́ ni mò ń sọ, àmọ́ Baba tó rán mi fúnra rẹ̀ ti fún mi ní àṣẹ kan nípa ohun tí màá wí àti ohun tí màá sọ.+ 50  Mo sì mọ̀ pé àṣẹ rẹ̀ túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.+ Torí náà, ohunkóhun tí mo bá sọ, bí Baba ṣe sọ fún mi gẹ́lẹ́ ni mo sọ ọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “rọ̀gbọ̀kú sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀.”
Ìyẹn, pọ́n-ùn ti àwọn ará Róòmù, nǹkan bíi gíráàmù 327. Wo Àfikún B14.
Tàbí “agódóńgbó.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “nínú ìròyìn wa?”