Jóòbù 20:1-29
20 Sófárì+ ọmọ Náámà fèsì pé:
2 “Ìdí nìyí tí àwọn èrò tó ń dà mí láàmú fi mú kí n fèsì,Nítorí ìdààmú tó bá mi.
3 Mo ti gbọ́ ìbáwí tí o fi bú mi;Òye mi* sì mú kí n fèsì.
4 Ó dájú pé o gbọ́dọ̀ ti mọ èyí tipẹ́,Torí ó ti wà bẹ́ẹ̀ látìgbà tí èèyàn* ti wà ní ayé,+
5 Pé igbe ayọ̀ ẹni burúkú kì í pẹ́Àti pé ìgbà díẹ̀ ni inú ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* fi máa ń dùn.+
6 Bí títóbi rẹ̀ tiẹ̀ ga dé ọ̀run,Tí orí rẹ̀ sì kan sánmà,
7 Ó máa ṣègbé títí láé bí ìgbẹ́ òun fúnra rẹ̀;Àwọn tó ti ń rí i máa sọ pé, ‘Ibo ló wà?’
8 Ó máa fò lọ bí àlá, wọn ò sì ní rí i;A máa lé e lọ, bí ìran òru.
9 Ojú tó fìgbà kan rí i kò ní rí i mọ́,Àyè rẹ̀ ò sì ní rí i mọ́.+
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá ojúure lọ́dọ̀ aláìní,Ọwọ́ ara rẹ̀ sì máa dá ọrọ̀ rẹ̀ pa dà.+
11 Okun ìgbà èwe kún inú àwọn egungun rẹ̀,Àmọ́, ó* máa bá a dùbúlẹ̀ sínú erùpẹ̀ lásán.
12 Tí ohun tó burú bá dùn lẹ́nu rẹ̀,Tó bá fi pa mọ́ sábẹ́ ahọ́n rẹ̀,
13 Tó bá ń gbádùn rẹ̀, tí kò sì gbé e mì,Àmọ́ tó ṣì fi í sẹ́nu,
14 Oúnjẹ rẹ̀ máa kan nínú rẹ̀;Ó máa dà bí oró* ṣèbé nínú rẹ̀.
15 Ó ti gbé ọrọ̀ mì, àmọ́ ó máa pọ̀ ọ́;Ọlọ́run máa kó o jáde nínú ikùn rẹ̀.
16 Ó máa fa oró ṣèbé mu;Eyín* paramọ́lẹ̀ máa pa á.
17 Kò ní rí odò tó ń ṣàn láé,Ọ̀gbàrá oyin àti bọ́tà.
18 Ó máa dá ẹrù rẹ̀ pa dà láìlò ó;*Kò ní gbádùn ọrọ̀ tó bá rí látinú òwò rẹ̀.+
19 Torí ó ti tẹ aláìní rẹ́, ó sì pa á tì;Ó ti gba ilé tí kò kọ́.
20 Àmọ́ kò ní ní àlàáfíà rárá nínú ara rẹ̀;Ọrọ̀ rẹ̀ kò ní gbà á sílẹ̀.
21 Ohunkóhun ò ní ṣẹ́ kù fún un láti jẹ;Ìdí nìyẹn tí aásìkí rẹ̀ kò fi ní tọ́jọ́.
22 Tí ọrọ̀ rẹ̀ bá pọ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àníyàn máa gbà á lọ́kàn;Gbogbo agbára ni àjálù máa fi kọ lù ú.
23 Bó ṣe ń fi nǹkan síkùn,Ọlọ́run* máa bínú sí i gidigidi,Ó máa rọ̀jò rẹ̀ lé e lórí wọnú ìfun rẹ̀.
24 Tó bá ń sá fún àwọn ohun ìjà irin,Àwọn ọfà tí wọ́n fi ọrun bàbà ta máa gún un.
25 Ó fa ọfà kan yọ láti ẹ̀yìn rẹ̀,Ohun ìjà tó ń dán yinrin látinú òróòro rẹ̀,Jìnnìjìnnì sì bò ó.+
26 Òkùnkùn biribiri ń dúró de àwọn ìṣúra rẹ̀;Iná tí ẹnì kankan ò fẹ́ atẹ́gùn sí máa jẹ ẹ́ run;Àjálù máa bá ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù nínú àgọ́ rẹ̀.
27 Ọ̀run máa tú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ síta;Ayé máa dìde sí i.
28 Àkúnya omi máa gbé ilé rẹ̀ lọ;Ọ̀gbàrá máa pọ̀ gan-an ní ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.*
29 Èyí ni ìpín ẹni burúkú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,Ogún tí Ọlọ́run ti pín fún un.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Ẹ̀mí kan látinú òye mi.”
^ Tàbí “aráyé; Ádámù.”
^ Tàbí “apẹ̀yìndà.”
^ Ìyẹn, okun rẹ̀.
^ Tàbí “òróòro.”
^ Ní Héb., “Ahọ́n.”
^ Ní Héb., “kò sì ní gbé e mì.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Ní Héb., “rẹ̀.”