Jóòbù 31:1-40

  • Jóòbù gbèjà ìwà títọ́ rẹ̀ (1-40)

    • “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú” (1)

    • Ó ní kí Ọlọ́run wọn òun (6)

    • Kì í ṣe alágbèrè (9-12)

    • Kò nífẹ̀ẹ́ owó (24, 25)

    • Kì í ṣe abọ̀rìṣà (26-28)

31  “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú.+ Ṣé ó wá yẹ kí n máa tẹjú mọ́ wúńdíá?+   Kí ló wá máa jẹ́ ìpín mi látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lókè,Ogún wo ni màá gbà látọ̀dọ̀ Olódùmarè lókè?   Ṣebí jàǹbá ń dúró de ẹni burúkú,Àjálù sì ń dúró de àwọn aṣebi?+   Ṣebí ó ń rí àwọn ọ̀nà mi,+Tó sì ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?   Ṣé mo ti rìn nínú àìṣòótọ́* rí? Ṣé ẹsẹ̀ mi ti yára ṣe ẹ̀tàn ni?+   Kí Ọlọ́run wọ̀n mí lórí òṣùwọ̀n tó péye;+Ó máa wá mọ ìwà títọ́ mi.+   Tí ẹsẹ̀ mi bá yà kúrò lọ́nà,+Tàbí tí ọkàn mi bá tẹ̀ lé ojú mi,+Tàbí tí ọwọ́ mi di aláìmọ́,   Kí n fún irúgbìn, kí ẹlòmíì sì jẹ ẹ́,+Kí wọ́n sì fa ohun tí mo gbìn* tu.   Tí ọkàn mi bá ti fà sí obìnrin kan,+Tí mo sì lúgọ+ sẹ́nu ọ̀nà ọmọnìkejì mi, 10  Kí ìyàwó mi lọ ọkà fún ọkùnrin míì,Kí àwọn ọkùnrin míì sì bá a lò pọ̀.*+ 11  Torí ìwà àìnítìjú nìyẹn,Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn adájọ́+ gbọ́dọ̀ torí ẹ̀ jẹni níyà. 12  Ó máa jẹ́ iná tó ń jẹ nǹkan run tó sì ń run nǹkan,*+Tó ń run gbòǹgbò èso mi látòkè délẹ̀ pàápàá.* 13  Tí mi ò bá ka ẹ̀tọ́ àwọn ìránṣẹ́kùnrin tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn mí,* 14  Kí ni mo lè ṣe tí Ọlọ́run bá kò mí lójú? Kí ni mo lè sọ tó bá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?+ 15  Ṣebí Ẹni tó dá mi nínú ilé ọlẹ̀ ló dá àwọn náà?+ Ǹjẹ́ kì í ṣe Ẹnì kan náà ló mọ wá kí wọ́n tó bí wa?*+ 16  Tí mo bá kọ̀ láti fún àwọn aláìní ní ohun tí wọ́n fẹ́,+Tàbí tí mo mú kí opó ba ojú jẹ́;*+ 17  Tí mo bá dá jẹ oúnjẹ mi,Tí mi ò fún àwọn ọmọ aláìlóbìí+ nínú rẹ̀; 18  (Torí láti ìgbà ọ̀dọ́ mi ni ọmọ aláìlóbìí* ti wà lọ́dọ̀ mi bí ẹni pé èmi ni bàbá rẹ̀,Mo sì ń tọ́jú opó* láti kékeré.*) 19  Tí mo bá rí ẹnikẹ́ni tó ń ṣègbé torí kò ní aṣọ,Tàbí aláìní tí kò ní ohun tó máa fi bora;+ 20  Tí kò* bá súre fún mi,+Bó ṣe ń fi irun àgùntàn mi mú kí ara rẹ̀ móoru; 21  Tí mo bá fi ẹ̀ṣẹ́ mi halẹ̀ mọ́ ọmọ aláìlóbìí,+Nígbà tó nílò ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnubodè ìlú;*+ 22  Kí apá* mi yẹ̀ kúrò ní èjìká mi,Kí apá mi sì kán ní ìgúnpá.* 23  Torí ẹ̀rù àjálù látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bà mí,Mi ò sì lè dúró níwájú iyì rẹ̀. 24  Tí mo bá gbẹ́kẹ̀ lé wúrà,Àbí tí mo sọ fún wúrà tó dáa pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi!’+ 25  Tó bá jẹ́ ọrọ̀ rẹpẹtẹ+ tí mo ní ló ń fún mi láyọ̀,Torí mo ti kó ọ̀pọ̀ ohun ìní jọ;+ 26  Tí mo bá rí i tí oòrùn ń ràn,*Tàbí tí òṣùpá ń lọ nínú iyì rẹ̀;+ 27  Tí ọkàn mi wá ń dọ́gbọ́n fà sí wọn,Tí mo sì fẹnu ko ọwọ́ mi láti jọ́sìn wọn;+ 28  Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ torí ẹ̀ jẹni níyà ni,Torí màá ti fìyẹn sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ lókè. 29  Ṣé inú mi ti dùn rí torí pé ọ̀tá mi pa run,+Tàbí kí n fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí ohun burúkú ṣẹlẹ̀ sí i? 30  Mi ò jẹ́ kí ẹnu mi mú kí n dẹ́ṣẹ̀ rí,Pé kí n búra pé kí ẹ̀mí* rẹ̀ bọ́.+ 31  Ṣebí àwọn èèyàn tó wà ní àgọ́ mi ti sọ pé,‘Ǹjẹ́ a lè rí ẹnikẹ́ni tí kò tíì jẹ oúnjẹ* rẹ̀ ní àjẹtẹ́rùn?’+ 32  Kò sí àlejò* tó sun ìta mọ́jú;+Mo ṣí ilẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún arìnrìn-àjò. 33  Ṣé mo ti gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ rí bíi ti àwọn èèyàn yòókù,+Pé kí n fi àṣìṣe mi pa mọ́ sínú àpò aṣọ mi? 34  Ṣé mo bẹ̀rù ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máa ṣe,Àbí jìnnìjìnnì bá mi nítorí bí àwọn ìdílé yòókù ṣe ń pẹ̀gàn mi,Tí mo wá dákẹ́, tí ẹ̀rù sì bà mí láti jáde? 35  Ká ní ẹnì kan lè fetí sí mi ni!+ Ǹ bá buwọ́ lùwé sí ohun tí mo sọ.* Kí Olódùmarè dá mi lóhùn!+ Ká ní ẹni tó fẹ̀sùn kàn mí ti kọ ẹ̀sùn náà sínú ìwé ni! 36  Màá gbé e lé èjìká mi,Màá sì dè é mọ́ orí mi bí adé. 37  Màá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ tí mo gbé fún un;Màá fìgboyà lọ bá a, bí ìjòyè ti ń ṣe. 38  Tí ilẹ̀ mi bá ké jáde sí mi,Tí àwọn poro rẹ̀ sì jọ ń sunkún; 39  Tí mo bá ti jẹ èso rẹ̀ láìsan owó,+Tàbí tí mo mú kí àwọn* tó ni ín máa dààmú;+ 40  Kí ẹ̀gún hù jáde fún mi dípò àlìkámà*Àti èpò tó ń rùn dípò ọkà bálì.” Ibí ni ọ̀rọ̀ Jóòbù parí sí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀lú àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn.”
Tàbí “àwọn àtọmọdọ́mọ mi.”
Ní Héb., “kúnlẹ̀ sórí rẹ̀.”
Ní Héb., “iná ajẹnirun.”
Tàbí “fa gbòǹgbò èso mi pàápàá tu.”
Tàbí “pè mí lẹ́jọ́.”
Ní Héb., “nínú ilé ọlẹ̀.”
Ní Héb., “kí ojú opó kọṣẹ́.”
Ní Héb., “látinú ilé ọlẹ̀ ìyá mi.”
Ní Héb., “rẹ̀.”
Ní Héb., “ó.”
Ní Héb., “Tí abẹ́nú rẹ̀ kò.”
Tàbí kó jẹ́, “Nígbà tí mo rí i pé wọ́n tì mí lẹ́yìn ní ẹnubodè ìlú.”
Tàbí “ibi palaba èjìká.”
Tàbí “kúrò ní ojúhò rẹ̀; kúrò ní egungun òkè rẹ̀.”
Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀ ń tàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ẹran.”
Tàbí “àjèjì.”
Tàbí “Ìbuwọ́lùwé mi rèé.”
Tàbí “ọkàn àwọn.”
Tàbí “wíìtì.”