Jóòbù 33:1-33

  • Élíhù bá Jóòbù wí torí ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀ (1-33)

    • Ó rí ìràpadà (24)

    • Kó pa dà ní okun ìgbà ọ̀dọ́ (25)

33  “Àmọ́ ní báyìí, Jóòbù, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi;Fetí sí gbogbo ohun tí mo fẹ́ sọ.   Jọ̀ọ́, wò ó! Mo gbọ́dọ̀ la ẹnu mi;Ahọ́n mi* gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀.   Àwọn ọ̀rọ̀ mi fi òótọ́ ọkàn+ mi hàn,Ètè mi sì ń fi òótọ́ inú sọ ohun tí mo mọ̀.   Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá mi,+Èémí Olódùmarè fúnra rẹ̀ ló sì fún mi ní ìyè.+   Dá mi lóhùn tí o bá lè ṣe bẹ́ẹ̀;Gbèjà ara rẹ níwájú mi; mú ìdúró rẹ.   Wò ó! Bákan náà ni èmi àti ìwọ rí níwájú Ọlọ́run tòótọ́;Amọ̀ ni ó fi mọ+ èmi náà.   Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́ rárá,Má sì jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò ọ́ mọ́lẹ̀ nítorí mi.   Àmọ́, o sọ ọ́ létí mi,Àní mo ṣáà ń gbọ́ tí ò ń sọ pé,   ‘Mo mọ́, mi ò ní ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn;+Mo mọ́, mi ò ní àṣìṣe.+ 10  Àmọ́ Ọlọ́run rí ìdí tó fi yẹ kó ta kò mí;Ó kà mí sí ọ̀tá rẹ̀.+ 11  Ó ti ẹsẹ̀ mi mọ́ inú àbà;Ó ń ṣọ́ gbogbo ọ̀nà mi lójú méjèèjì.’+ 12  Àmọ́ ohun tí o sọ yìí ò tọ́, torí náà, màá dá ọ lóhùn: Ọlọ́run tóbi ju ẹni kíkú+ lọ fíìfíì. 13  Kí nìdí tí o fi ń ṣàròyé nípa Rẹ̀?+ Ṣé torí pé kò fèsì gbogbo ọ̀rọ̀ tí o sọ ni?+ 14  Torí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kejì,Àmọ́ kò sẹ́ni tó ń fiyè sí i, 15  Lójú àlá, nínú ìran òru,+Nígbà tí àwọn èèyàn ti sùn lọ fọnfọn,Bí wọ́n ṣe ń sùn lórí ibùsùn wọn. 16  Lẹ́yìn náà, ó máa ṣí etí wọn,+Ó sì máa tẹ* ìtọ́ni rẹ̀ mọ́ wọn lọ́kàn, 17  Láti yí èèyàn kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,+Kó sì gba èèyàn lọ́wọ́ ìgbéraga.+ 18  Ọlọ́run ò jẹ́ kí ọkàn* rẹ̀ wọnú kòtò,*+Kò jẹ́ kí idà* gba ẹ̀mí rẹ̀. 19  Ìrora téèyàn ń ní lórí ibùsùn rẹ̀ máa ń bá a wí,Bẹ́ẹ̀ sì ni ìnira tó ń bá egungun rẹ̀ léraléra, 20  Tí òun fúnra rẹ̀* fi kórìíra búrẹ́dì gidigidi,* sì kọ oúnjẹ tó dáa + pàápàá. 21  Ẹran ara rẹ̀ ń joro lọ lójú,Egungun rẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ti wá yọ síta.* 22  Ọkàn* rẹ̀ ti sún mọ́ kòtò;*Ẹ̀mí rẹ̀ sì ti sún mọ́ àwọn tó ń pani. 23  Tí ìránṣẹ́* kan bá wá jíṣẹ́ fún un,Agbẹnusọ kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000),Láti sọ ohun tó tọ́ fún èèyàn, 24  Ọlọ́run máa wá ṣe ojúure sí i, á sì sọ pé,‘Dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, kó má bàa lọ sínú kòtò!*+ Mo ti rí ìràpadà!+ 25  Kí ara rẹ̀ jọ̀lọ̀* ju ti ìgbà ọ̀dọ́;+Kó pa dà sí àwọn ọjọ́ tó lókun nígbà ọ̀dọ́.’+ 26  Ó máa bẹ Ọlọ́run,+ ẹni tó máa gbà á,Ó máa rí ojú Rẹ̀ tòun ti igbe ayọ̀,Ó sì máa dá òdodo Rẹ̀ pa dà fún ẹni kíkú. 27  Ẹni yẹn máa kéde* fún àwọn èèyàn pé,‘Mo ti ṣẹ̀,+ mo sì ti yí ohun tó tọ́ po,Àmọ́ mi ò rí ohun tó tọ́ sí mi gbà.* 28  Ó ti ra ọkàn* mi pa dà kó má bàa lọ sínú kòtò,*+Ẹ̀mí mi sì máa rí ìmọ́lẹ̀.’ 29  Lóòótọ́, Ọlọ́run máa ń ṣe gbogbo nǹkan yìíFún èèyàn, lẹ́ẹ̀mejì, lẹ́ẹ̀mẹta, 30  Láti mú un* pa dà kúrò nínú kòtò,*Kí ìmọ́lẹ̀ ìyè+ lè là á lóye. 31  Fiyè sílẹ̀, Jóòbù! Fetí sí mi! Dákẹ́, kí n sì máa sọ̀rọ̀ lọ. 32  Tí o bá ní nǹkan sọ, fún mi lésì. Sọ̀rọ̀, torí mo fẹ́ fi hàn pé o jàre. 33  Tí kò bá sí ohun tí o fẹ́ sọ, kí o fetí sí mi;Dákẹ́, màá sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Ahọ́n mi pẹ̀lú òkè ẹnu mi.”
Ní Héb., “gbé èdìdì lé.”
Tàbí “ẹ̀mí.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “ohun ìjà (ohun ọṣẹ́).”
Tàbí “Tí ọkàn rẹ̀.”
Ní Héb., “ẹ̀mí rẹ̀.”
Tàbí “hàn síta.”
Tàbí “Ẹ̀mí.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “áńgẹ́lì.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “le.”
Ní Héb., “kọrin.”
Tàbí kó jẹ́, “Mi ò sì jèrè.”
Tàbí “ẹ̀mí.”
Tàbí “sàréè.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “sàréè.”