Àkọsílẹ̀ Mátíù 1:1-25
1 Ìwé ìtàn* nípa Jésù Kristi,* ọmọ Dáfídì,+ ọmọ Ábúráhámù:+
2 Ábúráhámù bí Ísákì;+Ísákì bí Jékọ́bù;+Jékọ́bù bí Júdà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀;
3 Támárì bí Pérésì àti Síírà+ fún Júdà;Pérésì bí Hésírónì;+Hésírónì bí Rámù;+
4 Rámù bí Ámínádábù;Ámínádábù bí Náṣónì;+Náṣónì bí Sálímọ́nì;
5 Ráhábù+ bí Bóásì fún Sálímọ́nì;Rúùtù bí Óbédì fún Bóásì;+Óbédì bí Jésè;+
6 Jésè bí Dáfídì+ ọba.
Ìyàwó Ùráyà bí Sólómọ́nì+ fún Dáfídì;
7 Sólómọ́nì bí Rèhóbóámù;+Rèhóbóámù bí Ábíjà;Ábíjà bí Ásà;+
8 Ásà bí Jèhóṣáfátì;+Jèhóṣáfátì bí Jèhórámù;+Jèhórámù bí Ùsáyà;
9 Ùsáyà bí Jótámù;+Jótámù bí Áhásì;+Áhásì bí Hẹsikáyà;+
10 Hẹsikáyà bí Mánásè;+Mánásè bí Ámọ́nì;+Ámọ́nì bí Jòsáyà;+
11 Jòsáyà+ bí Jekonáyà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nígbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì.+
12 Lẹ́yìn tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì, Jekonáyà bí Ṣéálítíẹ́lì;Ṣéálítíẹ́lì bí Serubábélì;+
13 Serubábélì bí Ábíúdù;Ábíúdù bí Élíákímù;Élíákímù bí Ásórì;
14 Ásórì bí Sádókù;Sádókù bí Ákímù;Ákímù bí Élíúdù;
15 Élíúdù bí Élíásárì;Élíásárì bí Mátáánì;Mátáánì bí Jékọ́bù;
16 Jékọ́bù bí Jósẹ́fù ọkọ Màríà, ẹni tó bí Jésù,+ tí à ń pè ní Kristi.+
17 Torí náà, gbogbo ìran náà látọ̀dọ̀ Ábúráhámù dórí Dáfídì jẹ́ ìran mẹ́rìnlá (14); látọ̀dọ̀ Dáfídì di ìgbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì, ìran mẹ́rìnlá (14); látìgbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì di ìgbà Kristi, ìran mẹ́rìnlá (14).
18 Àmọ́ bí wọ́n ṣe bí Jésù Kristi nìyí. Nígbà tí Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù ń fẹ́ra wọn sọ́nà, ó ṣẹlẹ̀ pé ó lóyún nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́*+ kí wọ́n tó so wọ́n pọ̀.
19 Àmọ́ torí pé olódodo ni Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀, tí kò sì fẹ́ dójú tì í ní gbangba, ó pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́.+
20 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó fara balẹ̀ ro ọ̀rọ̀ yìí, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà* fara hàn án lójú àlá, ó sọ pé: “Jósẹ́fù, ọmọ Dáfídì, má bẹ̀rù láti mú Màríà ìyàwó rẹ lọ sílé, torí oyún inú rẹ̀* jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+
21 Ó máa bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù,*+ torí ó máa gba àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”+
22 Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun tí Jèhófà* sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ lè ṣẹ, pé:
23 “Wò ó! Wúńdíá náà máa lóyún, ó sì máa bí ọmọkùnrin kan, wọ́n máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì,”+ tó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.”+
24 Jósẹ́fù wá jí lójú oorun, ó sì ṣe ohun tí áńgẹ́lì Jèhófà* ní kó ṣe, ó mú ìyàwó rẹ̀ lọ sílé.
25 Àmọ́ kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ títí ó fi bí ọmọkùnrin kan,+ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìlà ìdílé.”
^ Tàbí “Mèsáyà; Ẹni Àmì Òróró.”
^ Tàbí “ipá ìṣiṣẹ́.”
^ Nínú ìgbà 237 tí a lo orúkọ náà, Jèhófà, nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ibi àkọ́kọ́ nìyí tó ti fara hàn nínú ìtumọ̀ yìí. Wo Àfikún A5.
^ Tàbí “èyí tí o lóyún rẹ̀.”
^ Ìtumọ̀ kan náà ló ní pẹ̀lú orúkọ Hébérù náà, Jéṣúà tàbí Jóṣúà, tó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”