Míkà 3:1-12
3 Mo sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́ ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bùÀti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì.+
Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ ohun tó tọ́?
2 Àmọ́ ẹ kórìíra ohun rere,+ ẹ sì fẹ́ràn ohun búburú;+Ẹ bó àwọn èèyàn mi láwọ, ẹ sì ṣí ẹran kúrò lára egungun wọn.+
3 Ẹ tún jẹ ẹran ara àwọn èèyàn mi,+Ẹ sì bó wọn láwọ,Ẹ fọ́ egungun wọn, ẹ sì rún un sí wẹ́wẹ́,+Bí ohun tí wọ́n sè nínú ìkòkò,* bí ẹran nínú ìkòkò oúnjẹ.
4 Ní àkókò yẹn, wọ́n á ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,Àmọ́ kò ní dá wọn lóhùn.
Ó máa fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wọn ní àkókò yẹn,+Torí ìwà burúkú wọn.+
5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí nípa àwọn wòlíì tó ń ṣi àwọn èèyàn mi lọ́nà,+Tí wọ́n ń kéde ‘Àlàáfíà!’+ nígbà tí wọ́n bá ń rí nǹkan jẹ,*+Àmọ́ tí wọ́n ń gbógun ti* ẹni tí kò fún wọn ní nǹkan kan jẹ:
6 ‘Ilẹ̀ máa ṣú lọ́dọ̀ yín;+ kò ní sí ìran;+Òkùnkùn nìkan lẹ máa rí, ẹ kò ní lè woṣẹ́.
Oòrùn yóò wọ̀ lórí àwọn wòlíì,Ojúmọmọ yóò sì ṣókùnkùn fún wọn.+
7 Ojú máa ti àwọn tó ń rí ìran,+Ìjákulẹ̀ sì máa bá àwọn woṣẹ́woṣẹ́.
Gbogbo wọn máa bo ẹnu* wọn,Torí pé Ọlọ́run kò ní dá wọn lóhùn.’”
8 Ní tèmi, ẹ̀mí Jèhófà ti fún mi ní agbára,Ó ti jẹ́ kí n lè ṣe ìdájọ́ òdodo, ó sì ti fún mi lókun,Kí n lè sọ fún Jékọ́bù nípa ọ̀tẹ̀ tó dì, kí n sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fún un.
9 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bùÀti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì,+Tí ẹ kórìíra ìdájọ́ òdodo, tí ẹ sì ń yí gbogbo ọ̀rọ̀ po,+
10 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ kọ́ Síónì, tí ẹ sì ń fi àìṣòdodo kọ́ Jerúsálẹ́mù.+
11 Àwọn olórí* rẹ̀ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó dájọ́,+Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń gba owó kí wọ́n tó kọ́ni,+Àwọn wòlíì rẹ̀ ń gba owó* kí wọ́n tó woṣẹ́.+
Síbẹ̀ wọ́n gbára lé Jèhófà,* wọ́n ń sọ pé:
“Ṣebí Jèhófà wà pẹ̀lú wa?+
Àjálù kankan ò lè dé bá wa.”+
12 Nítorí yín,Wọ́n á túlẹ̀ Síónì bíi pápá,Jerúsálẹ́mù á di àwókù,+Òkè Ilé* náà á sì dà bí àwọn ibi gíga nínú igbó.*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “tí wọ́n bá ń rí nǹkan bù jẹ.”
^ Ní Héb., “sọ ogun di mímọ́ fún.”
^ Ní Héb., “irunmú.”
^ Tàbí “wọ́n ń sọ pé àwọn gbára lé Jèhófà.”
^ Tàbí “fàdákà.”
^ Ní Héb., “orí.”
^ Tàbí “Òkè tẹ́ńpìlì.”
^ Tàbí “òkìtì igi.”