Míkà 5:1-15
5 “Ò ń fi nǹkan ya ara rẹ,Ìwọ ọmọbìnrin tí wọ́n gbógun tì;Wọ́n ti pàgọ́ tì wá.+
Wọ́n fi ọ̀pá lu onídàájọ́ Ísírẹ́lì ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.+
2 Ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà,+Ìwọ tó kéré jù láti wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Júdà,Inú rẹ ni ẹni tí mo fẹ́ kó ṣàkóso Ísírẹ́lì ti máa jáde wá,+Ẹni tó ti wà láti ìgbà àtijọ́, láti àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́.
3 Torí náà, ó máa yọ̀ǹda wọnTítí di àkókò tí ẹni tó fẹ́ bímọ fi máa bímọ.
Àwọn arákùnrin rẹ̀ tó kù sì máa pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
4 Ó máa dìde dúró, Jèhófà yóò sì fún un lókun láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn,+Nípasẹ̀ orúkọ ńlá Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.
Ààbò yóò sì wà lórí wọn,+Torí àwọn èèyàn máa mọ̀ ní gbogbo ìkángun ayé pé ó tóbi lọ́ba.+
5 Ó sì máa mú àlàáfíà wá.+
Tí àwọn ará Ásíríà bá gbógun tì wá, tí wọ́n sì tẹ àwọn ilé gogoro wa tó láàbò mọ́lẹ̀,+A máa rán olùṣọ́ àgùntàn méje sí wọn, àní àwọn ìjòyè* mẹ́jọ látinú aráyé.
6 Wọ́n á fi idà ṣe olùṣọ́ àgùntàn ilẹ̀ Ásíríà,+Àti níbi àbáwọ ilẹ̀ Nímírọ́dù.+
Ó máa gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà+
Tí wọ́n bá gbógun tì wá, tí wọ́n sì tẹ ìlú wa mọ́lẹ̀.
7 Láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn, àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Jékọ́bùMáa dà bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,Bí ọ̀wààrà òjò lórí ewéko,Tí kì í retí èèyàn
Tàbí kó dúró de ọmọ aráyé.
8 Àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Jékọ́bù máa wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,Láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn,Bíi kìnnìún láàárín àwọn ẹran inú igbó,Bí ọmọ kìnnìún* láàárín agbo àgùntàn,Tó kọjá, tó bẹ́ mọ́ ẹran, tó sì fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ;Kò sì sí ẹni tó lè gbà wọ́n sílẹ̀.
9 Ọwọ́ yín máa lékè àwọn elénìní yín,Gbogbo ọ̀tá yín sì máa pa run.”
10 Jèhófà kéde pé: “Ní ọjọ́ yẹn,Màá pa àwọn ẹṣin yín run láàárín yín, màá sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin yín run.
11 Màá run àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ yín,Màá sì wó gbogbo ibi olódi yín lulẹ̀.
12 Màá fòpin sí iṣẹ́ oṣó tí ẹ̀ ń ṣe,*Kò sì ní sí onídán kankan láàárín yín mọ́.+
13 Màá run àwọn ère gbígbẹ́ àti àwọn ọwọ̀n yín kúrò láàárín yín,Ẹ kò sì ní forí balẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ yín mọ́.+
14 Màá fa àwọn òpó òrìṣà*+ yín tu,Màá sì run àwọn ìlú yín.
15 Ìbínú àti ìrunú ni màá fi gbẹ̀san
Lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ya aláìgbọràn.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “agbo ilé.”
^ Tàbí “olórí.”
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Ní Héb., “tó wà lọ́wọ́ rẹ.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.