Sáàmù 49:1-20
Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin.
49 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin èèyàn.
Ẹ fiyè sí i, gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ayé,*
2 Ẹni kékeré àti ẹni ńlá,*Àti olówó àti tálákà.
3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,Àṣàrò ọkàn mi+ yóò sì fi òye hàn.
4 Màá fiyè sí òwe;Màá fi háàpù pa àlọ́ mi.
5 Kí nìdí tí màá fi máa bẹ̀rù nígbà wàhálà,+Nígbà tí ìwà ibi* àwọn tó fẹ́ lé mi kúrò yí mi ká?
6 Àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ wọn,+Tí wọ́n sì ń fi ọrọ̀ rẹpẹtẹ wọn fọ́nnu,+
7 Kò sí ìkankan nínú wọn tó lè ra arákùnrin kan pa dàTàbí tí ó lè fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀,+
8 (Iye owó ìràpadà ẹ̀mí* wọn ṣe iyebíyeDébi pé ó kọjá ohun tí ọwọ́ wọn lè tẹ̀);
9 Tí á fi wà láàyè títí láé, tí kò sì ní rí kòtò.*+
10 Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé àwọn ọlọ́gbọ́n pàápàá ń kú;Àwọn òmùgọ̀ àti àwọn aláìnírònú ń ṣègbé pa pọ̀,+Wọ́n á sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì.+
11 Ohun tó ń wù wọ́n lọ́kàn ni pé kí ilé wọn wà títí láé,Kí àgọ́ wọn wà láti ìran dé ìran.
Wọ́n ti fi orúkọ wọn pe àwọn ilẹ̀ wọn.
12 Àmọ́ bí a tilẹ̀ dá èèyàn lọ́lá, kò lè máa wà nìṣó;+Kò sàn ju àwọn ẹranko tó ń ṣègbé.+
13 Bí ọ̀nà àwọn òmùgọ̀ ṣe rí nìyí+Àti ti àwọn tó ń tẹ̀ lé wọn, tí inú wọn ń dùn sí ọ̀rọ̀ asán tí wọ́n ń sọ. (Sélà)
14 A ti yàn wọ́n bí àgùntàn láti lọ sí Isà Òkú.*
Ikú yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn;Àwọn adúróṣinṣin yóò ṣàkóso wọn+ ní òwúrọ̀.
Wọ́n á pa rẹ́, tí a ò ní rí ipa wọn mọ́;+Isà Òkú*+ ló máa di ilé wọn dípò ààfin.+
15 Àmọ́, Ọlọ́run máa rà mí* pa dà kúrò lọ́wọ́ agbára* Isà Òkú,*+Nítorí ó máa dì mí mú. (Sélà)
16 Má bẹ̀rù nítorí pé ẹnì kan di ọlọ́rọ̀,Nítorí pé ògo ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i,
17 Nítorí tí ó bá kú, kò lè mú ohunkóhun lọ;+Ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀ kalẹ̀ lọ.+
18 Nítorí nígbà ayé rẹ̀, ó ń yin ara* rẹ̀.+
(Aráyé máa ń yin èèyàn nígbà tó bá láásìkí.)+
19 Àmọ́ nígbẹ̀yìn, yóò dara pọ̀ mọ́ ìran àwọn baba ńlá rẹ̀.
Wọn kò ní rí ìmọ́lẹ̀ mọ́ láé.
20 Ẹni tí kò bá lóye èyí, bí a tilẹ̀ dá a lọ́lá,+Kò sàn ju àwọn ẹranko tó ń ṣègbé.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “inú ètò àwọn nǹkan.”
^ Ní Héb., “Ẹ̀yin ọmọ ìran èèyàn àti ẹ̀yin ọmọ èèyàn.”
^ Ní Héb., “àṣìṣe.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “sàréè.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “kúrò ní ọwọ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”