ÌBÉÈRÈ 19
Kí Ló Wà Nínú Oríṣiríṣi Ìwé Tó Para Pọ̀ Di Bíbélì?
ÌWÉ MÍMỌ́ LÉDÈ HÉBÉRÙ (“MÁJẸ̀MÚ LÁÉLÁÉ”)
ÌWÉ MÁRÙN-ÚN ÀKỌ́KỌ́:
Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Nọ́ńbà, Diutarónómì
Ìtàn látìgbà ìṣẹ̀dá títí tá a fi dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀
ÀWỌN ÌWÉ ÌTÀN (ÌWÉ MÉJÌLÁ):
Jóṣúà, Àwọn Onídàájọ́, Rúùtù
Ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà
1 Sámúẹ́lì àti 2 Sámúẹ́lì, 1 Àwọn Ọba àti 2 Àwọn Ọba, 1 Kíróníkà àti 2 Kíróníkà
Ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì títí dìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run
Ẹ́sírà, Nehemáyà, Ẹ́sítà
Ìtàn àwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì
ÀWỌN ÌWÉ EWÌ (ÌWÉ MÁRÙN-ÚN):
Jóòbù, Sáàmù, Òwe, Oníwàásù, Orin Sólómọ́nì
Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àtàwọn orin
ÀWỌN ÌWÉ ÀSỌTẸ́LẸ̀ (ÌWÉ MẸ́TÀDÍNLÓGÚN):
Àìsáyà, Jeremáyà, Ìdárò, Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì, Hósíà, Jóẹ́lì, Émọ́sì, Ọbadáyà, Jónà, Míkà, Náhúmù, Hábákúkù, Sefanáyà, Hágáì, Sekaráyà, Málákì
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kan àwọn èèyàn Ọlọ́run
ÌWÉ MÍMỌ́ KRISTẸNI LÉDÈ GÍRÍÌKÌ (“MÁJẸ̀MÚ TUNTUN”)
ÀWỌN ÌWÉ ÌHÌN RERE (ÌWÉ MẸ́RIN):
Mátíù, Máàkù, Lúùkù, Jòhánù
Ìtàn ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù
ÌṢE ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ (ÌWÉ KAN):
Ìtàn bí ìjọ Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ àti iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì
ÀWỌN LẸ́TÀ (ÌWÉ MỌ́KÀNLÉLÓGÚN):
Róòmù, 1 Kọ́ríńtì àti 2 Kọ́ríńtì, Gálátíà, Éfésù, Fílípì, Kólósè, 1 Tẹsalóníkà àti 2 Tẹsalóníkà
Lẹ́tà sáwọn ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
1 Tímótì àti 2 Tímótì, Títù, Fílémónì
Lẹ́tà sáwọn Kristẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Hébérù, Jémíìsì, 1 Pétérù àti 2 Pétérù, 1 Jòhánù, 2 Jòhánù àti 3 Jòhánù, Júùdù
Lẹ́tà sí gbogbo Kristẹni
ÌFIHÀN (ÌWÉ KAN):
Oríṣiríṣi ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi han àpọ́sítélì Jòhánù