ÌBÉÈRÈ 13
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Iṣẹ́?
“Ǹjẹ́ o ti rí ọkùnrin tó já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀? Yóò dúró níwájú àwọn ọba; kò ní dúró níwájú àwọn èèyàn yẹpẹrẹ.”
“Kí ẹni tó ń jalè má jalè mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, kó máa ṣiṣẹ́ kára, kó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kó lè ní nǹkan tó máa fún ẹni tí kò ní.”
“Kí kálukú máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”