Bí Ọkọ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Lílu Ìyàwó Rẹ̀
Àpẹẹrẹ #1: Àwọn òbí Fọlákẹ́ * wá kí òun àti ọkọ rẹ̀ nílé. Inú wọn dùn gan-an, wọ́n sì gbádùn ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ sọ. Ṣe ni wọ́n ń rẹ́rìn-ín músẹ́ bí wọ́n ṣe ń wo bí ọkùnrin yìí ṣe ń kẹ́ ọmọ wọn. Inú wọn dùn pé ọkọ gidi lọmọ àwọn fẹ́.
Àpẹẹrẹ #2: Inú tún bẹ̀rẹ̀ sí í bí Fẹ́mi gan-an. Ó gbá ìyàwó rẹ̀ lójú bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó tún gbá a nípàá, ó fìbínú fa irun rẹ̀, ó sì ń fi orí rẹ̀ gbá ògiri léraléra.
Ó LÈ yà ẹ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé tọkọtaya kan náà la sọ̀rọ̀ wọn nínú àpẹẹrẹ méjèèjì yìí.
Fẹ́mi máa ń ṣojú ayé táwọn ẹlòmíì bá wà níbẹ̀ tàbí tí àwọn àná rẹ̀ bá wá kí i. Àmọ́ tí wọ́n bá ti lọ tán, á wá máa hùwà bí ẹhànnà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ tó máa ń lu ìyàwó wọn ṣe máa ń ṣe.
Inú ìdílé tí wọ́n ti máa ń lu ara wọn nílùkulù ni ọ̀pọ̀ èèyàn bíi Fẹ́mi dàgbà sí, torí náà, wọn ò rí nǹkan tó burú nínú kí ọkọ máa lu ìyàwó rẹ̀. Àmọ́ ìwà tó burú jáì ni.
Abájọ tí àwọn èèyàn kì í ṣeé fi ojú tó dáa wo ọkọ tó bá ń lu ìyàwó rẹ̀.Síbẹ̀ iye àwọn ọkọ tó ń lu ìyàwó wọn ṣì pọ̀ rẹpẹtẹ. Ìwádìí kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, láàárín ìṣẹ́jú kan lójoojúmọ́, èèyàn tó lé ní mẹ́rìndínlógún [16] ló máa ń pe ọ́fíìsì tí ìjọba gbé kalẹ̀ láti pèsè ìrànwọ́ fún àwọn aya tí ọkọ wọn ń lù. Ìṣòro yìí ti wá dà bí àjàkálẹ̀ àrùn tó ti dé ibi gbogbo kárí ayé. Èyí tá a rí la kúkú ń sọ, àìmọye irú ìwà yìí ló ń wáyé, àmọ́ tí a kò mọ̀. *
Irú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀ máa ń kọni lóminú gan-an. Ó tiẹ̀ lè mú kéèyàn máa ṣe kàyéfì pé báwo ni ọkùnrin kan ṣe lè máa hu irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀ sí ìyàwó rẹ̀? Báwo la ṣe lè ran irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè yíwà pa dà?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe ìwé yìí gbà pé ìmọ̀ràn Bíbélì lè ran àwọn ọkọ tó ń lu ìyàwó wọn lọ́wọ́ láti yíwà pa dà. Lóòótọ́, irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ kò rọrùn rárá. Àmọ́, ó ṣeé ṣe! Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí àwọn kan tó ya ẹhànnà tẹ́lẹ̀ di èèyàn jẹ́jẹ́ àti onínuure. (Kólósè 3:8-10) Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Tádé àti Fadékẹ́.
Báwo ni àárín yín ṣe rí nígbà tẹ́ ẹ kọ́kọ́ fẹ́ra?
Fadékẹ́: Lálẹ́ ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó, Tádé fọ́ mi létí, ọ̀sẹ̀ kan gbáko ni mo fi jẹ̀rora àpá tó dá sí mi lẹ́rẹ̀kẹ́. Ó bẹ̀ mí gan-an, ó sì ṣèlérí pé òun kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Àmọ́ àìmọye ìgbà ló tún ṣe bẹ́ẹ̀.
Tádé: Inú máa ń tètè bí mi gan-an. Bí àpẹẹrẹ, tí oúnjẹ ò bá tètè délẹ̀, mo lè
gbaná jẹ. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo fi ìdí ìbọn lu ìyàwó mi. Lọ́jọ́ kan, mo lù ú gan-an débi pé, ṣe ni mo rò pé ó ti kú. Ọjọ́ kan wà tí mo tún halẹ̀ mọ́ ọn pé màá fi òbẹ dúnbú ọmọ wa ọkùnrin.Fadékẹ́: Ẹ̀rù máa ń bà mí nígbà gbogbo. Nígbà míì, mo máa ń sá kúrò nílé títí tí ìbínú ọkọ mi fi máa rọlẹ̀. Àwọn èébú tó máa bú mi tiẹ̀ tún le ju lílù tó máa ń lù mí lọ.
Ọ̀gbẹ́ni Tádé, ṣé bẹ́ ẹ ṣe máa ń hùwà láti kékeré nìyẹn?
Tádé: Láti kékeré ni ìwà yìí ti mọ́ mi lára. Inú ìdílé oníjàgídíjàgan ni mo dàgbà sí. Gbogbo ìgbà ni bàbá mi máa ń lu ìyá mi níṣojú àwa ọmọ. Nígbà tí wọ́n kọra wọn sílẹ̀, ọkùnrin tí màmá mi tún fẹ́ máa ń lù ú. Ó tiẹ̀ tún fipá bá èmi àti ẹ̀gbọ́n mi lò pọ̀. Ó sì ṣẹ̀wọ̀n torí ohun tó ṣe yẹn. Àmọ́ mo mọ̀ pé kò yẹ kí n wá torí ìyẹn máa hùwàkiwà.
Fadékẹ́, kí ló dé tẹ́ ò fi ọkùnrin yìí sílẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ìyà tó fi ń jẹ yín?
Fadékẹ́: Ẹ̀rù ló ń bà mí. Mo máa ń rò ó lọ́kàn mi pé, ‘Tí mo bá sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó lè pa mí tàbí kó pa àwọn òbí mi. Tí mo bá sì gbé e lọ sílé ẹjọ́, nǹkan lè burú ju bí mo ṣe rò lọ.’
Ìgbà wo wá ni nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà?
Tádé: Ìyàwó mi ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú mi ò kọ́kọ́ dùn sáwọn èèyàn tó mú lọ́rẹ̀ẹ́ yẹn, mo sì ń wá bí mo ṣe fẹ́ gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn. Torí náà, mo tún wá gboró sí i òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, ṣàdédé ni gìrì gbé Daniel, ọmọ wa ọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́rin, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọ̀sẹ̀ mẹ́ta nílé ìwòsàn. Lákòókò yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn ṣe gudugudu méje, wọ́n tiẹ̀ tún bá wa tọ́jú Désọ́lá, ọmọ wa obìnrin ọmọ ọdún mẹ́fà. Ọ̀kan nínú wọn ṣiṣẹ́ mọ́jú níbi iṣẹ́ rẹ̀, síbẹ̀, bó ṣe dé ló wá bá wa dúró ti Daniel, kí Fadékẹ́ lè rí oorun díẹ̀ sùn. Ìwà ọmọlúwàbí táwọn èèyàn yìí hù sí ìdílé mi wú mi lórí, ó sì wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, láìka gbogbo
ìwàkiwà tí mo ti hù sí wọn sí. Ìyẹn jẹ́ kí n rí i pé Kristẹni tòótọ́ ni wọ́n, ni mo bá ní kí wọ́n wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀kọ́ Bíbélì yẹn ló jẹ́ kí n mọ bó ṣe yẹ kí n máa tọ́jú aya mi àtàwọn ohun tí kò yẹ kí n máa ṣe sí i. Bí mi ò ṣe lu ìyàwó mi mọ́ nìyẹn tí mo sì jáwọ́ pátápátá nínú gbogbo ìwàkiwà yẹn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló yí yín lọ́kàn pa dà?
Tádé: Ó pọ̀. 1 Pétérù 3:7 sọ pé kí n máa fi “ọlá” fún aya mi. Gálátíà 5:22, 23 gbà mí nímọ̀ràn pé kí n jẹ́ ‘oníwà tútù’ kí n sì máa ‘kóra mi níjàánu.’ Éfésù 4:31 sọ pé “ọ̀rọ̀ èébú” kò dáa. Hébérù 4:13 sì sọ pé “ohun gbogbo wà ní . . . ṣíṣísílẹ̀ gbayawu” fún Ọlọ́run. Torí náà, tí ẹlòmíì ò bá tiẹ̀ rí mi, Ọlọ́run ń rí gbogbo ìwà tí mò ń hù. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí n yan ọ̀rẹ́ gidi, torí pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ká sòótọ́, àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ní tẹ́lẹ̀ wà lára àwọn tó mú kí n máa hùwàkiwà. Wọ́n gbà pé ó yẹ kéèyàn máa lu ìyàwó “kó lè gba ọkọ rẹ̀ lọ́gàá.”
Báwo wá ni nǹkan ṣe ń lọ sí láàárín yín báyìí?
Fadékẹ́: Ó ti tó ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n [25] báyìí tí ọkọ mi ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Látìgbà yẹn ló ti ń kẹ́ mi, tó sì ń gẹ̀ mí. Ó ti wá nífẹ̀ẹ́ mi dénú, ó sì máa ń gba tèmi rò.
Tádé: Ká sòótọ́, ojú àpá ò lè jọ ojú ara, kò yẹ kí n hu irú ìwàkiwà yẹn sí ìyàwó àtàwọn ọmọ mi. Mò ń retí ìgbà tí ọ̀rọ̀ inú ìwé Aísáyà 65:17 máa ṣe, tí gbogbo ọṣẹ́ tí mo ti ṣe á sì di ohun ìgbàgbé pátápátá.
Ìmọ̀ràn wo lẹ ní fáwọn tọkọtaya tí wọ́n bá nírú ìṣòro yìí?
Tádé: Ọkọ tó bá ń lu aya rẹ̀, tó ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí i tàbí tó ń hùwàkiwà sáwọn ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́, kó sì tètè wá bó ṣe máa jáwọ́ nínú ìwà yẹn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Ohun tó jẹ́ kí èmi lè jáwọ́ nínú ìwàkiwà tó ti mọ́ mi lára yẹn ni ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti bí mo ṣe mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́.
Fadékẹ́: Tó o bá ń fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì tàbí tí ò ń fetí sí ìmọ̀ràn àwọn tó rò pé àwọn mọ ohun tó dáa jù fún ẹ, ò ń tan ara ẹ jẹ ni o. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ gbogbo èèyàn lè máà rí bákan náà, àmọ́ mo dúpẹ́ ní tèmi pé mi ò kọ ọkọ mi sílẹ̀. A ti wá mọwọ́ ara wa gan-an báyìí.
O LÈ JÁWỌ́ NÍNÚ LÍLU AYA RẸ
Bíbélì sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:16) Ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ tó máa ń hùwàkiwà sí ìyàwó wọn, bíi ti Tádé tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ló ti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, tí wọ́n sì ti yí èrò àti ìwà wọn pa dà.
Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ran ìdílé rẹ lọ́wọ́? Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì www.pr2711.com.
^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
^ ìpínrọ̀ 7 Àwọn obìnrin míì wà tó máa ń lu ọkọ wọn nílùkulù. Ṣùgbọ́n, tàwọn ọkùnrin ló pọ̀ jù lára èyí tó wà ní àkọsílẹ̀.