TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
Lẹbẹ Ẹja Àbùùbùtán
ẸJA àbùùbùtán oníké wúwo, ó sì tóbi ju ọkọ̀ àjàgbé ńlá lọ. Àmọ́, tó bá ń lúwẹ̀ẹ́ tó sì ń yí síbi tó wù ú nínú òkun, ṣe ló máa dà bíi pé kò ju ẹja kékeré kan lásán lọ. Kí ló jẹ́ kí ẹja yìí lè máa yára kánkán nínú òkun láìka bó ṣe tóbi tó? Lára ohun tó jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni igun tó wà lára lẹbẹ rẹ̀.
Rò ó wò ná: Ọ̀pọ̀ àwọn àbùùbùtán ni kò sí igun lára lẹbẹ wọn. Àmọ́ àbùùbùtán oníké yàtọ̀ sí gbogbo wọn torí pé igun pọ̀ lára lẹbẹ tirẹ̀, àwọn igun náà sì yọ síta dáadáa. Bí àbùùbùtán yìí ṣe ń wẹ̀ nínú ibú, àwọn igun ara lẹbẹ rẹ̀ máa ń darí ìṣàn omi. Èyí sì máa ń jẹ́ kí ìṣàn omi náà lágbára bí ìgbà tí omi ń ya bọ̀ látòkè. Ó tún máa ń jẹ́ kí ẹja náà lè lúwẹ̀ẹ́ wá sókè nínú ibú, kó fi lẹbẹ rẹ gbá omi sọ́tùn-ún sósì kó sì máa lúwẹ̀ẹ́ láìdáwọ́dúró. Lẹbẹ yìí tó ìdá kan nínú mẹ́ta ara ẹja náà, síbẹ̀, ó máa ń fì í lọ́nà tó yára kánkán bíi pé kò ju lẹbẹ àwọn ẹja kéékèèké lọ.
Àwọn tó ń ṣèwádìí ti ń lo ohun tí wọ́n kíyè sí lára ẹja yìí láti fi ṣe ìtọ́kọ̀ fún ọkọ̀ ojú omi, àwọn ẹ̀rọ amúnáwá tó ń lo omi, ẹ̀rọ tó ń fi atẹ́gùn ṣiṣẹ́ àti abẹ̀bẹ̀ tó wà lórí ọkọ̀ òfuurufú hẹlikọ́pítà.
Kí lèrò rẹ? Ṣé lẹbẹ ẹja àbùùbùtán yìí kàn dédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?