Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìjọba Ọlọ́run

Ìjọba Ọlọ́run

Ṣé inú ọkàn ni Ìjọba Ọlọ́run wà?

“Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọ́run.”​—Máàkù 12:34.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan tó gbajúmọ̀ dáadáa sọ pé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí ni pé kí “Ọlọ́run gba àkóso nínú ọkàn àti ìgbé ayé ẹnì kan.” Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà gbọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run nìyẹn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìṣàkóso gidi kan, kì í ṣe àfiwé kan lásán nípa bí ẹnì kan ṣe ń tẹrí ba fún Ọlọ́run nínú ọkàn rẹ̀. Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé.—Sáàmù 72:8; Dáníẹ́lì 7:14.

Àmọ́ kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó fi sọ pé “ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin”? (Ìkọ̀wé lọ́nà tó dúdú yàtọ̀ jẹ́ tiwa; Lúùkù 17:21, Bibeli Mimọ) Ó dájú pé kì í ṣe pé Jésù ń sọ pé Ìjọba Ọlọ́run wà ní ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Kí nìdí tí kò fi lè sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé àwọn Farisí ló ń bá sọ̀rọ̀ nígbà yẹn. Jésù sì sọ pé wọn ò ní wọnú Ìjọba Ọlọ́run torí pé àgàbàgebè ló kúnnú ìjọsìn wọn, inú Ọlọ́run ò sì dùn sí wọn. (Mátíù 23:13) Àmọ́, ó bá a mu bí Jésù ṣe sọ pé Ìjọba Ọlọ́run “mbẹ ninu nyin” tàbí bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe sọ pé ó wà “ní àárín yín.” Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù tó máa jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn nígbà yẹn.—Lúùkù 17:21.

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

“Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìṣàkóso gidi kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, Jésù Kristi sì ni Ọba rẹ̀. (Mátíù 28:18; 1 Tímótì 6:14, 15) Ohun tí Ìjọba yẹn máa ṣe ni pé ó máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ọ̀run àti ní ayé. (Mátíù 6:10) Torí náà, Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti yanjú ìṣòro àwa èèyàn. Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe ohun tí ìjọba èèyàn ṣe tì.

Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, àlàáfíà máa dé bá gbogbo èèyàn, ọkàn wọn á balẹ̀, wọ́n á sì máa gbádùn ara wọn nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 46:9; Aísáyà 35:1; Míkà 4:4) A ò ní ṣàìsàn, a ò ní kú mọ́, kò sì ní sí àrùn mọ́. (Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:4) Kódà kò ní sí pé èèyàn ń darúgbó mọ́. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.”—Jóòbù 33:25.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ìran yòówù kó o ti wá tàbí ọmọ ìlú yòówù kó o jẹ́, tó o bá ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé kó o ṣe, o lè wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Ṣé ìsapá àwọn èèyàn ló máa mú Ìjọba Ọlọ́run wá?

“Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé.”​— Dáníẹ́lì 2:44.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn kan gbà pé àwọn èèyàn ló máa gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, bí wọ́n sì ṣe máa ṣe é ni pé nínú kí wọ́n mú kí àwọn èèyàn máa ṣe ẹ̀sìn táwọn ń ṣe tàbí kí wọ́n sapá kí àlàáfíà lè wà kárí ayé, kí gbogbo ayé sì máa ṣe nǹkan pa pọ̀.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run ló gbé Ìjọba náà kalẹ̀, kì í ṣe èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà tí Ọlọ́run ń fi Ìjọba náà lọ́lẹ̀, ó sọ pé: “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ.” (Sáàmù 2:6) Èèyàn kọ́ ló máa mú Ìjọba Ọlọ́run wá, wọn ò sì lè dí Ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́, torí pé ọ̀run ni Ìjọba náà á ti máa ṣàkóso lé ayé lórí.—Mátíù 4:17.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI KÀN Ọ́

Ta ni kò wù kó rí i lọ́jọ́ kan pé gbogbo èèyàn wà ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan? O tiẹ̀ ṣeé ṣe kíwọ náà ti sapá torí kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà, àmọ́ tó o sọ̀rètí nù nígbà tọ́wọ́ ẹ ò tẹ ohun tó ò ń wá. Ní báyìí tó o ti mọ̀ pé Ọlọ́run máa fi agbára rẹ̀ darí Ìjọba rẹ̀, á jẹ́ kó o máa lo okun rẹ lọ́nà tó ṣàǹfààní, ìyẹn ni pé kó o sapá láti di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.