OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ilẹ̀ Ayé
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé?
“Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, . . . Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé . . . ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” —Aísáyà 45:18.
OHUN TÁWỌN ÈÈYÀN SỌ
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ilẹ̀ ayé yìí kàn ṣàdédé wà, pé kò sẹ́ni tó dá a. Àwọn onísìn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé ayé lọjà, ọ̀run nilé, ìyẹn ni pé Ọlọ́run ń fi ayé yìí dán wa wò kó lè mọ àwọn tó máa lọ sọ́run rere àtàwọn tó máa lọ sí ọ̀run àpáàdì.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ó sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí . . . olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ìgbà kan ṣoṣo tó dárúkọ ikú ni ìgbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá ṣàìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ìyẹn fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn olóòótọ́ máa tún ilẹ̀ ayé ṣe, kí wọ́n sì máa gbé inú rẹ̀ kánrin kése.
Ṣé ayé máa pa rẹ́?
“Ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; A kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” —Sáàmù 104:5.
OHUN TÁWỌN ÈÈYÀN SỌ
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé ó ṣeé ṣe káwọn àjálù kan pa ayé yìí run tàbí kó sọ ọ́ di ibi tí kò ní ṣeé gbé mọ́. Wọ́n ní ó lẹ̀ jẹ́ òkúta bìrìkìtì kan tí wọ́n ń pè ní asteroid ló máa já lu ayé tàbí kí òkè ayọnáyèéfín kan bú gbàù lọ́nà tó kàmàmà. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé epo tó ń mú kí oòrùn ràn máa tó tán tàbí kí ayé gbóná débi tí gbogbo nǹkan á bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́. Ó sì lè jẹ́ àfọwọ́fà àwọn èèyàn pàápàá, bóyá kí ogun dé káwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ju bọ́ǹbù runlérùnnà tàbí káwọn apániláyà lọ tú àrùn burúkú sínú afẹ́fẹ́.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Èrò tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé yìí ò tíì yí pa dà. Bíbélì sọ pé: “Ayé dúró títí láé.” (Oníwàásù 1:4, BÍBÉLÌ MÍMỌ́) Ìwé Mímọ́ tún fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
KÍ NÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ?
Àwọn kan ti walé ayé mọ́yà torí wọ́n rò pé ayé ọ̀hún ò kúkú ní í pẹ́ pa run. Àwọn kan ò tiẹ̀ ronú nípa ọjọ́ ọ̀la mọ́, wọ́n á ní ‘jẹ́ kí n jayé orí mi, mi ò mẹ̀yìn ọ̀la.’ Irú ìgbésí ayé báyìí kì í jẹ́ káyé ẹni nítumọ̀. Àmọ́ tá a bá gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ pé a máa gbé ayé títí láé, èyí á mú ká ṣe àwọn ìpinnu tó máa ṣe àwa àti ìdílé wa láǹfààní nísìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.
Ṣé ọ̀run ni gbogbo wa ń lọ?
“Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, Ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”—Sáàmù 115:16.
OHUN TÁWỌN ÈÈYÀN SỌ
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sọ́run.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ọlọ́run ń gbé ní ọ̀run, ilẹ̀ ayé ló dá fún àwa èèyàn. Bíbélì wá sọ̀rọ̀ nípa “ilẹ̀ ayé gbígbé tí ń bọ̀.” (Hébérù 2:5) Jésù lẹ́ni àkọ́kọ́ tó lọ sọ́run, Bíbélì wá sọ pé ìwọ̀nba àwọn èèyàn kéréje míì máa lọ sí ọ̀run fún iṣẹ́ pàtàkì kan. Àwọn wọ̀nyí máa dara pọ̀ mọ́ Jésù láti ‘ṣàkóso bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.’—Ìṣípayá 5:9, 10; Lúùkù 12:32; Jòhánù 3:13.
KÍ NÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ?
Ìgbàgbọ́ pé gbogbo èèyàn rere ló ń lọ sọ́run kò bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu rárá. Torí pé tí Ọlọ́run bá kó gbogbo èèyàn rere lọ sọ́run, á jẹ́ pé èrò tó ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé kò ní ṣẹ nìyẹn àti pé ìlérí tó ṣe nípa ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé máa já sófo. Ìmọ̀ràn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ni pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, Òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 37:34.