Ogbon To N Daabo Boni
“Ìràpadà ọkàn ènìyàn ni ọrọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ kò gbọ́ ìbáwí mímúná.” —ÒWE 13:8.
BÓ TÍLẸ̀ jẹ́ pé àǹfààní wà nínú kéèyàn lówó lọ́wọ́, síbẹ̀ níní ọ̀rọ̀ lè mú kéèyàn ní àwọn ìṣòro kan, pàápàá lásìkò líle koko tá a wà yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn olè àtàwọn ajínigbé máa ń dọdẹ àwọn olówó àti àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tó jọ pé wọ́n rí tówó ṣe.
Ìròyìn kan láti orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà sọ pé: “Ìdigunjalè, jìbìtì àti ìjínigbé ti mú kí àwọn olówó àti tálákà di ọ̀tá. Àwọn ilé oúnjẹ máa ń ní àwọn ẹ̀ṣọ́ tó dìhámọ́ra, àwọn olówó máa ń ṣe wáyà ẹlẹ́nu ṣóńṣó sórí odi ilé wọn, wọ́n máa ń tan iná tó mọ́lẹ̀ yòò, wọ́n sì máa ń ní kámẹ́rà àti àwọn ẹ̀ṣọ́.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí láwọn ilẹ̀ míì náà nìyẹn.
Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ kò gbọ́ ìbáwí mímúná,” ìyẹn ni pé kò sẹ́ni tó máa ń yọ àwọn tálákà lẹ́nu. Báwo ni ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yìí ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní? Tó bá jẹ́ àdúgbò tí ìwà ipá ti wọ́pọ̀ lò ń gbé tàbí tó o fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí irú àdúgbò bẹ́ẹ̀, má ṣe nǹkan tó máa mú káwọn èèyàn rò pé olówó ni ẹ́. Ronú nípa àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ tó o lò àtàwọn ohun tó o gbé lọ́wọ́ láàárín èrò, nípàtàkì àwọn nǹkan tó lè gba àfiyèsí àwọn èèyàn. Ìwé Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”
Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì jẹ́ ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dàá wa bìkítà nípa wa, kò sì fẹ́ ká kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn. Ìdí nìyẹn tí Oníwàásù 7:12 fi sọ pé irú “ọgbọ́n [bẹ́ẹ̀] jẹ́ fún ìdáàbòbò, torí pé ó “máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.”