ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Pinnu Pé Mi Ò Ní Juwọ́ Sílẹ̀
ẸNI ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89] ni mí, torí náà ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì sábà máa ń pè mi ní “Dádì,” tàbí “Bàbá.” Àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́nlé yẹn máa ń múnú mi dùn. Mo gbà pé èyí jẹ́ ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń san mí lẹ́san fún ọdún méjìléláàádọ́rin [72] tí mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àwọn ìrírí tó lárinrin ni mo ti ní lẹ́nu iṣẹ́ yìí, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n lè fi ìdánilójú sọ fáwọn ọ̀dọ́ pé Jèhófà máa san wọ́n lẹ́san tí wọn ò bá juwọ́ sílẹ̀.—2 Kíró. 15:7.
ÀWỌN ÒBÍ MI, ÀWỌN Ẹ̀GBỌ́N MI ÀTÀWỌN ÀBÚRÒ MI
Orílẹ̀-èdè Ukraine làwọn òbí mi ń gbé kí wọ́n tó kó lọ sílùú Rossburn tó wà ní ìpínlẹ̀ Manitoba lórílẹ̀-èdè Kánádà. Èmi ni ọmọ kẹrìnlá [14] nínú ọmọ mẹ́rìndínlógún [16] tí màmá mi bí, ọkùnrin mẹ́jọ àti obìnrin mẹ́jọ ni wá. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, màmá mi ò bí ìbejì. Bàbá mi nífẹ̀ẹ́ Bíbélì, wọ́n sì máa ń kà á sí wa létí ní gbogbo àárọ̀ Sunday. Wọ́n gbà pé jẹun-jẹun làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń fàwọn èèyàn ṣe, kódà wọ́n tiẹ̀ máa ń dápàárá pé, “Ṣé wọ́n sanwó fún Jésù fún iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe?”
Nígbà tó yá, mẹ́fà nínú àwọn ẹ̀gbọ́n mi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn àbúrò mi méjèèjì náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Aṣáájú-ọ̀nà ni Rose tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n mi. Títí tó fi sùn nínú oorun ikú ló máa ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa ka Bíbélì, wọ́n á sọ pé, “Mo fẹ́ rí i yín nínú ayé tuntun.” Nígbà kan, Ted ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin máa ń fìtara wàásù nípa ọ̀run àpáàdì, débi pé gbogbo àárọ̀ Sunday ló máa ń wàásù lórí rédíò. Á máa lọgun tantan pé títí láé láwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ á máa jóná nínú iná àjóòkú. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, òun náà di Ẹlẹ́rìí tó ń fìtara wàásù.
BÍ MO ṢE BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN
Mo rántí pé ní June 1944, mo dé láti ilé ìwé lọ́jọ́ kan, mo sì rí ìwé kan lórí tábìlì tá a ti ń jẹun, àkòrí ẹ̀ ni The Coming World Regeneration. * Ni mo bá ka ojú ìwé àkọ́kọ́ àti ojú ìwé kejì, mo gbádùn ẹ̀ débi pé mi ò lè gbé e sílẹ̀. Nígbà tí mo ka ìwé yẹn tán, mo pinnu pé màá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, màá sì fayé mi sin Jèhófà.
Mo wá béèrè pé, báwo ni ìwé yẹn ṣe dé orí tábìlì wa? Ẹ̀gbọ́n mi Steve wá sọ fún mi pé àwọn ọkùnrin méjì tó ń “ta” ìwé ló wá sílé wa. Ó sọ pé: “Mo rà á torí pé kò wọ́n.” Nígbà tó di Sunday tó tẹ̀ lé e, àwọn ọkùnrin náà tún wá sílé wa. Wọ́n sọ
fún wa pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn àti pé àwọn máa ń fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn bá ní. Ohun tí wọ́n sọ yìí dùn mọ́ wa torí pé àtikékeré làwọn òbí wa ti gbin Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn. Àwọn ọkùnrin méjèèjì tún sọ fún wa pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa tó ṣe àpéjọ àgbègbè kan nílùú Winnipeg, mo sì rántí pé ibẹ̀ ni Elsie ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ń gbé. Torí náà, mo pinnu láti lọ.Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogún [320] kìlómítà ni ọ̀dọ̀ wa sílùú Winnipeg, kẹ̀kẹ́ ni mo sì gùn láti ilé débẹ̀. Àmọ́ mo yà nílùú Kelwood torí pé ibẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tó wá sílé wa ń gbé. Mo sì bá wọn lọ sípàdé nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ wọn, ibẹ̀ ni mo ti mọ ohun tí wọ́n ń pè ní ìjọ. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ pé gbogbo wa ló yẹ ká máa wàásù láti ilé-dé-ilé bíi ti Jésù yálà a jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ọmọdé tàbí àgbà.
Nígbà tí mo dé Winnipeg, mo pàdé Jack ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, àríwá Ontario ló ti wá fún àpéjọ náà. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ yẹn, arákùnrin kan kéde pé àwọn èèyàn lè ṣèrìbọmi. Èmi àti Jack wá ṣèrìbọmi ní àpéjọ yẹn, àwa méjèèjì sì pinnu láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kété lẹ́yìn tá a bá ṣèrìbọmi. Ẹ̀yìn àpéjọ náà ni Jack bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àmọ́ mi ò lè bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ torí pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni mí, mo sì máa pa dà sílé ìwé. Àmọ́ èmi náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́dún tó tẹ̀ lé e.
ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ MO KỌ́
Èmi àti Stan Nicolson bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Souris, ìpínlẹ̀ Manitoba. Kò pẹ́ tí mo fi rí i pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, gbogbo owó wa tán pátá, síbẹ̀ à ń báṣẹ́ náà lọ. Mo rántí ọjọ́ kan tá à ń bọ̀ láti òde ẹ̀rí, ebi ń pa wá gan-an, a ò sí lówó kankan lọ́wọ́. Bá a ṣe délé, ó yà wá lẹ́nu nígbà tá a bá àpò oúnjẹ ńlá kan lẹ́nu ọ̀nà wa! Títí dòní olónìí, a ò mọ ẹni tó gbé e síbẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ṣe la jẹun bí ọba. Ẹ ò rí i bí Jèhófà ṣe san wá lẹ́san torí pé a ò dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Kódà, mó sanra ju ti tẹ́lẹ̀ lọ lóṣù yẹn.
Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ètò Ọlọ́run ní ká lọ sìn ní ìlú Gilbert Plains, tó wà ní nǹkan bí àádọ́jọ [150] máìlì sí àríwá Souris. Láyé ìgbà yẹn, ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń ní àtẹ ńlá kan lórí pèpéle tí wọ́n máa ń kọ ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù oṣooṣù sí. Ṣùgbọ́n lóṣù kan, ìròyìn yẹn lọ sílẹ̀ ni mo bá sọ àsọyé kan. Mo tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ káwọn ará túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i. Nígbà tí ìpàdé parí, arábìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí wá bá mi, pẹ̀lú omijé ló sọ fún mi pé: “Mo kúkú gbìyànjú, mi ò kàn lè ṣe ju bẹ́ẹ̀ lọ ni.” Lomi bá bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ lójú mi, mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó má bínú.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí n rí i pé àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ tí wọ́n ní ìtara lè ṣàṣìṣe kó sì dùn wọ́n. Ó tiẹ̀ lè máa ṣe wọ́n bíi pé wọn ò tóótun. Ṣùgbọ́n, àwọn ìrírí tí mo ti ní ti jẹ́ kí n rí i pé kò yẹ ká jẹ́ káwọn àṣìṣe wa mú ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀, ká sì sapá kí irú ẹ̀ má bàá wáyé mọ́. Tá ò bá dẹwọ́, ó dájú pé Jèhófà máa san wá lẹ́san.
ÀTAKÒ TÍ WỌ́N ṢE SÍ WA NÍLÙÚ QUEBEC
Mo láǹfààní láti lọ sí kíláàsì kẹrìnlá [14] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ yege ní February 1950. Nǹkan bí àwa mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], ìyẹn ìdá mẹ́rin àwa tá a jáde ní ilé ẹ̀kọ́ yẹn ni wọ́n rán lọ sí ìlú Quebec lórílẹ̀-èdè Kánádà. Èdè Faransé ni wọ́n ń sọ níbẹ̀, àwọn èèyàn ibẹ̀ sì ń ṣe inúnibíni sáwa Ẹlẹ́rìí. Ìlú Val-d’Or tí wọ́n ti ń wa kùsà ni wọ́n rán mi lọ. Lọ́jọ́ kan tá a lọ wàásù ní abúlé Val-Senneville, àlùfáà àgbègbè náà halẹ̀ mọ́ wa pé òun máa fojú wa rí màbo tá ò bá kúrò nílùú náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ni mo bá gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́, ilé ẹjọ́ dá a lẹ́bi, wọ́n sì ní kó san owó ìtanràn. *
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí àtàwọn míì tó wáyé lẹ́yìn náà wà lára àwọn àtakò tí wọ́n ṣe sí wa nílùú Quebec. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti ń darí ìlú Quebec, torí náà àwọn àlùfáà àtàwọn olóṣèlú gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n sì fojú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí màbo. Àkókò yẹn nira gan-an fún wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí ò pọ̀, síbẹ̀ a ò juwọ́ sílẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Mo tiẹ̀ láǹfààní láti kọ́ àwọn kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì,
wọ́n sì wá sínú òtítọ́. Ó ní ìdílé kan tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, àwọn mẹ́wàá ló wà nínú ìdílé náà, gbogbo wọn ló sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgboyà tí wọ́n ní ló mú kí wọ́n kúrò nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, àwọn míì náà sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Láìka àtakò sí, à ń bá ìṣẹ́ ìwàásù lọ, a sì ṣẹ́gun nígbà tó yá!À Ń FI ÈDÈ ÌBÍLẸ̀ DÁ ÀWỌN ARÁ LẸ́KỌ̀Ọ́
Nígbà tó di 1956, ètò Ọlọ́run tún ní kí n lọ sìn ní Haiti. Kò rọrùn fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì tí wọ́n rán lọ síbẹ̀ láti kọ́ èdè Faransé, síbẹ̀ àwọn èèyàn máa ń tẹ́tí sílẹ̀. Arákùnrin Stanley Boggus tó jẹ́ míṣọ́nnárì sọ pé: “Ó yà wá lẹ́nu pé àwọn èèyàn ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ èdè náà sọ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo gbọ́ èdè Faransé torí pé mo ti sìn nílùú Quebec. Àmọ́ kò pẹ́ tá a fi rí i pé èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti ni ọ̀pọ̀ àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ń sọ. Èyí wá mú kó pọn dandan fún wa láti kọ́ èdè náà ká lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù dáadáa. A kọ́ èdè náà, Jèhófà sì bù kún wa.
Káwọn ará lè túbọ̀ lókun nípa tẹ̀mí, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká tú Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde míì sí èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti. Bó ṣe di pé àwọn tó ń wá sípàdé pọ̀ sí i nìyẹn. Àwọn akéde mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] ló wà ní Haiti lọ́dún 1950, àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 1960, wọ́n ti lè ní ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800]! Lásìkò tá à ń wí yìí, Bẹ́tẹ́lì ni mo ti ń sìn. Ní 1961, mo láyọ̀ láti wà lára àwọn tó dárí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, a sì dá àwọn alàgbà àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó jẹ́ ogójì [40] lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó sì máa di àpéjọ àgbègbè tá a ṣe ní January 1962, a rọ àwọn ará pé kí wọ́n fi kún iṣẹ́ ìsìn wọn, kò sì pẹ́ táwọn kan fi di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ohun tá a ṣe yìí bọ́ sákòókò torí pé kò pẹ́ tí inúnibíni fi bẹ̀rẹ̀.
Ní January 23, 1962, ìyẹn lẹ́yìn tá a dé láti àpéjọ agbègbè, àwọn ọlọ́pàá wá mú èmi àti míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Andrew D’Amico. Inú ẹ̀ka ọ́fíìsì gan-an ni wọ́n ti wá mú wa, wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé Jí! January 8, 1962 (lédè Faransé). Ìwé ìròyìn Jí! yẹn fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé kan tó sọ pé àwọn tó ń gbé ní Haiti máa ń lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò. Àwọn kan kórìíra ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì sọ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa la ti kọ àpilẹ̀kọ náà. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan * Àmọ́, ṣe làwọn arákùnrin tá a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu. Lónìí, tí mo bá rántí bí wọ́n ṣe fara dà á àti bí ìgbàgbọ́ wọn ò ṣe yingin, ńṣe ní inú mi máa ń dùn. Ní báyìí, wọ́n ti ní Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Creole ti ilẹ̀ Haiti, a ò lérò pé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀.
lẹ́yìn náà, wọ́n lé àwọn míṣọ́nnárì kúrò lórílẹ̀-èdè yẹn.IṢẸ́ ÌKỌ́LÉ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ CENTRAL AFRICAN REPUBLIC
Lẹ́yìn ìyẹn, ètò Ọlọ́run ni kí n lọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Central African Republic. Ìgbà tó yá, wọ́n sọ mi di alábòójútó arìnrìn-àjò, kò sì pẹ́ ti mo tún di alábòójútó ẹ̀ka.
Àwọn ilé tí ò fi bẹ́ẹ̀ jojú ní gbèsè la fi ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà yẹn. Èmi náà kọ́ béèyàn ṣe ń já koríko, táá sì fi ṣe àtíbàbà. Ẹnu máa ń ya àwọn tó ń kọjá tí wọ́n bá ń rí i tí mò ń já koríko, tí mo sì ń dì í ká lè fi ṣe àtíbàbà. Èyí sì mú káwọn ará túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ kíkọ́ àti bíbójútó àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Àwọn olórí ìsìn kan máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé páànù ni wọ́n fi bo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọn, àmọ́ koríko làwa lò. Síbẹ̀, a ò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, a ṣì ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń fi koríko bò. Lọ́jọ́ kan, ìjì ńlá kan jà ní ìlú Bangui tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Gbogbo páànù tí wọ́n fi bo ṣọ́ọ̀ṣì kan ni ìjì náà ṣí dànù, àmọ́ kò sóhun tó ṣe koríko tá a fi bo Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, bí ẹnu gbogbo àwọn tó ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ ṣe wọhò nìyẹn. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun àti ilé àwọn míṣọ́nnárì láàárín oṣù márùn-ún péré ká lè túbọ̀ bojú tó iṣẹ́ ìwàásù náà dáadáa. *
ÈMI ÀTI ÌYÀWÓ MI LẸ́NU IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ
Nígbà tó di ọdún 1976, ìjọba orílẹ̀-èdè Central African Republic fòfin de iṣẹ́ wa, ètò Ọlọ́run wá rán mi lọ sílùú N’Djamena tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Chad. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé arábìnrin kan tó ń jẹ́ Happy, orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ló ti wá, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó nítara sì ni. A ṣègbéyàwó ní April 1, 1978. Oṣù yẹn gan-an ni ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà, a sì sá lọ sí apá gúúsù orílẹ̀-èdè náà. Nígbà tógun náà parí, a pa dà sílé wa, a wá rí i pé ilé wa gan-an láwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara kan fi ṣe ibùdó wọn. Gbogbo àwọn ìtẹ̀jáde tá a kó sílé ni wọ́n kó lọ, kódà aṣọ ìgbéyàwó Happy títí kan gbogbo ẹ̀bùn tí wọ́n fún wa lọ́jọ́ ìgbéyàwó ni wọ́n kó lọ. Àmọ́, a ò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, àwa méjèèjì ṣera wa lọ́kan, a sì ń báṣẹ́ lọ.
Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì, ìjọba orílẹ̀-èdè Central African Republic mú ìfòfindè náà kúrò. A pa dà síbẹ̀, ètò Ọlọ́run sì ní ká máa báṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò wa lọ. Ọkọ̀ kan la fi ṣe ilé, gbogbo ohun tá a sì ní ò ju bẹ́ẹ̀dì kan tó ṣeé ká, dúrọ́ọ̀mù ńlá kan tó lè gba omi igba [200] Lítà, fìríìjì kan àti gáàsì tá a fi ń dáná. Kò rọrùn rárá láti rìnrìn-àjò nígbà yẹn. Mo rántí pé nígbà kan tá a rìnrìn-àjò, ó lé nígbà mẹ́tàdínlọ́gọ́fà [117] táwọn ọlọ́pàá dá wa dúró lójú ọ̀nà.
Ooru ibẹ̀ ò dẹrùn rárá kódà ó máa ń gbóná tó àádọ́ta [50] lórí òṣùwọ̀n Celsius. Nígbà míì tá a bá ń ṣe àpéjọ, a kì í sábà rí omi tí ó tó fún ìrìbọmi. Torí náà, àwọn arákùnrin máa lọ gbẹ́ ìsàlẹ̀ odò tó ti gbẹ kí wọ́n lè rí omi díẹ̀ tí wọ́n á lò fún ìrìbọmi, lọ́pọ̀ ìgbà inú dúrọ́ọ̀mù kan ni wọ́n ti máa ń ṣe é.
MO ṢIṢẸ́ LÁWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ MÍÌ NÍLẸ̀ ÁFÍRÍKÀ
Lọ́dún 1980, wọ́n rán wa lọ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. A ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń múra sílẹ̀ fún kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun, ọdún méjì àtààbọ̀ la sì lò níbẹ̀. Àwọn ará ti ra ilé ìkẹ́rùsí alájà méjì kan tí wọ́n á tú palẹ̀, wọ́n á sì lọ tún un tò sórí ilẹ̀ tá a fẹ́ kọ́lé sí. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, mo gun òkè ilé ìkẹ́rùsí náà kí n lè bá wọn tú u palẹ̀. Àmọ́ bí mo ṣè ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ lọ́wọ́ ọ̀sán, ẹsẹ̀ mi yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, àfi wìì! Mo jábọ̀ látòkè, mo sì bára mi nílẹ̀. Ó kọ́kọ́ dà bíi pé mo ṣèṣe gan-an, àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àyẹ̀wò, dókítà sọ fún ìyàwó mi pé: “Má bẹ̀rù, àwọn iṣan kan ló ya, láàárín ọ̀sẹ̀ kan sí méjì, ará ẹ̀ máa yá.”
Lọ́dún 1986, ètò Ọlọ́run tún ní ká lọ ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò lórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire. Iṣẹ́
yìí máa ń gbé wa lọ sórílẹ̀-èdè Burkina Faso. Mi ò tiẹ̀ lè ronú ẹ̀ láé pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tá a máa ṣì máa gbé fúngbà díẹ̀ ní Burkina Faso.Ọdún 1956 ni mo kúrò ní Kánádà, àmọ́ lọ́dún 2003, ìyẹn lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta [47], ètò Ọlọ́run ní kémi àtìyàwó mi lọ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lórí ìwé, ọmọ Kánádà ni wá, síbẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà ò kúrò lọ́kàn wa.
Nígbà tó di ọdún 2007, ètò Ọlọ́run tún ní ká pa dà sórílẹ̀-èdè Burkina Faso nílẹ̀ Áfíríkà. Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] ni mí nígbà yẹn, mo sì wà lára Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè náà. Nígbà tó yá, wọ́n sọ ẹ̀ka náà di ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè lábẹ́ ìdarí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Benin. Nígbà tó sì di August 2013, wọ́n ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Benin.
Láìka àìlera mi sí, mo ṣì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù gan-an. Ìyàwó mi àtàwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ gbárùkù tì mí kí n má bàa dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ wọn, láàárín ọdún mẹ́ta tó kọjá, méjì nínú àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìyẹn Gédéon àti Frégis ti ṣèrìbọmi. Ní báyìí, àwọn méjèèjì ń fìtara sin Jèhófà.
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní South Africa ni ètò Ọlọ́run ní kémi àtìyàwó mi ti máa ṣiṣẹ́. Àwọn tó wà níbẹ̀ sì ń fìfẹ́ tọ́jú mi nítorí àìlera mi. Á yà yín lẹ́nu pé South Africa ni orílẹ̀-èdè keje tí mo ti sìn nílẹ̀ Áfíríkà. Nígbà tó sì di October 2017, Jèhófà bù kún wá lọ́nà tá ò lérò. Ètò Ọlọ́run pè wá fún ìyàsímímọ́ oríléeṣẹ́ wa ní Warwick ìpínlẹ̀ New York. Mánigbàgbé ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn jẹ́ nígbèésí ayé mi!
Ìwé Ọdọọdún 1994 sọ lójú ìwé 255 pé: “Fún gbogbo àwọn tó ti ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ yìí fún ọ̀pọ̀ ọdún, a gbà yín níyànjú pé: ‘Ẹ jẹ́ onígboyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọwọ́ yín rọ jọwọrọ, nítorí pé ẹ̀san wà fún ìgbòkègbodò yín.’—2 Kíró. 15:7.” Èmi àtìyàwó mi ti pinnu pé àá máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, àá sì máa gba àwọn míì níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 9 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ ní 1944, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.
^ ìpínrọ̀ 18 Wo àpilẹ̀kọ náà “Quebec Priest Convicted for Attack on Jehovah’s Witnesses” nínú Jí! November 8, 1953 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 3 sí 5.
^ ìpínrọ̀ 23 Tó o bá fẹ́ ka àlàyé sí i nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 1994 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 148 sí 150.
^ ìpínrọ̀ 26 Wo àpilẹ̀kọ náà, “Building on a Solid Foundation” nínú Jí!, May 8, 1966 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 27.