Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lo Ìgbàgbọ́—Kó O Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání!

Lo Ìgbàgbọ́—Kó O Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání!

“Máa bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá.”JÁK. 1:6.

ORIN: 81, 70

1. Kí ló mú kí Kéènì ṣèpinnu tí kò tọ́, kí ló sì yọrí sí?

OHUN kan ṣẹlẹ̀ tó gba pé kí Kéènì ṣèpinnu. Ó lè pinnu pé òun ò ní jẹ́ kí inú tó ń bí òun mú kóun ṣìwà hù, ó sì lè gbà kó mú òun ṣìwà hù. Kò sí ìpinnu tó ṣe tí kò ní lẹ́yìn, àbájáde ọ̀rọ̀ náà sì máa nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Ó dájú pé o mọ ohun tí Kéènì ṣe, kò ṣèpinnu tó tọ́. Ohun tó sì mú kó ṣekú pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ olódodo nìyẹn. Ìpinnu tó ṣe yẹn mú kí àárín òun àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bà jẹ́.Jẹ́n. 4:3-16.

2. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

2 Àwa náà láwọn ìpinnu tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Kì í ṣe gbogbo ìpinnu tá a fẹ́ ṣe ló máa jẹ́ ọ̀rọ̀ ikú tàbí ìyè. Àmọ́, púpọ̀ lára àwọn ìpinnu tá à ń ṣe máa nípa tó lágbára lórí ìgbésí ayé wa. Torí náà, tá a bá mọ bá a ṣe lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Àmọ́ tá a bá ṣe ìpinnu tí kò dáa, ó lè yọrí sí ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́.Òwe 14:8.

3. (a) Kí lá jẹ́ ká máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?

3 Kí lá jẹ́ ká máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání? Ó ṣe pàtàkì pé ká nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ká sì ní ìdánilójú pé Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ àti pé á fún wa lọ́gbọ́n láti ṣèpinnu tó tọ́. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká gba Ọ̀rọ̀ Jèhófà gbọ́, ká sì fọkàn tán àwọn ìtọ́ni rẹ̀. (Ka Jákọ́bù 1:5-8.) Bá a ṣe ń sún mọ́ Jèhófà, tá a sì nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àá túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé e. Nípa bẹ́ẹ̀, á mọ́ wa lára láti máa yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò ká tó ṣèpinnu. Àmọ́, kí la lè ṣe táá mú ká túbọ̀ máa ṣèpinnu tó tọ́? Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé tá a bá ti ṣèpinnu kò sóhun tó lè yí ìpinnu náà pa dà?

Ó DI DANDAN KÁ ṢÈPINNU

4. Ìpinnu wo ni Ádámù ní láti ṣe, kí ló sì yọrí sí?

4 Látìgbà tí Ọlọ́run ti dá èèyàn sáyé ló ti di dandan pé kí wọ́n máa ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Ádámù ní láti ṣèpinnu bóyá kóun tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí kóun tẹ́tí sí Éfà ìyàwó òun. Ó mọ̀ pé òun ní láti ṣèpinnu, àmọ́ ìpinnu tó ṣe lọ́jọ́ yẹn kò bọ́gbọ́n mu. Ìyàwó rẹ̀ mú kó ṣèpinnu tí kò tọ́, torí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run lé e kúrò nínú Párádísè, ó sì tún pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Kékeré nìyẹn lára ibi tọ́rọ̀ náà yọrí sí. Àbájáde ìpinnu tí Ádámù ṣe yẹn la ṣì ń jìyà rẹ̀ títí dòní.

5. Ǹjẹ́ o rò pé ó dáa bí Ọlọ́run ṣe dá wa pé ká lè ṣèpinnu?

5 Àwọn kan lè ronú pé ayé á dùn gbé ju báyìí lọ tí kò bá pọn dandan pé kéèyàn máa ṣèpinnu. Ṣé ohun tíwọ náà rò nìyẹn? Ohun kan ni pé Jèhófà tó dá wa kò ṣe wá ní ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì tí kì í ronú, tí kò sì lè ṣèpinnu. Àmọ́, ṣe ló fún wa ní Bíbélì táá ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Jèhofà dá wa ká lè ṣèpinnu torí ó mọ̀ pé ó máa ṣe wá láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.

6, 7. Ìpinnu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ní láti ṣe, kí sì nìdí tó fi ṣòro fún wọn láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

6 Àpẹẹrẹ kan ni tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí, ó di dandan kí wọ́n pinnu ẹni tí wọ́n máa jọ́sìn: Ṣé Jèhófà ni wọ́n máa sìn ni àbí àwọn ọlọ́run èké? (Ka Jóṣúà 24:15.) A lè ronú pé ìpinnu yẹn kò nira rárá. Síbẹ̀ ó ṣe kedere pé ohun tí wọ́n bá pinnu ló máa sọ bóyá wọ́n á wà láàyè tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó yani lẹ́nu pé léraléra làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣèpinnu tí kò tọ́ lásìkò àwọn Onídàájọ́. Wọ́n ń fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì ń bọ̀rìṣà. (Oníd. 2:3, 11-23) Ìgbà kan tiẹ̀ wà lẹ́yìn náà tó di dandan pé kí wọ́n pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Wòlíì Èlíjà ní káwọn èèyàn náà pinnu bóyá Jèhófà ni wọ́n máa jọ́sìn tàbí Báálì. (1 Ọba 18:21) Èlíjà bá àwọn èèyàn náà wí torí pé wọn ò mọ èyí tí wọ́n á ṣe. O lè ronú pé ìpinnu yẹn kò ṣòro ṣe rárá, torí pé ohun tó bọ́gbọ́n mu tó sì máa ṣeni láǹfààní ni pé kéèyàn jọ́sìn Jèhófà. Ó sì dájú pé kò sẹ́ni tó láròjinlẹ̀ tó máa sọ pé Báálì lòun á sìn. Síbẹ̀, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń “tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra.” Abájọ tí wòlíì Èlíjà fi rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n sin Jèhófà, torí pé ìyẹn ni ìjọsìn tòótọ́.

7 Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu? Àkọ́kọ́ ni pé wọn ò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà mọ́, wọn ò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọn kì í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wọn ò fi ọgbọ́n rẹ̀ ṣèwà hù, wọn ò sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Ká ní wọ́n ń fọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù ni, wọ́n á máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (Sm. 25:12) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gbà káwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká kó èèràn ràn wọ́n, wọ́n sì tún gbà kí wọ́n máa ṣèpinnu fún wọn. Àwọn èèyàn ilẹ̀ yẹn kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà, torí náà wọ́n mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa bọ̀rìṣà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti kìlọ̀ fún wọn pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn tí wọn ò bá ṣọ́ra.Ẹ́kís. 23:2.

ṢÓ YẸ KÁWỌN MÍÌ MÁA ṢÈPINNU FÚN WA?

8. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

8 Àwọn àpẹẹrẹ tá a sọ tán yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló wà láti ṣèpinnu, tá a bá sì máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ó ṣe pàtàkì ká lóye Ìwé Mímọ́ dáadáa. Gálátíà 6:5 sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ kí ẹlòmíì ṣèpinnu fún wa, ojúṣe wa ni. Dípò táwọn míì á fi máa ṣèpinnu fún wa, ó yẹ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì ṣe é.

9. Kí nìdí tí kò fi dáa pé ká jẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún wa?

9 Kí ló lè mú kẹ́nì kan jẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún òun? Ó lè jẹ́ torí àtiṣe ohun táwọn míì ń ṣe, ìyẹn sì máa ń mú kéèyàn ṣèpinnu tí kò tọ́. (Òwe 1:10, 15) Síbẹ̀, ohun yòówù káwọn èèyàn rọ̀ wá pé ká ṣe, àwa la máa pinnu bóyá ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́ la máa tẹ̀ lé àbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá jẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún wa, ó túmọ̀ sí pé ohun tí wọ́n fẹ́ la yàn láti ṣe. Yálà a mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí a ò mọ̀, ìpinnu kan la ṣe yẹn, àmọ́ ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í sábà dáa.

10. Ìkìlọ̀ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fáwọn ará tó wà ní Gálátíà?

10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn ará tó wà ní Gálátíà pé ó léwu tí wọ́n bá ń jẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún wọn. (Ka Gálátíà 4:17.) Àwọn kan wà nínú ìjọ yẹn tí wọ́n fẹ́ máa ṣèpinnu fáwọn míì kí wọ́n lè kẹ̀yìn wọn sáwọn àpọ́sítélì. Kí ló mú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n fẹ́ fa àwọn ará sẹ́yìn ara wọn. Ìkọjá àyè gbáà nìyẹn, bákan náà wọn ò jẹ́ káwọn ará lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣèpinnu fúnra wọn.

11. Báwo la ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu?

11 Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti pé ó jẹ́ kí àwọn ará lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣèpinnu fúnra wọn. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:24.) Àpẹẹrẹ yìí làwọn alàgbà ń tẹ̀ lé lónìí tí wọ́n bá ń gba àwọn ará níyànjú lórí ọ̀rọ̀ ara ẹni. Wọ́n máa ń jẹ́ káwọn ará mọ ohun tí Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde sọ. Síbẹ̀, àwọn alàgbà máa ń kíyè sára kó má lọ di pé àwọn ló ń sọ ìpinnu táwọn ará máa ṣe fún wọn. Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu torí pé ẹni tó ṣèpinnu ló ni àbájáde ìpinnu tó bá ṣe. Èyí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ẹ̀kọ́ náà sì ni pé a lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó fẹ́ ṣèpinnu nípa jíjẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀rọ̀ náà. Síbẹ̀, ká rántí pé ẹ̀tọ́ wọn ni, ojúṣe wọn sì ni láti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Tí wọ́n bá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, á ṣe wọ́n láǹfààní. Ó ṣe kedere nígbà náà pé a ò gbọ́dọ̀ ronú pé a láṣẹ láti ṣèpinnu fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè fúnra wọn ṣèpinnu (Wo ìpínrọ̀ 11)

MÁ ṢE ÌPINNU TORÍ BÍ NǸKAN ṢE RÍ LÁRA RẸ

12, 13. Kí nìdí tó fi léwu tá a bá ṣèpinnu nígbà tá a ṣì ń bínú tàbí nígbà tá a rẹ̀wẹ̀sì?

12 Ọ̀rọ̀ kan wà táwọn èèyàn kan máa ń sọ, wọ́n á ní: Ohun tọ́kàn rẹ bá ti ní kó o ṣe ni kó o ṣe. Àmọ́ ó léwu gan-an tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra ká má ṣe jẹ́ kí ọkàn wa tàbí bí nǹkan ṣe rí lára wa pinnu ohun tá a máa ṣe. (Òwe 28:26) Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í dáa téèyàn bá ṣe ohun tí ọkàn rẹ̀ sọ. Ìṣòro ibẹ̀ ni pé aláìpé ni wá, ọkàn wa sì máa ń “ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jer. 3:17; 13:10; 17:9; 1 Ọba 11:9) Torí náà, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ohun tọ́kàn wa bá ti ní ká ṣe là ń ṣe?

13 Àwa Kristẹni mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká fọkàn ṣe nǹkan. Ó ṣe tán, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa ká sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa bí ara wa. (Mát. 22:37-39) Àmọ́, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú ìpínrọ̀ kejìlá jẹ́ ká rí i pé ó léwu gan-an téèyàn bá jẹ́ kí bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ pinnu ohun tó máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ṣèpinnu nígbà tá a ṣì ń bínú? Ó ṣeé ṣe ká mọ ìdáhùn tírú ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí wa rí. (Òwe 14:17; 29:22) Àbí kẹ̀, ṣó rọrùn kéèyàn ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání lásìkò tó rẹ̀wẹ̀sì? (Núm. 32:6-12; Òwe 24:10) Ká máa rántí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ téèyàn bá jẹ́ “ẹrú fún òfin Ọlọ́run.” (Róòmù 7:25) Ó ṣe kedere pé a lè ṣàṣìṣe, tá a bá jẹ́ kí bí nǹkan ṣe rí lára wa pinnu àwọn ohun pàtàkì tá a máa ṣe.

ÌGBÀ TÓ YẸ KÓ O YÍ ÌPINNU RẸ PA DÀ

14. Kí ló fi hàn pé a lè yí ìpinnu tá a ti ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà?

14 Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé tá a bá ti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ kò sóhun tó lè yí i pa dà. Àwọn ìgbà míì wà tó máa pọn dandan pé ká yiri ìpinnu kan wò, ká sì yí i pa dà. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jónà. Jèhófà yí ìpinnu tó ṣe nípa àwọn ará Nínéfè pa dà. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ sì wá rí àwọn iṣẹ́ wọn, pé wọ́n ti yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn; nítorí náà, Ọlọ́run tòótọ́ pèrò dà lórí ìyọnu àjálù tí ó ti sọ pé òun yóò mú bá wọn; kò sì mú un wá.” (Jónà 3:10) Lẹ́yìn tí Jèhófà rí i pé àwọn èèyàn náà ti ronú pìwà dà, ó pinnu pé òun ò ní pa wọ́n run mọ́. Bí Jèhófà ṣe yí èrò rẹ̀ pa dà yìí fi hàn pé ó gba tàwọn èèyàn náà rò, ó káàánú wọn, ó sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kì í ṣe bí àwa èèyàn, tá a máa ń bínú rangbọndan, tíyẹn á sì mú ká ṣìwà hù.

15. Kí ló lè mú ká yí ìpinnu kan pa dà?

15 Àwọn ìgbà míì wà tó máa bọ́gbọ́n mu pé ká yí ìpinnu kan pa dà. Ó lè jẹ́ torí ipò nǹkan tó yí pa dà. Àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà náà yí ìpinnu rẹ̀ pa dà torí pé ipò nǹkan yí pa dà. (1 Ọba 21:20, 21, 27-29; 2 Ọba 20:1-5) Nígbà míì, a lè yí ìpinnu kan pa dà torí pé a rí àwọn ìsọfúnni tuntun gbà. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan parọ́ mọ́ Mefibóṣẹ́tì ọmọ-ọmọ Sọ́ọ̀lù níwájú Ọba Dáfídì. Àmọ́ lẹ́yìn tí Dáfídì wá mọ ìdí ọ̀rọ̀ náà, ó yí ìpinnu tó ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà. (2 Sám. 16:3, 4; 19:24-29) Torí náà, àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ohun tó máa bọ́gbọ́n mu pé ká ṣe nìyẹn.

16. (a) Àwọn ìlànà wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání? (b) Kí nìdí tó fi lè pọn dandan pé ká yiri ìpinnu tá a ti ṣe wò? Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

16 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká má ṣe máa kánjú ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. (Òwe 21:5) Tá a bá ń fara balẹ̀ tá a sì ń ronú jinlẹ̀ dáadáa ká tó ṣèpinnu, ó ṣeé ṣe ká ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (1 Tẹs. 5:21) Kí olórí ìdílé kan tó ṣèpinnu, ó yẹ kó fara balẹ̀ ṣèwádìí nínú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, kó sì tún tẹ́tí sí èrò àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀. Rántí pé Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó tẹ́tí sí ìyàwó rẹ̀. (Jẹ́n. 21:9-12) Ó tún yẹ káwọn alàgbà máa fara balẹ̀ ṣèwádìí kí wọ́n tó ṣèpinnu. Tí wọ́n bá sì rí àwọn ìsọfúnni tó mú kó pọn dandan pé kí wọ́n yí ìpinnu tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà, kò yẹ kí wọ́n lọ́ tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Torí pé wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, wọn kì í ronú pé àwọn ará ò ní bọ̀wọ̀ fáwọn mọ́ tí àwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí wọ́n ṣe tán láti yí èrò wọn àti ìpinnu wọn pa dà nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ohun tó sì yẹ kí gbogbo wa máa ṣe nìyẹn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àlàáfíà máa wà nínú ìjọ, ohun gbogbo á sì máa lọ létòlétò.Ìṣe 6:1-4.

ṢE OHUN TÓ O TI PINNU

17. Kí láá mú ká máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

17 Àwọn ìpinnu kan ṣe pàtàkì ju àwọn míì lọ. Tó bá di pé ká ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, kò yẹ ká kánjú, ṣe ló yẹ ká ronú dáadáa, ká sì gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni kan ń ronú bóyá káwọn ṣègbéyàwó tàbí káwọn má ṣègbéyàwó, wọ́n sì tún máa ń ronú ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Ohun rere míì táwọn míì máa ń ronú nípa rẹ̀ ni báwọn ṣe máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún àti ìgbà táwọn máa bẹ̀rẹ̀. Ká tó ṣe irú àwọn ìpinnu yìí, ó ṣe pàtàkì ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, kó sì dá wa lójú pé ó máa tọ́ wa sọ́nà. (Òwe 1:5) Torí náà, ó yẹ ká gbé ìmọ̀ràn inú Bíbélì yẹ̀ wò torí pé ìmọ̀ràn rẹ̀ ló dára jù lọ, ká sì máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà. Ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò láti ṣèpinnú tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Torí náà, nígbàkigbà tó o bá fẹ́ ṣèpinnu pàtàkì, máa bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ìpinnu mi yìí fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Ṣé á múnú àwọn ará ilé mi dùn, táá sì jẹ́ ká wà ní àlàáfíà? Ṣé á fi hàn pé mo ní sùúrù, mo sì jẹ́ onínúure?’

18. Kí nìdí tí Jèhófà fi retí pé ká fúnra wa ṣèpinnu?

18 Jèhófà kì í fipá mú wa pé ká nífẹ̀ẹ́ òun tàbí ká jọ́sìn òun. Ọwọ́ wa nìyẹn wà. Torí pé Ọlọ́run fún wa lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá, ó gbà pé a lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu bóyá a máa sin òun tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóṣ. 24:15; Oníw. 5:4) Àmọ́, ó retí pé ká ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìmọ̀ràn òun mu. Torí náà, tá a bá gbà pé àwọn ìtọ́ni Jèhófà ló dára jù, tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, àá máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ọ̀nà wa sì máa yọrí sí rere.Ják. 1:5-8; 4:8.