Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 13

Ẹ Ní Ìfẹ́ Tó Jinlẹ̀ sí Ara Yín

Ẹ Ní Ìfẹ́ Tó Jinlẹ̀ sí Ara Yín

“Ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara yín látọkàn wá.”​—1 PÉT. 1:22.

ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó tẹnu mọ́ ọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an (Wo ìpínrọ̀ 1 àti 2)

1. Kí ni Jésù pa láṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

LÁLẸ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó pa àṣẹ pàtàkì kan fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “Bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín.” Ó wá fi kún un pé: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”​—Jòh. 13:34, 35.

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa?

2 Jésù sọ pé á ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ tí wọ́n bá ń fìfẹ́ hàn síra wọn bóun ṣe fi hàn sí wọn. Bó ti ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní firú ìfẹ́ yìí hàn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kókó pé káwa náà fi hàn lónìí. Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu gan-an pé ká má ṣe fàyè gba ohunkóhun tí kò ní jẹ́ ká fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa!

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Torí pé a jẹ́ aláìpé, ó lè ṣòro fún wa láti fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn síra wa látọkàn wá. Bó ti wù kó rí, a gbọ́dọ̀ sapá láti fara wé Jésù Kristi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí ìfẹ́ ṣe máa mú ká jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ká jẹ́ni tí kì í ṣojúsàájú, ká sì máa ṣe aájò àlejò. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ yìí, bi ara ẹ pé: ‘Kí ni mo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń fìfẹ́ hàn bí kò tiẹ̀ rọrùn?’

JẸ́ ẸLẸ́MÌÍ ÀLÀÁFÍÀ

4. Bó ṣe wà nínú Mátíù 5:23, 24, kí nìdí tó fi yẹ ká wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tó ní ohun kan lòdì sí wa?

4 Jésù jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin tó ní ohun kan lòdì sí wa. (Ka Mátíù 5:23, 24.) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé tá a bá máa rí ojúure Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì. Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín àwa àtàwọn arákùnrin wa. Kò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa tá a bá ń di ẹlòmíì sínú, tá ò sì wá bá a ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà.​—1 Jòh. 4:20.

5. Kí ló mú kó ṣòro fún arákùnrin kan láti wá àlàáfíà?

5 Nígbà míì, ó lè ṣòro fún wa láti wá àlàáfíà. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Mark. * Ó gbọ́ pé arákùnrin kan ṣe àríwísí òun, ó sì ń sọ̀rọ̀ òun láìdáa fáwọn míì nínú ìjọ. Báwo lọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára Mark? Ó sọ pé: “Inú bí mi, mo sì sọ̀rọ̀ burúkú sí i.” Nígbà tó yá, Mark ronú pé ìwà tóun hù kù díẹ̀ káàtó, torí náà ó lọ bẹ arákùnrin náà kọ́rọ̀ náà lè parí. Àmọ́ gbogbo bí Mark ṣe ṣe tó, arákùnrin yẹn ò gbà. Kí ni Mark wá ṣe? Níbẹ̀rẹ̀ ó ronú pé: ‘Kí nìdí tí mo tiẹ̀ fi ń yọ ara mi lẹ́nu nígbà tí kò ṣe tán láti yanjú ọ̀rọ̀ náà?’ Àmọ́, alábòójútó àyíká wọn sọ fún Mark pé kó má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ náà sú òun, kó ṣì máa gbìyànjú. Kí ni Mark tún ṣe?

6. (a) Kí ni Mark tún ṣe kí àlàáfíà lè jọba? (b) Báwo ni Mark ṣe fìmọ̀ràn tó wà nínú Kólósè 3:13, 14 sílò?

6 Nígbà tí Mark ronú jinlẹ̀ lórí bóun ṣe hùwà, ó rí i pé òun ò fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn àti pé ṣe lòun ń dá ara òun láre ṣáá. Ó wá rí i pé ó yẹ kóun ṣàtúnṣe. (Kól. 3:​8, 9, 12) Ó tún pa dà lọ sọ́dọ̀ arákùnrin yẹn, ó sì bẹ̀ ẹ́. Kódà, Mark tún kọ lẹ́tà sí i lọ́pọ̀ ìgbà, ó bẹ̀ ẹ́, ó sì rọ̀ ọ́ pé kó jẹ́ káwọn gbàgbé ọ̀rọ̀ àná kí àárín àwọn lè pa dà gún. Yàtọ̀ síyẹn, Mark fún arákùnrin náà láwọn ẹ̀bùn tó mọ̀ pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ náà, ṣe ni arákùnrin yẹn fàáké kọ́rí. Síbẹ̀, Arákùnrin Mark pinnu pé òun máa pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa, ká sì máa dárí jini. (Ka Kólósè 3:13, 14.) Torí náà, yálà àwọn míì mọyì bá a ṣe ń sapá láti wá àlàáfíà tàbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, àwa Kristẹni tòótọ́ á máa nífẹ̀ẹ́ wọn, àá máa dárí jì wọ́n, a ò sì ní yéé gbàdúrà pé kí Ọlọ́run yí wọn lọ́kàn pa dà.​—Mát. 18:21, 22; Gál. 6:9.

Ó lè gba pé ká ṣe onírúurú nǹkan ká tó lè yanjú èdèkòyédè, kí àlàáfíà sì jọba (Wo ìpínrọ̀ 7 àti 8) *

7. (a) Ìmọ̀ràn wo ni Jésù gbà wá? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan?

7 Jésù gbà wá nímọ̀ràn pé bá a ṣe fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí wa ni káwa náà máa ṣe sí wọn. Ó fi kún un pé kì í ṣe àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa nìkan ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́. (Lúùkù 6:​31-33) Ẹ jẹ́ ká ṣàpẹẹrẹ kókó yìí pẹ̀lú ohun kan tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ bí irú ẹ̀ kò tiẹ̀ wọ́pọ̀. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ ká sọ pé ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìjọ bá ń yẹra fún ẹ, tí kì í sì í kí ẹ? Ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lara nìyẹn. Ó sọ pé: “Arábìnrin kan ń yàn mí lódì, mi ò sì mọ̀dí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ yẹn ká mi lára débi pé inú mi kì í dùn tí mo bá ń lọ sípàdé.” Lákọ̀ọ́kọ́, Lara ronú pé: ‘Òun ló mọ̀, mi ò kúkú ṣẹ̀ ẹ́. Ó ṣe tán, gbogbo ìjọ ló mọ̀ pé ó máa ń yan àwọn èèyàn lódì.’

8. Kí ni Lara ṣe kí àlàáfíà lè jọba láàárín òun àti arábìnrin yẹn, kí nìyẹn sì kọ́ wa?

8 Lara ṣe àwọn nǹkan kan láti mú kí àlàáfíà pa dà jọba. Ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì pinnu pé òun máa lọ bá arábìnrin yẹn káwọn lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn tí wọ́n jọ sọ̀rọ̀, wọ́n dì mọ́ra, wọ́n sì gbà pé ọ̀rọ̀ náà ti tán. Lọ́kàn Lara, ó gbà pé ọ̀rọ̀ ti yanjú. Àmọ́ ẹ gbọ́ ohun tí Lara sọ, ó ní: “Nígbà tó yá, arábìnrin yẹn tún gbéṣe ẹ̀ dé. Ọ̀rọ̀ náà wá sú mi, mi ò mọ ohun tí mo tún lè ṣe.” Lara ronú pé ó dìgbà tí arábìnrin náà bá yíwà pa dà kóun tó lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Àmọ́ nígbà tó yá, Lara rí i pé ohun tó dáa jù ni pé kóun máa fìfẹ́ hàn sí arábìnrin náà, kóun sì ‘dárí jì í.’ (Éfé. 4:32–5:2) Lara rántí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ táwa Kristẹni tòótọ́ ní, pé ìfẹ́ “kì í di èèyàn sínú. Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó máa ń retí ohun gbogbo, ó máa ń fara da ohun gbogbo.” (1 Kọ́r. 13:5, 7) Bó ṣe di pé ọkàn Lara balẹ̀ nìyẹn. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, ọkàn arábìnrin náà rọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ Lara. Ohun kan tó dájú ni pé tó o bá ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tó o sì ń fìfẹ́ hàn sí wọn, “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò . . . wà pẹ̀lú” rẹ. ​—2 Kọ́r. 13:11.

MÁ ṢE MÁA ṢOJÚSÀÁJÚ

9. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 10:34, 35, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣe ojúsàájú?

9 Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú. (Ka Ìṣe 10:34, 35.) Táwa náà kì í bá ṣojúsàájú, ṣe là ń fi hàn pé ọmọ Jèhófà ni wá. À ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ tó ní ká nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa bí ara wa, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa.​—Róòmù 12:9, 10; Jém. 2:8, 9.

10-11. Kí ló ran arábìnrin kan lọ́wọ́ láti yí èrò òdì tó ní pa dà?

10 Kò rọrùn fáwọn kan láti má ṣojúsàájú. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Ruth. Ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Ẹnì kan tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ṣe ohun kan sí ìdílé rẹ̀, ó sì dùn ún gan-an. Kí ni Ruth wá ṣe? Ó sọ pé: “Mi ò kì í fẹ́ gbọ́ nǹkan kan nípa orílẹ̀-èdè yẹn rárá. Mo gbà pé èèyànkéèyàn ni gbogbo ẹni tó bá wá látibẹ̀, títí kan àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin.” Kí ló mú kí Ruth borí èrò òdì yìí?

11 Ruth rí i pé á dáa kóun wá nǹkan ṣe kóun lè borí èrò òdì tóun ní. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìrírí àwọn ará àtàwọn ìròyìn nípa ilẹ̀ náà nínú Ìwé Ọdọọdún. Ó sọ pé: “Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè ní èrò tó tọ́ nípa àwọn èèyàn ilẹ̀ náà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé àwọn ará yẹn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì nítara. Ó túbọ̀ ṣe kedere sí mi pé ara ẹgbẹ́ ará kárí ayé làwọn náà.” Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Ruth tún rí i pé àwọn nǹkan míì wà tó yẹ kóun ṣe. Ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí mo bá pàdé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wá láti orílẹ̀-èdè yẹn, mo máa ń tiraka gan-an láti yá mọ́ wọn. Mo máa ń bá wọn sọ̀rọ̀, mo sì máa ń gbìyànjú láti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́.” Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ruth sọ pé: “Kí n tó mọ̀, mi ò ní èrò òdì nípa wọn mọ́.”

Tá a bá “nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará” látọkàn wá, a ò ní máa ṣojúsàájú (Wo ìpínrọ̀ 12 àti 13) *

12. Ìṣòro wo ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah ní?

12 Àwọn kan lè máa ṣojúsàájú láìfura. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arábìnrin Sarah tó gbà pé òun kì í ṣe ojúsàájú torí ẹ̀yà tẹ́nì kan ti wá, torí bẹ́nì kan ṣe lówó tó tàbí torí pé ẹnì kan ní ojúṣe pàtàkì nínú ètò Ọlọ́rùn. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Nígbà tó yá mo wá rí i pé mò ń ṣojúsàájú.” Lọ́nà wo? Sarah àtàwọn òbí ẹ̀ kàwé gan-an, àwọn tó kàwé bíi tiwọn ló sì fẹ́ràn àtimáa bá ṣọ̀rẹ́. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan pé: “Àwọn tó kàwé láàárín àwọn ará nìkan lọ̀rẹ́ mi. Mi ò gba tàwọn yòókù yẹn rárá.” Ẹ ò rí i pé ó yẹ kí Sarah yí ojú tó fi ń wo nǹkan pa dà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ló wá ṣe?

13. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Sarah?

13 Alábòójútó àyíká kan ló tún ojú ìwòye Sarah ṣe. Ó sọ pé: “Arákùnrin yẹn gbóríyìn fún mi bí mo ṣe ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, tí mo máa ń dáhùn nípàdé, tí mo sì lóye Ìwé Mímọ́ dáadáa. Ó wá sọ fún mi pé béèyàn ṣe túbọ̀ ń lóye Ìwé Mímọ́, bẹ́ẹ̀ ló yẹ kó máa hàn nínú ìwà ẹ̀, kó túbọ̀ jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ tó sì jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú.” Sarah mọrírì ohun tí alábòójútó àyíká yẹn sọ fún un, ó sì fi í sílò. Ó sọ pé: “Ó wá yé mi pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí n nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, kí n sì máa ṣe dáadáa sí wọn.” Níkẹyìn, Sarah bẹ̀rẹ̀ sí í fojú tó tọ́ wo gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ó fi kún ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé: “Mo gbìyànjú láti mọ àwọn ànímọ́ tó mú kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ará yẹn.” Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ yìí? Ká má ṣe fojú pa àwọn míì rẹ́ torí pé wọn ò kàwé tó wa! Tá a bá “nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará” látọkàn wá, a ò ní máa ṣe ojúsàájú.​—1 Pét. 2:17.

Ẹ MÁA ṢE AÁJÒ ÀLEJÒ

14. Bó ṣe wà nínú Hébérù 13:16, báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tá a bá ṣe àwọn míì lálejò?

14 Jèhófà mọyì ẹ̀ gan-an tá a bá ń ṣe àwọn èèyàn lálejò. (Ka Hébérù 13:16.) Tá a bá ń ṣe aájò àlejò, pàápàá tá à ń ṣèrànwọ́ fáwọn aláìní, Jèhófà gbà pé òun là ń bọlá fún, ó sì tún kà á sí apá kan ìjọsìn wa sí òun. (Jém. 1:27; 2:14-17) Abájọ tí Ìwé Mímọ́ fi rọ̀ wá pé ká “máa ṣe aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) Tá a bá ń ṣe àwọn èèyàn lálejò, ńṣe là ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a mọyì wọn, a sì fẹ́ mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ṣe àwọn míì lálejò, ì báà jẹ́ ìpápánu tàbí oúnjẹ tàbí ohun mímu la fún wọn, kódà kó jẹ́ àkókò wa la yọ̀ǹda fún wọn. (1 Pét. 4:8-10) Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tí kì í jẹ́ kó rọrùn láti ṣe àwọn èèyàn lálejò.

“Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mi ò kì í gba àwọn èèyàn lálejò, àmọ́ mo ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí, mo sì ń láyọ̀ gan-an”(Wo ìpínrọ̀ 16) *

15-16. (a) Kí nìdí táwọn kan kì í fẹ́ ṣe àwọn èèyàn lálejò? (b) Kí ló mú kí Arábìnrin Edit bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn èèyàn lálejò?

15 Bí nǹkan ṣe rí fún wa lè mú kó ṣòro fún wa láti máa ṣe àwọn èèyàn lálejò. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin opó kan tó ń jẹ́ Edit. Kó tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, ó sì fẹ́ràn kó máa dá wà. Ó gbà pé àwọn tó rí jájẹ ju òun lọ ló lè máa ṣàlejò.

16 Lẹ́yìn tí Edit di Ẹlẹ́rìí, ó yí èrò ẹ̀ pa dà, ó sì gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tó jẹ́ kó lè máa ṣe àwọn èèyàn lálejò. Ó sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun fún wa, alàgbà kan bi mí bóyá màá lè gba tọkọtaya kan tó wà lára àwọn tó wá bá wa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sílé fún ọ̀sẹ̀ méjì. Mo wá rántí bí Jèhófà ṣe bù kún opó Sáréfátì.” (1 Ọba 17:12-16) Edit gbà pé òun máa gba tọkọtaya náà sílé. Ṣé Jèhófà sì bù kún un? Ẹ gbọ́ ohun tó sọ, ó ní: “A ò tiẹ̀ mọ̀gbà tí ọ̀sẹ̀ méjì di oṣù méjì bá a ṣe gbádùn ara wa tó. Ìyẹn sì mú ká di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.” Jèhófà tún mú kí Edit ní àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nínú ìjọ. Ní báyìí, ó ti di aṣáájú-ọ̀nà, ó sì ń gbádùn kó máa bá àwọn míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Tí wọ́n bá parí, wọ́n á jọ darí sílé ẹ̀ láti fi nǹkan panu. Ó wá sọ pé: “Ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀, èèyàn á láyọ̀ tó bá ń fúnni ní nǹkan! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ni mò ń rí gbà torí pé mò ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn.”​—Héb. 13:1, 2.

17. Kí ló túbọ̀ ṣe kedere sí Arákùnrin Luke àtìyàwó rẹ̀?

17 Ó ṣeé ṣe ká máa ṣe àwọn èèyàn lálejò, àmọ́ ṣé a lè sunwọ̀n sí i? Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Luke àti ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ràn àtimáa ṣe àwọn èèyàn lálejò. Wọ́n sábà máa ń pe àwọn òbí wọn, àwọn ìbátan wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ títí kan alábòójútó àyíká àtìyàwó rẹ̀ sílé wọn. Àmọ́ Luke sọ pé, “Ó wá túbọ̀ ṣe kedere sí wa pé àwọn tó sún mọ́ wa nìkan la máa ń ṣe lálejò.” Kí wá ni Luke àtìyàwó ẹ̀ ṣe kí wọ́n lè sunwọ̀n sí i?

18. Kí ni Luke àtìyàwó ẹ̀ ṣe kí wọ́n lè sunwọ̀n sí i?

18 Luke àtìyàwó ẹ̀ ṣe àwọn àtúnṣe kan lẹ́yìn tí wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ yín, kí ni èrè yín?” (Mát. 5:45-47) Wọ́n rí i pé á dáa káwọn fara wé Jèhófà tó máa ń ṣoore fún gbogbo èèyàn, láìyọ ẹnì kankan sílẹ̀. Torí náà, wọ́n pinnu pé àwọn máa pe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin táwọn ò tíì pè tẹ́lẹ̀. Luke wá sọ pé: “Gbogbo wa pátá la máa ń gbádùn ìkórajọ yẹn, ó ti dùn jù! A máa ń fún ara wa níṣìírí, a sì máa ń gbé ara wa ró.”

19. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wá, kí lo sì pinnu láti ṣe?

19 A ti jíròrò bí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tá a ní fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì ṣe lè mú ká jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ká máa ṣe aájò àlejò, ká má sì máa ṣe ojúsàájú. Torí náà, ká má ṣe jẹ́ kí èrò òdì mú wa kẹ̀yìn sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kàkà bẹ́ẹ̀ ká rí i pé a nífẹ̀ẹ́ wọn látọkàn wá. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá láyọ̀, àá sì fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wá lóòótọ́.​—Jòh. 13:17, 35.

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

^ ìpínrọ̀ 5 Jésù sọ pé ìfẹ́ làwọn èèyàn fi máa dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, àá sapá láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn, a ò ní máa ṣojúsàájú, àá sì máa ṣe aájò àlejò. Ohun tá a sọ yìí lè dùn ún sọ, àmọ́ ó lè má fìgbà gbogbo rọrùn. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan pàtó táá jẹ́ ká túbọ̀ máa fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn látọkàn wá.

^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń ṣe ohun táá mú kí àlàáfíà wà láàárín òun àti arábìnrin míì. Lákọ̀ọ́kọ́, arábìnrin kejì kò gbà fún un, àmọ́ arábìnrin àkọ́kọ́ náà kò jẹ́ kó sú òun. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, arábìnrin yẹn gbà, wọ́n sì yanjú ọ̀rọ̀ náà..

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Ó ń ṣe arákùnrin àgbàlagbà kan bíi pé àwọn yòókù nínú ìjọ pa á tì.

^ ìpínrọ̀ 61 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan tí kì í yá lára tẹ́lẹ̀ láti máa gbàlejò yí èrò ẹ̀ pa dà, ó sì ń láyọ̀ gan-an ní báyìí tó ti ń gbàlejò.