KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ WÀÁ GBA Ẹ̀BÙN ỌLỌ́RUN TÓ DÁRA JÙ?
Kí Lo Máa Ṣe sí Ẹ̀bùn Ọlọ́run Tó Dára Jù Lọ?
“Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa . . . Ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn.”—2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.
TÁ A bá gba ẹ̀bùn bàǹtàbanta lọ́wọ́ ẹnì kan, ó máa yá wa lórí láti fẹ̀mí ìmoore hàn. Jésù tẹ ẹ̀kọ́ yìí mọ́ wa lọ́kàn lẹ́yìn tó mú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá kan lára dá, àìsàn tó ń ṣe wọ́n burú débi pé kò sí ẹni tó lè wò wọ́n sàn lásìkò yẹn. Àmọ́, ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin aláìsàn náà “padà, ó ń fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo.” Jésù wá sọ pé: “Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ni a wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn mẹ́sàn-án yòókù wá dà?” (Lúùkù 17:12-17) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́? Kò yẹ ká tètè máa gbàgbé oore táwọn míì bá ṣe fún wa.
Kò sí ẹ̀bùn tó dà bí ìràpadà. Gbogbo ọ̀nà ló fi jẹ́ ẹ̀bùn tó dára jù lọ tẹ́nì kan lè fún wa. Kí ló wá yẹ kó o ṣe sí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ẹ yìí?
-
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹni tó fún ẹ. Ìràpadà yìí kò túmọ̀ sí pé ọwọ́ kan ni gbogbo aráyé máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Tó o bá mọ̀ pé ọkùnrin kan ni kò jẹ́ kó o kú nígbà tó o wà ní kékeré, ṣé kò ní wù ẹ́ láti túbọ̀ mọ ẹni náà àti ìdí tó fi gba ẹ̀mí rẹ là? Jéhòfà Ọlọ́run ló fún ẹ ní ẹ̀bùn ìràpadà, ó sì fẹ́ kó o mọ òun, kó o sì tún ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
-
Ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà. “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:36) Kí ló túmọ̀ sí láti lo ìgbàgbọ́? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká ṣe nǹkan kan. (Jákọ́bù 2:17) Irú nǹkan wo? Kí ẹ̀bùn kan tó lè di tìẹ, o máa ní láti nawọ́ gbà á. Torí náà, o ní láti sapá kó o sì gba ìràpadà náà. Báwo? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó o gbé ìgbésí ayé rẹ, kó o sì ṣe bẹ́ẹ̀. * Gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó dárí jì ẹ́, kó sì fún ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ẹ̀bùn ìràpadà yìí máa mú ká ní ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú, níbi tí ohun gbogbo tá a bá ń ṣe á máa yọrí sí rere, àlááfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn sì máa wà fún gbogbo àwọn tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà!—Hébérù 11:1.
-
Lọ síbi Ìrántí Ikú Jésù. Jésù dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fẹ́ ká máa ṣe é lọ́dọọdún ká lè máa rántí ìràpadà yìí. Ó sọ báyìí pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù ní Tuesday, April 11, 2017, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Ìtòlésẹẹsẹ náà máa gbà tó wákàtí kan, níbẹ̀ a máa gbọ́ àsọyé kan tó ṣàlàyé ohun tí ikú Jésù túmọ̀ sí, àǹfààní tó ń fún wa báyìí àti ohun tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú. Lọ́dún tó kọjá, ó tó nǹkan bíi ogún [20] mílíọ̀nù èèyàn tó wà síbi Ìrántí Ikú Jésù kárí ayé. Inú wa dùn láti pé ìwọ náà wá ká lè jọ fẹ̀mí ìmoore hàn fún ẹ̀bùn Ọlọ́run tó dára jù lọ yìí.
^ ìpínrọ̀ 7 Ọ̀nà tó dáa jù lọ láti mọ Ọlọ́run, ká sì sún mọ́ ọn ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè ṣe èyí, o lè ní kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì wa, www.pr2711.com/yo.