Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lè Wà Láàyè Títí Láé Lórí Ilẹ̀ Ayé

O Lè Wà Láàyè Títí Láé Lórí Ilẹ̀ Ayé

ÌRÈTÍ ÀGBÀYANU NÌYẸN O! Ẹlẹ́dàá wa ti ṣèlérí fún wa pé a máa wà láàyè títí láé, lórí ilẹ̀ ayé níbí. Èyí ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà gbọ́. Wọ́n tiẹ̀ máa ń sọ pé, ‘Gbogbo wa la ti dá agbádá ikú.’ Àmọ́ àwọn kan gbà pé ó ṣeé ṣe fún èèyàn láti wà láàyè títí láé, àmọ́ kì í ṣe lórí ilẹ̀ ayé níbí, wọ́n ní ó dìgbà téèyàn bá kú tó sì lọ sọ́run. Kí lèrò ẹ?

Kó o tó dáhùn, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ wo ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: Kí ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá wa fi hàn nípa bó ṣe fẹ́ kí ẹ̀mí wa gùn tó? Kí ni ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé yìí àti aráyé lápapọ̀? Kí nìdí tá a fi ń kú?

ÀWA ÈÈYÀN ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀

Nínú gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá sáyé, àwa èèyàn ṣàrà ọ̀tọ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn nìkan ni Ọlọ́run dá ní “àwòrán” àti “ìrí” ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:​26, 27) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run dá àwọn ànímọ́ kan mọ́ wa ká lè fìwà jọ ọ́, irú bí ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo.

Ní àfikún síyẹn, Ọlọ́run fún àwa èèyàn ní làákàyè, a lè ronú, a lè mọ ìyàtọ̀ láàárín nǹkan tó dára àtèyí tí kò dára, a tún láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, ká sì jọ́sìn rẹ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi lè mọyì àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá, títí kan orin àti ewì. Àmọ́ nínú gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá sáyé, àwa ẹ̀dá èèyàn nìkan la lè jọ́sìn Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé àti ọ̀run. Èyí ló jẹ́ ká ṣàrà ọ̀tọ̀.

Tiẹ̀ rò ó wò ná: Ṣé Ọlọ́run máa dá àwọn ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yẹn mọ́ wa, tó fi mọ́ oríṣiríṣi àrà tá a lè fi àwọn ẹ̀bùn tó fún wa dá, tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ló fẹ́ káwa èèyàn fi wà láàyè? Rárá! Ńṣe ni Ọlọ́run fún wa láwọn ànímọ́ àtàwọn ẹ̀bùn yìí ká lè máa gbádùn ara wa lórí ilẹ̀ ayé níbí títí láé.

OHUN TÍ ỌLỌ́RUN NÍ LỌ́KÀN FÚN WA

Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run ò dá àwa èèyàn láti máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n sọ pé ọ̀run ni ilé àwa èèyàn àti pé ohun tá a bá ṣe láyé ló máa pinnu bóyá a máa lọ sọ́run láti lọ gbé pẹ̀lú Ọlọ́run títí láé. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ṣe ló máa dà bíi pé Ọlọ́run ló ń fa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Àmọ́ ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.”​—Diutarónómì 32:4.

Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tó dá ayé yìí, ó ní: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sáàmù 115:16) Bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn o, Ọlọ́run dá ayé yìí lọ́nà tó rẹwà, kí àwa èèyàn lè máa gbé títí láé lórí rẹ̀, ó sì fi gbogbo nǹkan tá a nílò síbẹ̀ ká lè máa gbádùn ara wa títí láé.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:​8, 9.

“Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”​—Sáàmù 115:16

Bíbélì tún jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn. Ọlọ́run sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: ‘Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.’ (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ẹ ò rí i pé àǹfààní nìyẹn fún Ádámù àti Éfà láti sọ gbogbo ayé di Párádísè! Ẹ ò rí i báyìí pé kì í ṣe ọ̀run ni Ọlọ́run fẹ́ kí Ádámù àti Éfà máa gbé, ohun tó fẹ́ ni pé kí wọ́n wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.

KÍ NÌDÍ TÁ A FI Ń KÚ?

Kí wá nìdí tá a fi ń kú? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú kan tó ń jẹ́ Sátánì Èṣù ló fẹ́ dènà ohun tí Ọlọ́run fé ṣe. Báwo ló ṣe ṣe é?

Sátánì fọgbọ́n tan Ádámù àti Éfà jẹ kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ọn láti dìtẹ̀ sí Ọlọ́run. Sátánì sọ fún wọn pé ńṣe ni Ọlọ́run ń fi ohun rere kan dù wọ́n bí kò ṣe jẹ́ kí wọ́n máa pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Wọ́n gba Sátánì gbọ́, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ikú ni. Ọlọ́run sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ohun tó máa gbẹ̀yìn wọn nìyẹn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀. Bó ṣe di pé wọn ò lè wà láàyè títí láé nìyẹn.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:​1-6; 5:5.

Gbogbo wa pátá là ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: ‘Ẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.’ (Róòmù 5:12) Ìdí tá a fi ń kú ni pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, kì í ṣe pé Ọlọ́run ti dá ikú mọ́ wa, Ọlọ́run ò sì fẹ́ kó máa rí bẹ́ẹ̀.

O LÈ WÀ LÁÀYÈ TÍTÍ LÁÉ LÓRÍ ILẸ̀ AYÉ

Ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì kò dí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún àwa èèyàn. Nítorí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ó fún wa lóhun tó máa jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ikú àti ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó “fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Àmọ́ Jésù ra gbogbo ohun tí Ádámù sọ nù pa dà nígbà tó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ. a

Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ayé yìí sì máa di Párádísè. Tó o bá fi ìmọ̀ràn Jésù sọ́kàn, ìwọ náà lè wà nínú Párádísè yẹn, kó o sì gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Ọlọ́run ní fún wa. Jésù sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:​13, 14) Fi sọ́kàn pé ohun tó o bá ṣe báyìí ló máa pinnu bí ọjọ́ ọ̀la rẹ ṣe máa rí. Kí ni wàá ṣe?

a Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ìràpadà àti bó o ṣe lè jàǹfààní látinú rẹ̀, wo ẹ̀kọ́ 27 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, o tún lè rí i wà jáde lọ́fẹ̀ẹ́ lórí ìkànnì wa www.pr2711.com/yo