ILÉ ÌṢỌ́ No. 2 2019 | Ayé Rẹ Ṣì Máa Dùn!
Ṣé ìṣòro ti bò ẹ́ mọ́lẹ̀ débi tó o fi béèrè pé ṣé ayé mi ṣì lè dùn?
Tí Ìṣòro Bá Pọ̀ Lápọ̀jù
Ayé rẹ ṣì máa dùn láìka ìṣòro sí.
Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn ohun tá a lè ṣe láti borí ẹ̀dùn ọkàn wa nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.
Tí Ẹnì Kan Tó O Fẹ́ràn Bá Kú
Wo ohun márùn-ún tó o lè ṣe tí ẹnì kan tó o fẹ́ràn bá kú.
Tí Ẹnì Kejì Rẹ Bá Ṣe Ìṣekúṣe
Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí ìtùnú nínú Ìwé Mímọ́ nígbà tí ẹni kejì wọn ṣe ìṣekúṣe.
Tí Àìsàn Burúkú Bá Ń Ṣe Ẹ́
Kọ́ nípa ohun tó ti ran àwọn kan lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń sàìsàn tó le koko.
Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Pa Ara Rẹ
Ṣé ìṣòro ti mu ẹ́ lómi débi tó o fi ronú pé ó sàn kó o kúkú pa ara rẹ? Ibo lo ti lè rí ìrànlọ́wọ́?
Ayé Rẹ Ṣì Máa Dùn!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lè má fi bẹ́ẹ̀ lóye ìṣòro rẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ, ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.
“Ó Bìkítà fún Ẹ”
Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí máa tù ẹ́ nínú, wọ́n á sì fún ẹ lókun.