Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa, Ó Sì Ń Bójú Tó Wa
1. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń MÚ KÍ OÒRÙN RÀN
Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí tí kò bá sí oòrùn? Oòrùn ló ń fún àwọn igi lágbára tí wọ́n fi ń mú ewé, òdòdó, èso, àwọn ẹ̀pà àti irúgbìn jáde. Òun ló tún máa ń jẹ́ káwọn igi fi gbòǹgbò wọn fa omi láti ilẹ̀ lọ sára àwọn ewé tí omi náà á sì lọ sínú afẹ́fẹ́.
2. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń MÚ KÍ ÒJÒ RỌ̀
Ẹ̀bùn pàtàkì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òjò jẹ́, ó sì ń mú kí ilẹ̀ mú oríṣiríṣi oúnjẹ jáde. Ọlọ́run ń fún wa ní òjò látọ̀run àti àkókò èso, ìyẹn ń jẹ́ ká gbádùn oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn, ó sì ń mú kí ọkàn wa yọ̀.
3. ẸLẸ́DÀÁ WA Ń PÈSÈ OÚNJẸ ÀTI AṢỌ
Ọ̀pọ̀ àwọn bàbá máa ń wá bí wọ́n á ṣe pèsè oúnjẹ àti aṣọ fún ìdílé wọn. Wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ó ní: “Kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni?”—Mátíù 6:25, 26.
“Kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà . . . ; àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí. Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ . . . , ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ?”—Mátíù 6:28-30.
Nítorí pé Ọlọ́run pèsè oúnjẹ àti aṣọ fún wa, ó dájú pé ó máa jẹ́ ká rí àwọn ohun mìíràn tá a nílò. Tá a bá ń wá bá a ṣe máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run á fi èrè sí iṣẹ́ wa kí àwọn ohun ọ̀gbìn wa lè méso jáde tàbí kó pèsè iṣẹ́ tó máa jẹ́ ká lè rówó ra àwọn ohun tá a nílò.—Mátíù 6:32, 33.
Ó dájú pé a máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an tá a bá ronú nípa oòrùn, òjò, àwọn ẹyẹ àti òdòdó. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa sọ bí Ọlọ́run ṣe ń bá aráyé sọ̀rọ̀.