Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | Ẹ̀BÙN WO LÓ JU GBOGBO Ẹ̀BÙN LỌ?

Bá A Ṣe Lè Rí Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Fúnni

Bá A Ṣe Lè Rí Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Fúnni

Ó máa ń gba ìsapá gan-an ká tó lè rí ẹ̀bùn fún ẹnì kan kó sì kà á sí ẹ̀bùn tó dáa jù. Tẹ́ni náà bá mọyì ẹ̀bùn náà ló máa fi hàn bí ẹ̀bùn náà ti ṣe pàtàkì tó. Ohun tí ẹnì kan kà sí pàtàkì sì lè máà ṣe pàtàkì lójú ẹlòmíì.

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ kan lè ronú pé àwọn ohun èlò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lẹ̀bùn tí òun máa fẹ́ràn jù láti gbà. Àwọn tó ti dàgbà máa ń mọyì kí wọ́n jogún nǹkan pàtàkì látọ̀dọ̀ ìdílé wọn. Láwọn ilẹ̀ kan, tọmọdé tàgbà ló máa ń mọyì kéèyàn fún wọn lówó kí wọ́n lè fi ra ohun tí wọ́n bá fẹ́.

Láìka bó ṣe nira tó, ọ̀pọ̀ onínúure èèyàn ló ṣì ń wá ẹ̀bùn tó dáa jù láti fún èèyàn wọn kan tó ṣe pàtàkì sí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn láti rí irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀, a ṣì lè fi àwọn kókó kan sọ́kàn tá a jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ẹ̀bùn tó dáa. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́rin táá mú kí ẹ̀bùn tá a fún ẹni náà tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Ohun tó wu ẹni tá a fún. Ọkùnrin kan nílùú Belfast, ní Àríwá orílẹ̀-èdè Ireland sọ pé kẹ̀kẹ́ tẹ́nì kan fún òun nígbà tóun wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mọ́kànlá lẹ̀bùn tóun fẹ́ràn jù. Kí nìdí? Ó ṣàlàyé pé: “Torí ó wù mí gan-an kí n nírú kẹ̀kẹ́ yẹn.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí fi hàn pé ohun tó bá wu ẹnì kan ló máa pinnu bóyá ó máa mọyì ẹ̀bùn tá a fún un. Torí náà, ronú nípa ẹni tó o fẹ́ fún lẹ́bùn. Gbìyànjú láti mọ ohun tó kà sí pàtàkì, torí ohun téèyàn bá kà sí pàtàkì ló máa ń wuni. Bí àpẹẹrẹ, ohun pàtàkì làwọn òbí àgbà kà á sí tàwọn ìdílé wọn bá wá kí wọn. Ó lè máa wọ́n láti rí àwọn ọmọ wọn àtàwọn ọmọ-ọmọ wọn látìgbàdégbà. Tẹ́ ẹ bá mú àwọn òbí àgbà dání pẹ̀lú ìdílé yín nígbà tẹ́ ẹ̀ ń ṣeré jáde, ó ṣeé ṣe kí wọ́n mọyì rẹ̀ ju ẹ̀bùn míì tẹ́ ẹ bá fún wọn.

Ọ̀nà kan téèyàn lè gbà mọ ohun tẹ́nì kan nífẹ̀ẹ́ sí ni pé ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Jákọ́bù 1:19) Bó o ṣe ń bá ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, fetí sílẹ̀ dáadáa kó o lè mọ ohun tó ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ́ àtohun tí wọn kò fẹ́. Ìyẹn á sì mú kó o lè fún wọn ní ẹ̀bùn tí wọ́n á mọyì gan-an.

Ohun tẹ́ni náà nílò. Ẹni tó o fún lẹ́bùn máa mọyì rẹ̀ gan-an kódà kó jẹ́ ẹ̀bùn tó kéré, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé ohun tó nílò gan-an nìyẹn lásìkò yẹn. Àmọ́ báwo lo ṣe lè mọ ohun tí ẹnì kan nílò?

Ó lè fẹ́ dá bíi pé ohun tó rọrùn jù ni pé kéèyàn béèrè ohun tẹ́ni náà nílò lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó bá fẹ́ fúnni lẹ́bùn, wọn kì í fẹ́ kẹ́ni tí wọ́n fẹ́ fún lẹ́bùn mọ̀ tẹ́lẹ̀ torí kò ní jẹ́ kó jọ wọ́n lójú mọ́, á sì dín ayọ̀ téèyàn máa ń rí nínú fífúnni lẹ́bùn kù. Nǹkan míì tún ni pé, àwọn kan máa ń sọ ohun tí wọ́n fẹ́ àtohun tí wọn ò fẹ́, àmọ́ wọn kì í fẹ́ sọ ohun tí wọ́n nílò.

Torí náà, máa fara balẹ̀ ṣàkíyèsí kó o sì mọ ipò tó yí ẹni náà ká. Ṣé ọmọdé ni àbí àgbàlagbà, ó ti lọ́kọ tàbí aya, ṣé àpọ́n ṣì ni, àbí ẹni tí ọkọ tàbí aya ẹ̀ ti kọ̀ sílẹ̀, ṣé ẹni tí ìyàwó tàbí ọkọ ẹ̀ ti kú ni, ṣé ó níṣẹ́ lọ́wọ́, àbí ó ti fẹ̀yìn tì? Ronú nípa ẹ̀bùn tó máa bá ipò ẹni náà mu.

Láti mọ ohun tẹ́ni tó o fẹ́ fún lẹ́bùn máa nílò, o lè lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó wà nírú ipò tẹni náà wà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ ohun àrà ọ̀tọ̀ táwọn tó wà nírú ipò yẹn máa ń nílò tó sì jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló mọ̀ nípa rẹ̀. Ìyẹn máa jẹ́ kó o lè wá ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó sì máa wúlò fún ẹni tó o fẹ́ fún.

Àsìkò tẹ́ni náà nílò rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò mà dára o!” (Òwe 15:23) Ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé ó dáa gan-an tá a bá sọ̀rọ̀ lásìkò tó yẹ. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tá a bá ṣe ohun kan lásìkò tó yẹ. Bó ṣe jẹ́ pé ará á tu olùgbọ́ wa tá a bá sọ̀rọ̀ lásìkò tó yẹ, bẹ́ẹ̀ layọ̀ ẹni tá a fún lẹ́bùn á ṣe pọ̀ tó tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ lásìkò tó yẹ àti níbi tó tọ́.

Ọ̀rẹ́ ẹ fẹ́ ṣègbéyàwó. Ọ̀dọ́ kan fẹ́ gboyè jáde nílé ìwé. Tọkọtaya kan ò ní pẹ́ bímọ. Èyí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àsìkò téèyàn lè fúnni lẹ́bùn. Àwọn kan máa ń fẹ́ láti kọ irú àwọn àsìkò yìí sílẹ̀ tó máa wáyé lọ́dún tó ń bọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè ṣètò ẹ̀bùn tó dáa tí wọ́n máa fún onítọ̀hún lọ́jọ́ náà. *

Àmọ́ kò yẹ kó o dúró dìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan kó o tó fúnni lẹ́bùn. O lè ní ayọ̀ tó wà nínú fífúnni lẹ́bùn nígbàkigbà. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún gba ìṣọ́ra. Bí àpẹẹrẹ, tí ọkùnrin kan bá fún obìnrin kan lẹ́bùn tí kò sì sídìí kan tó ṣe gúnmọ́ tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, obìnrin yẹn lè ronú pé ẹ̀bùn náà jẹ́ àmì pé ọkùnrin yẹn fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ òun sí i ni. Àfi tó bá jẹ́ pé ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ nìyẹn, àmọ́ tí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, irú ẹ̀bùn yẹn lè dá wàhálà sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gbé àwọn kókó míì tó ṣe pàtàkì yẹ̀wò, ìyẹn ohun tó wà lọ́kàn ẹni tó ń fúnni lẹ́bùn.

Ohun tó wà lọ́kàn ẹni tó fúnni lẹ́bùn. Bá a ṣe sọ nínú àpẹẹrẹ yẹn, ó dáa ká ronú nípa ẹ̀bùn tá a fẹ́ fúnni, kí onítọ̀hún má lọ máa ro nǹkan míì. Lọ́wọ́ kejì náà, ẹni tó fẹ́ fúnni lẹ́bùn máa ní láti yẹ ọkàn rẹ̀ wò láti mọ ìdí tó fi ń fúnni lẹ́bùn. Àwọn kan máa ń fúnni lẹ́bùn pẹ̀lú èrò tó dáa lọ́kàn, àwọn míì sì máa ń fúnni lẹ́bùn láwọn àsìkò kan torí kó má bàa di ìsọlẹ́nu fún wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn míì máa ń ṣe é láti mú kí àwọn èèyàn máa fi ojú pàtàkì wò wọ́n, tàbí kí wọ́n lè rí nǹkan gbà pa dà lọ́wọ́ wọn.

Kí lo lè ṣe láti rí i pé ò ń fúnni lẹ́bùn pẹ̀lú èrò tó dáa lọ́kàn? Bíbélì sọ pé: “Kí gbogbo àlámọ̀rí yín máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 16:14) Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tòótọ́ tó o ní sí ẹni tó o fẹ́ fún lẹ̀bùn ló sún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa gbà á pẹ̀lú ayọ̀, inú ìwọ náà sì máa dùn gan an tó o bá ń fúnni pẹ̀lú ẹ̀mí tó dáa. Tó o bá ń fúnni lẹ́bùn látọkànwá, ńṣe lò ń múnú Baba wa ọ̀run dùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì àtijọ́ fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn Kristẹni bíi tiwọn tó wà ní ìlú Jùdíà. Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”​—2 Kọ́ríńtì 9:7.

Tá a bá ronú lórí àwọn ohun tá a sọ níbí yìí, á ràn wá lọ́wọ́ láti máa fáwọn èèyàn lẹ́bùn táá múnú wọn dùn. Àwọn kókó tá a sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ yìí àtàwọn míì kan ètò tí Ọlọ́run ṣe láti fún aráyé ní ẹ̀bùn tó ju gbogbo ẹ̀bùn lọ. A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka àkòrí tó kàn kó o lè mọ ẹ̀bùn àgbàyanu náà.

^ ìpínrọ̀ 13 Ọ̀pọ̀ máa ń fúnni lẹ́bùn nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣe ọjọ́ ìbí àti lásìkò ọdún. Àmọ́ àwọn nǹkan táwọn èèyàn sábà máa ń ṣe lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ yìí ni ó ta ko ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Wo àpilẹ̀kọ tó ní àkòrí náà “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé​—Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Ṣe Ọdún Kérésìmesì?” nínú ìwé ìròyìn yìí.