Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí ni Amágẹ́dọ́nì?

Àwọn kan gbà gbọ́ pé . . .

ó jẹ́ ogun runlérùnnà tó máa fa ìparun yán-án-yán bá gbogbo ibi láyé. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

Amágẹ́dọ́nì jẹ́ ibi ìṣàpẹẹrẹ fún “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tí Ọlọ́run máa fi mú àwọn ẹni ibi kúrò.​—Ìṣípayá 16:14, 16.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Ọlọ́rn máa lo ogun Amágẹ́dọ́nì láti fi gba ayé lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ bà á jẹ́, kì í ṣe láti fi pa ayé run.​—Ìṣípayá 11:18.

  • Ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa fòpin sí gbogbo ogun.​—Sáàmù 46:​8, 9.

Ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn la ogun Amágẹ́dọ́nì já?

Kí lèrò rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

“Ogunlọ́gọ̀ ńlá” látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ló máa la “ìpọ́njú ńlá” já, ìpọ́njú ńlá yìí máa dópin nígbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì bá bẹ̀rẹ̀. ​—Ìṣípayá 7:9, 14.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Ọlọ́run fẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn la ogun Amágẹ́dọ́nì já. Àwọn ẹni burúkú tí kò yí pa dà nìkan ló máa pa run.​—Ìsíkíẹ́lì 18:32.

  • Bíbélì ṣàlàyé bá a ṣe lè la ogun Amágẹ́dọ́nì já.​—Sefanáyà 2:3.