Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì Ti Wá Lóòótọ́?

Bíbélì Péye ní Gbogbo Ọ̀nà

Bíbélì Péye ní Gbogbo Ọ̀nà

Ó Péye Ní Ti Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì

BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé sáyẹ́ǹsì, òótọ́ ni gbogbo ohun tó sọ nípa àwọn ohun àrà tá a dáyé bá. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan nínú ẹ̀kọ́ nípa ojú ọjọ́ àti àbùdá èèyàn.

Ẹ̀KỌ́ NÍPA OJÚ ỌJỌ́​—OHUN TÓ Ń ṢẸLẸ̀ KÍ ÒJÒ TÓ RỌ̀

Ẹ̀KỌ́ NÍPA OJÚ ỌJỌ́

Bíbélì sọ pé: “[Ọlọ́run] a máa fa ẹ̀kán omi sókè; wọ́n a máa kán wínníwínní bí òjò fún ìkùukùu rẹ̀, tí àwọsánmà fi ń sẹ̀.”​—Jóòbù 36:​27, 28.

Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣàlàyé ohun mẹ́ta tí Ọlọ́run máa ń mú kó ṣẹlẹ̀ kí òjò tó rọ̀. (1) Oòrùn máa fa omi lọ sí ojú sánmà (2) omi náà á wá di yìnyín bó ṣe gbára jọ sójú sánmà, ìyẹn la fi máa ń sọ pé òjò ṣú; lẹ́yìn náà, á wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ pa dà sílẹ̀ bí òjò tàbí (3) kí yìnyín máa já bọ́. Síbẹ̀, gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ bí òjò ṣe ń rọ̀ kò tíì yé àwọn onímọ̀ nípa ojú ọjọ́ dáadáa títí di báyìí. Abájọ tí Bíbélì fi béèrè pé: “Ta ní lè lóye ipele àwọsánmà?” (Jóòbù 36:29) Ẹlẹ́dàá wa mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ kí òjò tó rọ̀, ó sì rí i dájú pé ẹni tó kọ ẹsẹ Bíbélì yìí ṣàlàyé àwọn nǹkan yìí dáadáa lọ́nà tó péye sínú Bíbélì. Ó sì ti jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ yìí wà nínú Bíbélì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó bẹ́rẹ̀ sí í ṣèwádìí nípa rẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ NÍPA ÀBÙDÁ ÈÈYÀN​—BÍ ỌLẸ̀ ṢE Ń DI ỌMỌ

ÀBÙDÁ ÈÈYÀN

Lára àwọn tó kọ Bíbélì ni Ọba Dáfídì, ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀.” (Sáàmù 139:16) Ewì ni Dáfídì fi jẹ́ ká mọ̀ pé bí ọlẹ̀ ṣe ń dàgbà, ńṣe ló dà bíi pé ó ń tẹ̀ lé ìlànà kan tó ti wà ní àkọsílẹ̀ nínú “ìwé.” Ó yani lẹ́nu gan-an pé láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ yìí ti wà nínú Bíbélì!

Àmọ́, nǹkan bí ọdún 1850 ni Gregor Mendel, ọmọ ilẹ̀ Austria kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ewéko ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ àwọn ìlànà tó wà nídìí àbùdá èèyàn. Bákan náà, April 2003 ni àwọn olùṣèwádìí ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìwádìí nípa àbùdá èèyàn, ìyẹn àwọn ohun tó dà bí ìsọfúnni tó para pọ̀ mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan di ẹ̀dá alààyè. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ńṣe ni àbùdá èèyàn dà bí ìwé atúmọ̀ èdè kan tí gbogbo lẹ́tà “a” “b” “d” kún inú rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ló dà bí ìlànà tó máa pinnu bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe máa rí. Ìlànà yìí ni gbogbo ẹ̀yà ara tó wà nínú ọlẹ̀ máa ń tẹ̀ lé; ìyẹn àwọn nǹkan bí ọpọlọ, ọkàn, èdọ̀fóró, apá àti ẹsẹ̀. Ńṣe ni wọ́n á sì máa dàgbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé àti ní àkókò tó yẹ kálukú wọn. Abájọ tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fi pe ohun tó para pọ̀ di àbùdá èèyàn ní “ìwé ẹ̀mí.” Báwo ni Ọba Dáfídì ṣe mọ̀ pé ńṣe ni ọlẹ̀ tàbí àbùdá èèyàn dà bí ìwé àkọsílẹ̀ kan? Ó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà * ni ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ mi, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wà lórí ahọ́n mi.”​—2 Sámúẹ́lì 23:2.

Ó Sọ Bí Ọjọ́ Ọ̀la Ṣe Máa Rí Gẹ́lẹ́

BÓYÁ la lè rí èèyàn kan tó lè sọ ìgbà, àsìkò àti bí àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn ìlú kan á ṣe di alágbára tàbí bí wọ́n á ṣe pa run. Àmọ́, Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn ìjọba alágbára kan àtàwọn ìlú kan ṣe máa dahoro. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì.

BÍ BÁBÍLÓNÌ ṢE PA RUN TÓ SÌ DAHORO

Bábílónì àtijọ́ jẹ́ orílẹ̀-èdè alágbára kan, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ló fi ṣàkóso, àkóso rẹ̀ sì nasẹ̀ dé gbogbo ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Éṣíà. Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Bábílónì ló tóbi jù láyé. Àmọ́, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì [200] ọdún ṣáájú, Ọlọ́run mí sí Aísáyà tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Kírúsì ló máa ṣẹ́gun ìlú Bábílóní àti pé kò ní sí ẹnì kan tó máa gbé ibẹ̀ títí láé. (Aísáyà 13:​17-20; 44:​27, 28; 45:​1, 2) Ṣé bó sì ṣe ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ náà nìyẹn?

ÌTÀN

Lóru ọjọ́ kan, ìyẹn ní October 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Kírúsì Ńlá ṣẹ́gun ìlú Bábílónì. Nígbà tó yá, kòtò omi tí wọ́n gbẹ́ yíká ìlú náà dí pa, torí pé kò sẹ́ni tó tún un ṣe mọ́. Nígbà tó fi máa di ọdún 200 Sànmánì Kristẹni, ìlú náà ti dahoro. Títí di òní olónìí, Bábílóní ṣì wà ní ahoro. Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí, Bábílóní ti “di ahoro látòkè délẹ̀.”​—Jeremáyà 50:13.

Ibo ni àwọn tó kọ Bíbélì ti rí ìsọfúnni nípa ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀ tó sì péye bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé, ó jẹ́ “ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Bábílónì, èyí tí Aísáyà ọmọkùnrin Émọ́sì rí nínú ìran.”​—Aísáyà 13:1.

NÍNÉFÈ MÁA DI “ILẸ̀ ALÁÌLÓMI BÍ AGINJÙ”

Ìlú ńlá ni Nínéfè. Olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Ásíríà ni, ó sì ní àwọn ilé mèremère tó jẹ́ àwòṣífìlà. Ìlú náà ní àwọn òpópónà tó fẹ̀, àwọn ọgbà ìtura, àwọn tẹ́ńpìlì òrìṣà, àtàwọn ààfin gìrìwò-gìrìwò. Síbẹ̀, wòlíì Sefanáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìlú ńlá yìí pé, ‘Nínéfè yóò di ahoro, ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi bí aginjù.’​—Sefanáyà 2:​13-15.

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ọdún kí Jésù tó wá sáyé, àwọn ará Bábílónì àtàwọn ará Mídíà para pọ̀ gbéjà ko ìlú Nínéfè, wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ pátápátá. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, ìlú tá a ṣẹ́gun yìí “ròkun ìgbàgbé fún ẹgbẹ̀rùn ọdún méjì àtààbọ̀ [2500].” Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn èèyàn fi ń sọ pé àwọn ò rò pé ìlú kan wà tó ń jẹ́ Nínéfè! Ìgbà tó di àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ni àwọn awalẹ̀pìtàn tó rí àwókù ìlú Nínéfè. Ibi tí ìlú Nínéfè wà lóde òní ti bà jẹ́ gan-an, àwọn oníwà ipá ò sì jẹ́ káwọn tó ń gbé ibẹ̀ gbádùn. Èyí ló mú kí àjọ Global Heritage Fund kìlọ̀ pé: “Ó ṣeé ṣe kí ìlú Nínéfè tún pa run lẹ́ẹ̀kan sí i tá ò sì ní gbúròó rẹ̀ mọ́ láé.”

Ibo ni Sefanáyà ti rí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ yìí? Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ òun wá.’​—Sefanáyà 1:1.

Bíbélì Dáhùn Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láyé

BÍBÉLÌ dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè náà rèé.

KÍ NÌDÍ TÍ ÌWÀ BURÚKÚ ÀTI ÌYÀ FI PỌ̀ LÁYÉ?

Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ gan-an nípa ìwà burúkú àti ìyà. Bíbélì sọ pé:

  1. “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”​Oníwàásù 8:9.

    Ìyà pọ̀ láyé torí pé ẹ̀dá èèyàn ò kúnjú ìwọ̀n láti ṣàkóso ara wọn, wọ́n sì tún ń hùwà ìbàjẹ́.

  2. “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”​Oníwàásù 9:11.

    Àwọn nǹkan kan máa ń ṣèèṣì ṣẹlẹ̀, irú bí àìsàn tó le gan-an, jàǹbá tàbí àjálù, ó sì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni, níbikíbi àti nígbàkigbà.

  3. Ẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.’​Róòmù 5:12.

    Nígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, èèyàn pípé ni wọ́n, kò sì sọ pé wọ́n á kú nígbà tó bá yá. Ẹ̀ṣẹ̀ “wọ ayé” nígbà tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn.

Àmọ́, kì í ṣe ìdí táwa èèyàn fi ń jìyà nìkan ni Bíbélì sọ fún wa. Ó tún sọ pé Olọ́run máa mú ìwà ibi kúrò àti pé ‘yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wa, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.’​—Ìṣípayá 21:​3, 4.

KÍ LÓ Ń ṢẸLẸ̀ SÁWỌN TÓ TI KÚ?

Bíbélì sọ pé tí èèyàn bá ti kú, onítọ̀hún ò mọ nǹkan kan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè ṣe ohunkóhun mọ́. Oníwàásù 9:5 sọ pé: “Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Tí ẹnì kan bá ti kú, gbogbo “àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé” nìyẹn. (Sáàmù 146:4) Èyí fi hàn pé téèyàn bá ti kú báyìí, ọpọlọ ṣíwọ́ iṣẹ́ nìyẹn. Onítọ̀hún ò lè ṣe ohunkóhun mọ́, kò lè ní ìmọ̀lára kankan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè ronú mọ́.

Àmọ́ kì í ṣe ipò táwọn tó ti kú wà nìkan ni Bíbélì sọ fún wa. Ó tún fún wa ní ìrètí kan tó ń múnú ẹni dùn gan-an, ìyẹn ni pé Ọlọ́run máa jí àwọn tó ti kú dìde.​—Hóséà 13:14; Jòhánù 11:​11-14.

KÍ NÌDÍ TÁ A FI WÀ LÁYÉ?

Bíbélì sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ló dá ọkùnrin àti obìnrin. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé “ọmọkùnrin Ọlọ́run” ni ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Ádámù. (Lúùkù 3:38) Ìdí tí Ọlọ́run fi dá èèyàn sáyé ni pé kí ó lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Baba rẹ̀ ọ̀run, kó máa láyọ̀, kó máa ṣe àwọn nǹkan tó máa ṣe é láǹfààní, kó sì máa gbé ayé títí láé. Torí náà, ńṣe ni Ọlọ́run dá àwa èèyàn lọ́nà tó jẹ́ pé yóò máa wù wá láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”​—Mátíù 5:3.

Bákan náà, Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:28) Kì í ṣe bá a ṣe lè mọ Ọlọ́run nìkan ni Bíbélì kọ́ wa, ó tún sọ bí ìgbé ayé wa ṣe lè ládùn nísinsìnyí àti ohun tá a lè ṣe ká lè wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú.

Wàá Jàǹfààní Púpọ̀ Tó O Bá Mọ Ọlọ́run Tó Mí Sí Bíbélì

LẸ́YÌN ọ̀pọ̀ ìwádìí, àìmọye èèyàn kárí ayé ló ti wá gbà pé Bíbélì kì í kàn ṣe ìwé àtíjọ kan lásán. Ó dá wọn lójú gbangba pé Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni Bíbélì àti pé ó jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà bá aráyé sọ̀rọ̀, tó fi mọ́ ìwọ alára! Ọlọ́run ń tipasẹ̀ Bíbélì pè ọ́ pé kó o wá mọ òun kó o sì di ọ̀rẹ́ òun. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”​—Jákọ́bù 4:8.

Àǹfààní ńlá kan wà téèyàn máa rí tó bá ń ka Bíbélì. Kí ni àǹfààní náà? Bó ṣe jẹ́ pé tá a bá ka ìwé tẹ́nì kan kọ, ó máa ń jẹ́ ká mọ nǹkan díẹ̀ nípa bí òǹkọ̀wé náà ṣe ń ronú; bákan náà tá a bá ń ka Bíbélì, ó máa jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run tó mí sí Bíbélì àti ojú tó fi ń wo nǹkan. Àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ pé o lè mọ ojú tí Ẹlẹ́dàá wa fi ń wo nǹkan, ohun tó máa ń múnú rẹ̀ dùn àti ohun tó máa ń dùn ún! Àwọn nǹkan míì tí Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ rèé:

Ṣé ó wù ẹ́ kó o mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà á dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. A máa ṣètò láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Èyí á mú kó o sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run tó mí sí Bíbélì.

A ti rí àwọn ẹ̀rí kan nínú àpilẹ̀kọ yìí tó fi hàn pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo orí 2 nínú ìwé náà Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, ó sì wà lórí ìkànnì wa, www.pr2711.com

O tún lè wo fídíò náà Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì? Ó wà lórí ìkànnì wa www.pr2711.com/yo

Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN FÍDÍÒ

^ ìpínrọ̀ 10 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.