JÍ! No. 4 2017 | Ṣé Ọwọ́ Rẹ Máa Ń Dí Jù?
Lónìí, ọwọ́ àwọn èèyàn máa ń dí débi pé wọn kì í sábà ráyè fún ẹbí àti ọ̀rẹ́, èyí ló sì máa ń fà á tí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì kì í fi í gún régé.
Báwo la ṣe lè máa lo àkókò wa bó ṣe tọ́?
Ọkùnrin ọlọgbọ́n kan sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:6.
Ìwé ìròyìn “Jí!” yìí sọ bá a ṣe lè lo àkókò wa lọ́nà tí ó tọ́ àti bá a ṣe lè mọ ohun tó yẹ ká fi sí ipò àkọ́kọ́.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ṣé Ọwọ́ Rẹ Máa Ń Dí Jù?
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló máa ń sọ pé kì í rọrùn fún àwọn láti ṣe ojúṣe àwọn níbi iṣẹ́ àti nínú ilé. Kí ló fà á? Kí lèèyàn lè ṣe nípa rẹ̀?
Ẹyẹ Arctic Tern
Nígbà kan, èrò àwọn èèyàn ni pé tí ẹyẹ arctic tern bá fò lọ fò bọ̀ láti Arctic sí Antarctica, ó máa ń gbà tó ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún méjì [35,200] kìlómítà. Àmọ́ ohun tá a wá mọ̀ nípa rẹ̀ báyìí tún yani lẹ́nu gan-an.
‘Orúkọ Rere Dára Ju Ọ̀pọ̀ Yanturu Ọrọ̀ Lọ’
Báwo la ṣe lè ní orúkọ rere kí àwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún wa?
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Nígbà Tí Àwọn Ọmọ Bá Ti Kúrò Nílé
Kì í rọrùn rárá fún àwọn òbí kan tí àwọn ọmọ bá ti dàgbà tí wọ́n sì ti kúrò nílé. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tó máa wáyé nígbà tó bá ti ku àwọn nìkan nínú ilé?
ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ
Onímọ̀ Nípa Àrùn Ọpọlọ Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́
Ọ̀jọ̀gbọ́n Rajesh Kalaria sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ rẹ̀ àti ohun tó gbà gbọ́. Kí nìdí tó fi fẹ́ràn ìmọ̀ sáyẹ́ńsì? Kí nìdí tó fi ṣèwádìí nípa bí ìwàláàyè ṣe bèrẹ̀?
OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Temptation
Tí ẹnì kan bá jẹ́ kí ìdẹwò borí òun, lára ohun tó lè yọrí sí ni pé ìdílé rẹ̀ lè tú ká, ó lè kó àìsàn burúkú tàbí kí ẹ̀rí ọkàn máa dà á láàámú. Báwo la ṣe lè yẹra fún ìdẹwò?
TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
Èso Pollia
Kò sí ewéko tàbí èso kan láyé yìí tó ní àwọ̀ búlúù tó ń tàn yanran tó èsò pollia, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sí èròjà olómi aró kankan nínú èso yìí. Kí ló mú kó máa tan yanran tó bẹ́ẹ̀?
Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì
Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ní Ìdílé Aláyọ̀?
Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n láti inú Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀.
Monica Richardson: Dókítà Kan Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́
Obìnrin yìí rò ó bóyá ẹnì kan tó gbọ́n ló ṣètò ọmọ bíbí lọ́nà àrà àbí ó kàn ṣèèṣì rí bẹ́ẹ̀. Kí lohun tó ti mọ̀ nídìí iṣẹ́ dókítà tó ń ṣe mú kó parí èrò sí?