Ìbátan Káyáfà Ni
Iṣẹ́ ìwádìí tí àwọn kan ń ṣe gba pé kí wọ́n máa hú àwọn nǹkan jáde látinú ilẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn nǹkan tí wọ́n ṣàwárí ti fi hàn pé òótọ́ ni ẹnì kan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé láyé rí. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 2011, ọ̀mọ̀wé kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì tẹ ìsọfúnni kan jáde nípa irú àwárí bẹ́ẹ̀. Wọ́n hú àpótí kan jáde látinú ilẹ̀. Òkúta ẹfun ni wọ́n fi ṣe àpótí náà lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n sì kó egungun òkú kan sínú rẹ̀. Àpótí náà ti wà lábẹ́ ilẹ̀ fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún.
Àkọlé tó wà lára àpótí náà ni: “Míríámù ọmọbìnrin Yéṣúà, ọmọkùnrin Káyáfà, àlùfáà Maasáyà láti ìlú Bẹti Ímírì.” Káyáfà ni àlùfáà àgbà àwọn Júù tó gbọ́ ẹjọ́ Jésù tó sì fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa á. (Jòh. 11:48-50) Òpìtàn náà, Flavius Josephus, pè é ní “Jósẹ́fù tí à ń pè ní Káyáfà.” Láìsí àní-àní, egungun ìbátan rẹ̀ kan ló wà nínú àpótí náà. Wọ́n ti kọ́kọ́ rí àpótí kan ṣáájú ìgbà yẹn. Àkọlé tó wà lára rẹ̀ ni Yehosef bar Caiapha, èyí tó túmọ̀ sí Jósẹ́fù ọmọkùnrin Káyáfà. * Orúkọ yìí mú kí wọ́n gbà pé egungun òkú àlùfáà àgbà náà ló wà níbẹ̀. Látàrí èyí, wọ́n gbà pé Míríámù yìí bá Káyáfà tan lọ́nà kan ṣá.
Àwọn tó ń bójú tó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì sọ pé ọwọ́ àwọn olè ni wọ́n ti gba àpótí tí wọ́n kó egungun òkú Míríámù sí yìí. Wọ́n ní àwọn olè náà jí i gbé nígbà tí wọ́n lọ sí ibì kan táwọn èèyàn máa ń sìnkú sí láyé àtijọ́. Béèyàn bá fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò àpótí náà àti ohun tí wọ́n kọ sára rẹ̀, ó máa rí i pé òótọ́ ni wọ́n sọ.
Àpótí yìí tún jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì kan. Wọ́n rí “Maasáyà” nínú àkọlé ara àpótí náà. Maasáyà yìí ló gbẹ̀yìn lára àwọn àlùfáà mẹ́rìnlélógún tí wọ́n ń pín iṣẹ́ ìsìn ṣe ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. (1 Kíró. 24:18) Látàrí ìyẹn, àwọn tó ń bójú tó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé náà sọ pé èyí tún fi hàn pé, “inú ìpín Maasáyà ni ìdílé Káyáfà ti wá.”
Orúkọ míì tó tún wà nínú àkọlé ara àpótí náà ni Bẹti Ímírì. Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń ṣàbójútó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé náà ṣe sọ, ohun méjì ló ṣeé ṣe kí Bẹti Ímírì jẹ́. “Àkọ́kọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orúkọ ìdílé àlùfáà kan tó jẹ́ ọmọ Ímérì. (Ẹ́sírà 2:36-37; Neh. 7:39-42) Àwọn àtọmọdọ́mọ Ímérì yìí sì wà lára àwọn tí wọ́n máa ń pín pa pọ̀ pẹ̀lú Maasáyà láti ṣe iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì. Èkejì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ‘Bẹti Ímírì’ ni orúkọ ìlú tí wọ́n bí Míríámù sí, tàbí kó jẹ́ pé ibẹ̀ ni gbogbo ìdílé rẹ̀ ti ṣẹ̀ wá.” Èyí ó wù kó jẹ́, àpótí tí wọ́n kó egungun òkú Míríámù sí fi hàn kedere pé kì í ṣe àwọn èèyàn inú ìtàn àròsọ lásán ni àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, bí kò ṣe àwọn èèyàn tó gbé ayé rí lóòótọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ní ìdílé tí wọ́n ti wá.
^ ìpínrọ̀ 3 Àlàyé síwájú sí i nípa àpótí tí wọ́n kó egungun òkú Káyáfà sí wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Àlùfáà Àgbà Tó Dá Jésù Lẹ́bi,” nínú Ilé Ìṣọ́ January 15, 2006, ojú ìwé 10 sí 13.