Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú ní Philippines.

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú ní Philippines.

NÍ NǸKAN bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, Gregorio àti ìyàwó rẹ̀ Marilou tí wọ́n ti lé díẹ̀ ní ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún nígbà yẹn, ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Manila, wọ́n sì tún ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ń gbà wọ́n lákòókò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, wọ́n ń yí i mọ́ra, wọ́n sì ń ṣe méjèèjì pọ̀. Nígbà tó yá, wọ́n sọ Marilou di máníjà ní báńkì tó ti ń ṣiṣẹ́. Ó sọ pé: “Torí pé a ní iṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́, à ń gbádùn ìgbésí ayé wa dáadáa.” Kódà, owó ń wọlé fún wọn gan-an débi pé wọ́n pinnu láti kọ́ ilé aláràbarà kan tí wọ́n tí ń ronú nípa rẹ̀ tipẹ́. Wọ́n fẹ́ láti kọ́ ọ sí ibi tó dáa, èyí tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mọ́kàndínlógún [19] ní ìlà oòrùn ìlú Manila. Wọ́n gbé iṣẹ́ náà fún abánikọ́lé kan, wọ́n sì jọ ṣe àdéhùn pé àwọn á máa san owó ilé náà díẹ̀díẹ̀ lóṣooṣù fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá.

“Ó Ń ṢE MÍ BÍI PÉ MÒ Ń JA JÈHÓFÀ LÓLÈ”

Marilou sọ pé: “Iṣẹ́ máníjà tí mò ń ṣe yẹn ń gbà mí lákòókò, ó sì ń tán mi lókun débi pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè fáwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí mọ́. Ó ń ṣe mí bíi pé mò ń ja Jèhófà lólè.” Ó tún sọ pé: “Mi ò wá fún Jèhófà ní àkókò tí mo ti pinnu pé màá máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ mọ́.” Inú tọkọtaya yìí ò dùn sí bí nǹkan ṣe ń lọ. Torí náà, lọ́jọ́ kan, wọ́n jókòó, wọ́n sì jọ sọ̀rọ̀ nípa ibi tí ìgbésí ayé wọn ń forí lé. Gregorio sọ pé: “Ó wù wá láti ṣe àwọn ìyípadà, àmọ́ a ò mọ ohun tó yẹ ká ṣe gan-an. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé a ò tíì bímọ kankan, a jíròrò bá a ṣe lè túbọ̀ lo ara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. A sì bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà.”

Ní àsìkò yẹn, Gegorio àti Marilou gbọ́ ọ̀pọ̀ àsọyé nípa àwọn ará tó lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Gregorio sọ pé: “A gbà pé ńṣe ni Jèhófà lo àwọn àsọyé yẹn láti dáhùn àdúrà wa.” Wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àwọn túbọ̀ lágbára káwọn lè ní ìgboyà láti ṣe ìpinnu tó tọ́. Ohun tó wá jẹ́ olórí ìṣòro wọn ni ilé wọn tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́, torí pé wọ́n ti san owó ọdún mẹ́ta. Kí ni wọ́n máa wá ṣe báyìí? Marilou sọ pé: “Tá a bá sọ pé a ò kọ́lé mọ́, ṣe la máa pàdánù gbogbo owó tá a ti san, owó yẹn sì pọ̀ gan-an ni. Àmọ́, a wá wò ó bí ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn bóyá ìfẹ́ Jèhófà la máa fi sípò àkọ́kọ́ tàbí ìfẹ́ tara wa.” Nígbà tí wọ́n ronú lórí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé òun gbà láti pàdánù ohun gbogbo, wọ́n pa ilé tí wọ́n ń kọ́ tì, wọ́n fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀, wọ́n ta èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ohun ìní wọn, wọ́n sì lọ sì abúlé àdádó kan tó wà ní erékúṣù Palawan, ní nǹkan bí ọgọ́rin lé ní irínwó [480] kìlómítà ní apá gúúsù ìlú Manila.—Fílí. 3:8.

WỌ́N “KỌ́ ÀṢÍRÍ” BÉÈYÀN ṢE Ń NÍ ÌTẸ́LỌ́RÙN

Kí Gregorio àti ìyàwó rẹ̀, Marilou tó lọ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn. Àmọ́, wọn ò mọ bí àwọn nǹkan ṣe máa rí fún wọn tí wọ́n bá débẹ̀. Marilou sọ pé: “Ó yà wá lẹ́nu gan-an ni pé kò sí iná, kò sì sí àwọn nǹkan amáyédẹrùn kankan níbẹ̀. Dípò ohun èlò tó ń lo iná mànàmáná, èyí tá a fi ń se ìrẹsì, ńṣe la máa ń la igi tá a máa kó sínú ààrò láti dáná. Tẹ́lẹ̀ a máa ń lọ sílé ìtajà ńlá, àá jáde lọ jẹun, a sì máa ń gbádùn àwọn nǹkan míì tó wà nígboro. Ní báyìí, kò sí gbogbo ìyẹn mọ́.” Àmọ́ wọn ò yé rán ara wọn létí ìdí tí wọ́n fi lọ síbẹ̀, kò sì pẹ́ tí ibẹ̀ fi mọ́ wọn lára. Marilou wá sọ pé: “Mo ti wá ń gbádùn wíwo àwọn ohun àrà tí Ọlọ́run dá, títí kan àwọn ìràwọ̀ tó máa ń tàn lójú ọ̀run lálẹ́. Pabanbarì ẹ ni pé, inú mi máa ń dùn pé àwọn èèyàn máa ń láyọ̀ nígbà tá a bá wàásù fún wọn. Bí a ṣe ń sìn níbí ti jẹ́ ká ‘kọ́ àṣírí’ béèyàn ṣe ń ní ìtẹ́lọ́rùn.”—Fílí. 4:12.

“Kò sí ohun téèyàn lè fi wé ayọ̀ téèyàn máa ń rí bí àwọn ẹni tuntun bá wá sin Jèhófà. Ìsinsìnyí gan-an ni ìgbésí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”—Gregorio àti Marilou

Gregorio sọ pé: “Nígbà tá a débí, àwọn ará tá a bá ò ju mẹ́rin lọ. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọyé fún wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí mo sì ń lo gìtá mi nígbà tá a bá ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run.” Láàárín ọdún kan péré, tọkọtaya yìí rí bí àwùjọ kékeré yẹn ṣe gbèrú di ìjọ tó ní àkéde mẹ́rìnlélógún [24]. Gregorio sọ pé: “Bí àwọn ará yẹn ṣe ń fi ìfẹ́ hàn sí wa lónírúurú ọ̀nà wú wa lórí gan-an ni.” Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí wọ́n ti ń sìn ní ibi àdádó yẹn, wọ́n sọ pé: “Kò sí ohun téèyàn lè fi wé ayọ̀ téèyàn máa ń rí bí àwọn ẹni tuntun bá wá sin Jèhófà. A gbà pé ìsinsìnyí gan-an ni ìgbésí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

“MO TI ‘TỌ́ JÈHÓFÀ WÒ, MO SÌ TI RÍ I PÉ ẸNI RERE NI’!”

Ní orílẹ̀-èdè Philippines, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni wọ́n ti lọ sí àwọn àgbègbè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lára àwọn arábìnrin yẹn ni kò tíì lọ́kọ. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Karen tó jẹ́ ọ̀kan lára wọn.

Karen

Àgbègbè Baggao ní ìlú Cagayan ni wọ́n ti tọ́ Karen tó ti tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] báyìí dàgbà. Kò tíì pé ọmọ ogún ọdún tó ti máa ń wù ú pé kó ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ó sọ pé: “Torí pé àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù, àti pé onírúurú èèyàn ní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó máa ń wù mí láti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára ìdílé Karen gbà á níyànjú pé kó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga dípò táá fi lọ máa wàásù ní ibi àdádó, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. Ó tún bá àwọn tó ń sìn ní ibi àdádó sọ̀rọ̀. Nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], ó kó lọ sí ibi àdádó kan tó tó nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] sí ìlú rẹ̀.

Àwọn ará tó wà nínú ìjọ kékeré tí Karen lọ yẹn ni wọ́n máa ń lọ wàásù láwọn àgbègbè olókè ní Etí Òkun Pàsífíìkì. Karen sọ pé: “Nígbà tí mo máa lọ sí ìjọ tuntun yẹn, ìrìn ọjọ́ mẹ́ta gbáko la rìn láti Baggao ká tó débẹ̀. A gun àwọn òkè ńlá, a sì sọdá odò tó lé ní ọgbọ̀n [30] ká tó débẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Ìrìn wákàtí mẹ́fà gbáko ló máa ń gbà mí láti dé ọ̀dọ́ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi kan, lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́, màá wá sùn sí ilé wọ́n mọ́jú, tó bá sì di ọjọ́ kejì màá tún rin ìrìn wákàtí mẹ́fà pa dà sílé.” Àmọ́ ṣé àwọn ìsapá yẹn mérè wá? Karen sọ pé: “Nígbà míì, ṣe ni ẹsẹ̀ mi méjèèjì á máa ro mí.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀ríntẹ̀rín pé: “Mo ti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjìdínlógún [18] rí. Mo ti ‘tọ́ Jèhófà wò, mo sì ti rí i pé ẹni rere ni’!”—Sm. 34:8.

“MO RÍ I PÉ Ó YẸ KÍ N GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ”

Sukhi

Arábìnrin kan wà tó ń jẹ́ Sukhi, ó ti lé ní ogójì ọdún kò sì tíì lọ́kọ. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ń gbé kó tó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Philippines. Kí ló fà á tó fi kó lọ? Ní ọdún 2011, ó lọ sí àpéjọ àyíká kan níbi tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wá tọkọtaya kan lẹ́nu wò. Tọkọtaya náà sọ bí wọ́n ṣe ta èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ohun ìní wọn, tí wọ́n sì kó lọ sí orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò kí wọ́n lè lọ wàásù níbẹ̀. Sukhi sọ pé: “Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn àfojúsùn tí mi ò ronú nípa rẹ̀ rí.” Ọmọ bíbí ìlú Íńdíà ni Sukhi, nígbà tó gbọ́ pé wọ́n nílò àwọn tó máa lọ wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè Punjabi àmọ́ tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè Philippines, ó pinnu pé òun á lọ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ó dojú kọ ìṣòro kankan?

Sukhi sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti pinnu èyí tó yẹ kí n tà àtèyí tí kò yẹ kí n tà nínú àwọn ẹrù mi. Bákan náà, kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún mi láti máa gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn mi kan lẹ́yìn tí mo ti dá gbé nínú ilé ara mi fún ọdún mẹ́tàlá [13]. Àmọ́, ó jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun ìní tara.” Àwọn ìṣòro wo ló bá pàdé lẹ́yìn tó dé orílẹ̀-èdè Philippines? Ó sọ pé: “Àwọn ohun tó jẹ́ olórí ìṣòro mi ni pé mo máa ń bẹ̀rù àwọn kòkòrò gan-an, àárò ilé tún máa ń sọ mí. Mo rí i pé ó yẹ kí n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lákọ̀tun!” Àmọ́ ṣé àwọn ìsapá yẹn mérè wá? Pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ ni Sukhi fi sọ pé: “Jèhófà sọ fún wa pé, ‘Ẹ dán mi wò, bóyá èmi kì yóò tú ìbùkún dà sórí yín.’ Mo máa ń rí bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ yìí ṣe jẹ́ òótọ́ nígbà tí onílé kan bá béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Ìgbà wo lẹ tún máa pa dà wá? Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí mo fẹ́ bi yín.’ Inú mi máa ń dùn gan-an pé mo láǹfààní láti ran àwọn tí ebi tẹ̀mí ń pa lọ́wọ́!” (Mál. 3:10) Sukhi fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ká sòótọ́, ohun tó le jù ni pé kéèyàn pinnu pé òun máa lọ sìn níbòmíràn. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo ti gbéra, ó kàn ń yà mí lẹ́nu ni bí mo ṣe ń rí ọwọ́ Jèhófà lára mi nínú gbogbo ohun tí mò ń ṣe.”

“MI Ò JẸ́ KÍ ÌBẸ̀RÙ BORÍ MI”

Orílẹ̀-èdè Philippines ni Arákùnrin Sime àti ìyàwó rẹ̀ ń gbé, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogójì [40] ọdún báyìí, àmọ́ ó wá iṣẹ́ olówó gọbọi lọ sí orílẹ̀-èdè kan tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Ọ̀rọ̀ ìṣírí tí alábòójútó àyíká kan àti ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ mú kó fẹ́ láti fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Sime sọ pé: “Àmọ́, ẹ̀rù ń bà mí láti fi iṣẹ́ mi sílẹ̀.” Láìka ti ẹ̀rù tó ń bà á sí, ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ó sì pa dà sí orílẹ̀-èdè Philippines. Ní báyìí, Sime àti ìyàwó rẹ̀ Haidee ń sìn ní ìlú Davao del Sur tó wà ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè náà, níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ torí pé ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn tóbi gan-an. Sime sọ pé: “Tí mo bá ronú pa dà sẹ́yìn, inú mi máa ń dùn pé mi ò jẹ́ kí ìbẹ̀rù borí mi, mo fi iṣẹ́ mi sílẹ̀, mo sì fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́. Kò sí ohun tó tún lè fi èèyàn lọ́kàn balẹ̀ láyé yìí ju pé kéèyàn fi èyí tó dára jù lọ nínú àwọn ohun ìní rẹ̀ fún Jèhófà!”

Sime àti Haidee

“Ó MÚ KÍ ỌKÀN WA BALẸ̀ GAN-AN NI!”

Tọkọtaya ni Ramilo àti Juliet, wọ́n ti lé lọ́gbọ̀n ọdún, wọ́n sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ìjọ kan tó wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà sí ilé wọn nílò ìrànlọ́wọ́, wọ́n yọ̀ǹda ara wọn. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń lọ sí ìpàdé àti òde-ẹ̀rí, alùpùpù wọn ni wọ́n sì máa ń gbé lọ gbé bọ̀ láìka bójú ọjọ́ ṣe rí sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti máa gba àwọn ọ̀nà gbágungbàgun yẹn àtàwọn afárá alásorọ̀ kọjá, inú wọn dùn pé àwọn ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn. Ramilo sọ pé: “Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́kànlá [11] ni èmi àti ìyàwó mi ń darí! Kéèyàn máa sìn ní ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i gba pé kéèyàn yááfì àwọn nǹkan kan, àmọ́ ó mú kí ọkàn wá balẹ̀ gan-an ni!”—1 Kọ́r. 15:58.

Juliet àti Ramilo

Ṣé wàá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tó o lè ṣe tó o bá fẹ́ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè rẹ tàbí ní ilẹ̀ òkèèrè? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, bá alábòójútó àyíká yín sọ ọ́, kó o sì ka àpilẹ̀kọ náà, “Ǹjẹ́ O Lè ‘Ré Kọjá Lọ Sí Makedóníà’?” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù November, ọdún 2011.