Ìpinnu Tí Mo Ṣe Nígbà Tí Mo Wà ní Kékeré
Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mí lọ́dún 1985 nígbà tí àwọn ọmọdé kan ti orílẹ̀-èdè Cambodia wá sí iléèwé wa ní ìlú Columbus ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ tó wá yẹn gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì díẹ̀. Ó máa ń lo àwòrán láti sọ àwọn ìtàn ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ fún mi nípa bí wọ́n ṣe ń dá àwọn èèyàn lóró, bí wọ́n ṣe ń pa wọn àti bí àwọn kan ṣe ríbi sá. Alaalẹ́ ni mo máa ń sunkún tí mo bá ronú kan àwọn ọmọ náà. Ó wù mí kí n sọ fún wọn nípa Párádísè àti ìrètí àjíǹde, àmọ́ a ò gbédè ara wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré, mo pinnu pé màá kọ́ èdè Cambodian kí n bàa lè sọ nípa Jèhófà fáwọn ọmọléèwé mi. Àṣé ìpinnu tí mo ṣe yìí ń bọ̀ wá nípa lórí ọjọ́ ọ̀la mi!
Kò rọrùn láti kọ́ èdè Cambodian. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo pinnu pé mi ò ní kọ́ èdè náà mọ́, àmọ́ Jèhófà lo àwọn òbí mi láti fún mi níṣìírí. Nígbà tó ṣe, àwọn olùkọ́ mi àtàwọn tá a jọ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà mí níyànjú láti kọ́ ẹ̀kọ́ táá mú kí n ríṣẹ́ táá máa mówó gọbọi wọlé. Àmọ́, torí pé mo fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà, mo yan ẹ̀kọ́ táá mú kí n lè rí iṣẹ́ tí kò ní gba gbogbo àkókò mi táá sì jẹ́ kí ń lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Tá a bá ti jáde iléèwé, mo máa ń bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan jáde òde ẹ̀rí. Mo tún máa ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Èyí wá mú kí wọ́n gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní àfikún sí èdè ìbílẹ̀ wọn. Àǹfààní ńláǹlà lèyí sì jẹ́ fún mi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], mo gbọ́ pé ìjọ kékeré kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Cambodian wà ní ìlú Long Beach ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Mo lọ síbẹ̀, mo sì kọ́ bí wọ́n ṣe ń ka èdè Cambodian. Gbàrà tí mo parí iléèwé girama, mo di aṣáájú-ọ̀nà, mo sì ń bá a nìṣó láti máa wàásù fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Cambodia tí wọ́n wà nítòsí ilé tí mò ń gbé. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], mò ń ronú láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè Cambodia. Àmọ́ ó ṣì léwu láti lọ síbẹ̀ nígbà yẹn. Síbẹ̀ mo mọ̀ pé ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn èèyàn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá tó ń gbé ibẹ̀ ló tíì gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà yẹn sì rèé, ìjọ kan ṣoṣo ló wà ní orílẹ̀-èdè Cambodia, akéde wọn ò sì ju mẹ́tàlá [13] lọ. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sí orílẹ̀-èdè yẹn. Mo wá pinnu láti kó lọ síbẹ̀ pátápátá ní ọdún méjì lẹ́yìn náà. Nígbà tí mo débẹ̀, mo rí iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ èdè, mo sì tún ń kọ́ àwọn èèyàn lédè Gẹ̀ẹ́sì kí n lè fi máa gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó ṣe, mo fẹ́ arábìnrin kan tá a jọ ní àfojúsùn tẹ̀mí kan náà. Àwa méjèèjì gbádùn ríran ọ̀pọ̀ ọmọ ìbílẹ̀ Cambodia lọ́wọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
Jèhófà ti dáhùn ‘àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn mi wá.’ (Sm. 37:4) Kò sí iṣẹ́ tó lè fún èèyàn láyọ̀ láyé yìí bí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Mo ti lo ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ní orílẹ̀-èdè Cambodia, mo sì ti rí bí àwa mẹ́tàlá [13] tá a wà nínú àwùjọ kékeré yẹn ṣe gbèrú di ìjọ méjìlá àti àwùjọ àdádó mẹ́rin!—Gẹ́gẹ́ bí Jason Blackwell ṣe sọ ọ́.