Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ta Ni Jésù Kristi?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.
1. Ta ni Jésù Kristi?
Jésù kò dà bí àwọn èèyàn, ó ti gbé ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí kí wọ́n tó bí i sí ayé. (Jòhánù 8:23) Òun ni ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ó sì ṣèrànwọ́ nínú dídá ohun gbogbo yòókù. Òun nìkan ni Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ dá ní tààràtà, ìdí nìyẹn tó fi ń jẹ́ orúkọ náà, Ọmọ “bíbí kan ṣoṣo” Ọlọ́run. Jésù jẹ́ Agbọ̀rọ̀sọ Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tí ó tún fi ń jẹ́ orúkọ náà, “Ọ̀rọ̀.”—Jòhánù 1:1-3, 14; ka Òwe 8:22, 23, 30; Kólósè 1:15, 16.
2. Kí nìdí tí Jésù fi wá sí ayé?
Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ wá sí ayé nípa mímú ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ ní ọ̀run, ó sì fi í sí inú wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà. Nítorí náà, Jésù kò ní bàbá tó jẹ́ èèyàn. (Lúùkù 1:30-35) Jésù wá sí ayé (1) láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run, (2) láti fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àti (3) láti fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà.”—Ka Mátíù 20:28; Jòhánù 18:37.
3. Kí nìdí tá a fi nílò ìràpadà?
Ìràpadà jẹ́ iye téèyàn san láti dá ẹnì kan tàbí ohun kan sílẹ̀. Ikú àti ọjọ́ ogbó kì í ṣe ara ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ọlọ́run sọ fún Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ pé tó bá ṣàìgbọràn, èyí tí Bíbélì pè ní ẹ̀ṣẹ̀, yóò kú. Bí Ádámù kò bá dẹ́ṣẹ̀, kò ní kú láé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yìn ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀ ni ó kú, àmọ́ láti ọjọ́ náà gan-an tó ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 5:5) Ẹ̀ṣẹ̀ ni ogún tí Ádámù fi sílẹ̀ fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, ikú sì ni ìyọrísí rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ikú “wọ” inú ayé nípasẹ̀ Ádámù. Ìdí nìyẹn tá a fí nílò ìràpadà.—Ka Róòmù 5:12; 6:23.
4. Kí nìdí tí Jésù fi kú?
Ta ló máa san ìràpadà láti dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú? Nígbà tá a bá kú, ẹ̀ṣẹ̀ tiwa nìkan la jìyà rẹ̀. Kò sí èèyàn aláìpé tó lè ra èèyàn míì pa dà nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—Ka Sáàmù 49:7-9.
Jésù kò jogún àìpé nítorí bàbá tó jẹ́ èèyàn kọ́ ló bí i, kò ní ẹ̀ṣẹ̀, fún ìdí yìí, kò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, àmọ́ ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwa èèyàn. Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ láti wá kú nítorí wa, èyí sì jẹ́ ìfẹ́ àgbàyanu tí Ọlọ́run fi hàn fún aráyé. Jésù tún fi ìfẹ́ yìí hàn fún wa nípa ṣíṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ tó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa.—Ka Jòhánù 3:16; Róòmù 5:18, 19.
5. Kí ni Jésù ń ṣe nísinsìnyí?
Nígbà tí Jésù wo àwọn aláìsàn sàn, tó jí òkú dìde, tó sì tún gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ńṣe ló ń fi ohun tí yóò ṣe níkẹyìn fún aráyé onígbọràn hàn wá. (Lúùkù 18:35-42; Jòhánù 5:28, 29) Lẹ́yìn tí Jésù kú, Ọlọ́run jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí sí ọ̀run. (1 Pétérù 3:18) Jésù dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run títí dìgbà tí Jèhófà fún un ní agbára láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lé ayé lórí. (Hébérù 10:12, 13) Nísinsìnyí, Jésù ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé sì ń kéde ìhìn rere náà kárí ayé.—Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 24:14.
Láìpẹ́, Jésù yóò lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba láti fòpin sí gbogbo ìjìyà tó wà láyé àtàwọn tó ń fà á. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i yóò gbádùn ìyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Sáàmù 37:9-11.