Ìbéèrè Kìíní: Ìwọ Ọlọ́run, Kí Nìdí Tó O Fi Dá Mi Sáyé?
ILẸ̀ England ni wọ́n bí Rosalind sí, ó sì wù ú láti ní ìmọ̀ àti òye gan-an. Ó tún máa ń fẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Lẹ́yìn tó jáde ilé ìwé, ó ríṣẹ́ tó jẹ mọ́ kó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí kò rí ilé gbé, àwọn aláàbọ̀ ara àti àwọn tí kì í tètè mọ̀wé, iṣẹ́ yìí sì gbé e dépò ọlá. Pẹ̀lú bí Rosalind ṣe ní iṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́ yìí, tí ìyà owó ò sì jẹ ẹ́, síbẹ̀ ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń rò ó ṣáá pé, ‘Kí nìdí tá a fi wà láyé?’ àti pé ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run tiẹ̀ fi dá wa pàápàá?’”
Kí ló ń jẹ́ káwọn èèyàn béèrè irú ìbéèrè yìí?
Ìdí ni pé àwa èèyàn máa ń ronú, a kò dà bí àwọn ẹranko tí kì í ronú. A máa ń kọ́gbọ́n látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, a máa ń ronú ohun tí a máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, a sì máa ń fẹ́ ní ohun pàtàkì tí a ń fi ayé wa ṣe.
Kí ni àwọn kan sọ nípa ìbéèrè yìí?
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé gbogbo ohun tí a wá ṣe láyé kò ju pé ká ní ọrọ̀ tàbí ká lókìkí, pé tá a bá ti lè ní nǹkan wọ̀nyẹn a ó máa láyọ̀.
Irú ìwà wo ni ìdáhùn yìí ń fi hàn?
Òun ni pé ohun tó bá jẹ kálukú lógún láyé yìí ni kó gbájú mọ́. Ìfẹ́ ọkàn tiwa ló jà jù, ti Ọlọ́run kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì.
Kí ni Bíbélì fi kọ́ni?
Sólómọ́nì Ọba kó ọrọ̀ jọ rẹpẹtẹ, ó sì gbádùn ayé rẹ̀ dọ́ba, àmọ́ ó pa dà wá rí i pé nǹkan wọ̀nyẹn kọ́ ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé. Ó sọ ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kí èèyàn máa fi ayé rẹ̀ ṣe nígbà tó sọ pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” (Oníwàásù 12:13) Báwo ni èèyàn ṣe lè máa pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́?
Ara ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa ni pé ká gbádùn ara Oníwàásù 2:24.
wa. Kódà Sólómọ́nì sọ pé: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Èyí pẹ̀lú ni èmi ti rí, àní èmi, pé ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni èyí ti wá.”—Ọlọ́run tún fẹ́ ká fẹ́ràn àwọn tó wà nínú ìdílé wa, ká sì máa tọ́jú wọn. Wo ìtọ́ni tó wúlò, tó sì ṣe kedere tó fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé.
-
“Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.”—Éfésù 5:28.
-
“Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:33.
-
“Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín.”—Éfésù 6:1.
Tí a bá ń ṣe àwọn ohun tí Bíbélì sọ yẹn, a ó máa láyọ̀, ọkàn wa á sì balẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ ká fi ayé wa ṣe ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nípa Ẹlẹ́dàá wa, ká sì sún mọ́ ọn bí ọ̀rẹ́ wa àtàtà. Bíbélì pàápàá sọ fún wa pé ká “sún mọ́ Ọlọ́run.” Ó wá fi dá wa lójú pé Ọlọ́run “yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́, ìwọ fúnra rẹ máa rí i pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lò ń fi ìgbésí ayé rẹ ṣe yẹn.
Ní báyìí, Rosalind tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ti mọ ohun pàtàkì tó yẹ kí ó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Tó o bá lọ sí ojú ìwé 10 nínú ìwé ìròyìn yìí wàá rí ohun tó sọ pé ó jẹ́ kí òun mọ̀ ọ́n.