Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àlàáfíà Láàárín Àwọn Ẹni Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí

Àlàáfíà Láàárín Àwọn Ẹni Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí

“Ògo fún Ọlọ́run ní òkè ọ̀run tí ó ga jùlọ, àti alaafia ní ayé láàrin àwọn ẹni tí inú Ọlọ́run dùn sí.” —LÚÙKÙ 2:14, Ìròhìn Ayọ̀.

Ìdí tí àwọn kan fi ń ṣe ọdún Kérésìmesì.

Lọ́dọọdún, àwọn póòpù àti àwọn aṣáájú ìsìn máa ń wàásù nípa àlàáfíà. Wọ́n máa ń retí pé lásìkò ọdún Kérésì ohun tí áńgẹ́lì kan polongo máa ṣẹ. Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Alaafia ní ayé láàrin àwọn ẹni tí inú Ọlọ́run dùn sí.” Àwọn kan tiẹ̀ máa ń rin ìrìn àjò lọ sí àwọn ibi mímọ́ láti lọ ṣe ayẹyẹ Kérésì.

Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn?

Tí àlàáfíà bá wà lásìkò ọdún Kérésì, kì í sábà tọ́jọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní December 1914, nígbà tí ilẹ̀ Yúróòpù ń ja Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Jámánì jáde wá láti inú kòtò tí wọ́n ti ń bá ara wọn jagun, wọ́n jọ ṣe ọdún Kérésì pa pọ̀. Wọ́n jọ pín oúnjẹ àti nǹkan mímu, títí kan sìgá. Wọ́n tún jọ gbá bọ́ọ̀lù pa pọ̀. Ṣùgbọ́n, àdéhùn àlàáfíà yẹn kò pẹ́. Nígbà tí ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan kọ lẹ́tà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ogun, ó sọ pé lọ́jọ́ náà ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì kan sọ fún òun pé: “Lónìí àwa méjèèjì jọ wà ní àlàáfíà. Àmọ́ lọ́la a ó jọ wà á kò. Wàá jà fún orílẹ̀-èdè tìẹ; èmi náà á jà fún tèmi.”

Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè tọ́ni sọ́nà?

“A ti bí ọmọ kan fún wa . . . Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní . . . Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.” (Aísáyà 9:6, 7) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí nípa Jésù Kristi tuni nínú gan-an. Àmọ́ kì í ṣe torí pé kí Jésù lè máa mú kí àlàáfíà wà ní ọjọ́ kan ṣoṣo péré lọ́dọọdún ni wọ́n ṣe bí i sí ayé. Ṣe ni Jésù Ọba tí yóò máa ṣàkóso láti ọ̀run, yóò mú kí ojúlówó àlàáfíà tí kì yóò lópin wà lórí ilẹ̀ ayé.

“Ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi [Jésù]. Nínú ayé, ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33) Lónìí pàápàá, Jésù ń mú kí àlàáfíà wà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Lóòótọ́ o, àwọn Kristẹni náà máa ń ní ìpọ́njú. Ṣùgbọ́n Bíbélì ti jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí ìyà fi pọ̀ nínú ayé, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí Jésù yóò ṣe mú àlàáfíà tí kò lópin wá sínú ayé. Torí náà, ọkàn wọn máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pa ọ̀rọ̀ Jésù mọ́, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé láìka ti pé a wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí àwọ̀ ara wa yàtọ̀, tí ẹ̀yà wa yàtọ̀, tí èdè wa sì yàtọ̀ síra, àlàáfíà wà láàárín wa, ọkàn wa sì balẹ̀. Kí ìwọ náà lè fi ojú ara rẹ rí ohun tí a sọ yìí, o ò ṣe gbìyànjú kí o lọ sí ìpàdé tí a ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó jẹ́ ilé ìjọsìn wa. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà gbà pé àlàáfíà tí a ní láàárín wa dára ju àlàáfíà tó máa ń wáyé nígbà Kérésìmesì lọ.

Àlàáfíà wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìka ti pé àwọ̀ ara wa tàbí èdè wa yàtọ̀ síra. O lè fi ojú ara rẹ rí èyí tí o bá lọ sí ìpàdé tí a máa ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa