Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rò Pé Èèyàn Máa Ń Tún Ayé Wá?

Ǹjẹ́ O Rò Pé Èèyàn Máa Ń Tún Ayé Wá?

“Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn tó kú máa ń tún ayé wá, òótọ́ sì tún ni pé àwọn tó ti kú ni wọ́n tún ń bí sí ayé bí ọmọ tuntun àti pé ọkàn àwọn òkú kì í kú.”—PLATO, ỌMỌ ILẸ̀ GÍRÍÌSÌ KAN TÓ JẸ́ ONÍMỌ̀ ỌGBỌ́N ORÍ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KARÙN-ÚN ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI, LÓ ṢÀYỌLÒ Ọ̀RỌ̀ “SOCRATES” YÌÍ.

“Níwọ̀n bí ọkàn kò ti lè dá wà láìsí ara, tó sì jẹ́ pé òun gan-gan kọ́ ni ara ọ̀hún, inú onírúurú ara ló lè gbé, ó sì lè jáde kúrò nínú ara kan bọ́ sí òmíràn.”—GIORDANO BRUNO, ỌMỌ ILẸ̀ ÍTÁLÌ TÓ JẸ́ ONÍMỌ̀ ỌGBỌ́N ORÍ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KẸRÌNDÍNLÓGÚN SÀNMÁNÌ KRISTẸNI.

“Tí èèyàn bá kú, kì í ṣe pé ó kú tán pátápátá: ohun kan wà lára rẹ̀ tí kì í kú . . . Ṣe ni ohun tí kò kú yìí máa ń para dà, tí yóò sì gbé ara míì wọ̀, á wá máa wo gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwa aráyé bí ìgbà tí èèyàn ń wo ohun tó ń lọ níta láti ojú fèrèsé.”—RALPH WALDO EMERSON, ỌMỌ ILẸ̀ AMẸ́RÍKÀ TÓ MÁA Ń KỌ ÀRÒKỌ ÀTI EWÌ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KỌKÀNDÍNLÓGÚN SÀNMÁNÌ KRISTẸNI.

ǸJẸ́ o ti ronú nípa ẹni tí o jẹ́ gan-an rí? Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé èèyàn máa ń tún ayé wá? Àwọn kan náà máa ń rò bẹ́ẹ̀. Láti ayé àtijọ́ ni irú àwọn ìbéèrè yìí ti ń jà gùdù lọ́kàn àwọn èèyàn onírúurú ẹ̀yà káàkiri ayé. Ọ̀nà àtirí ìdáhùn sí ìbéèrè wọn ni wọ́n wá dé ìdí ẹ̀kọ́ àtúnwáyé. Ohun tí àwọn tó nígbàgbọ́ nínú àtúnwáyé sọ ni pé, tí ẹnì kan bá kú, ọkàn onítọ̀hún tí kò ṣeé fojú rí yóò jáde lára rẹ̀, yóò sì gbé ara míì wọ̀. Yóò wá pa dà wá sáyé, yálà ní àwọ̀ èèyàn tàbí ti ẹranko tàbí ewéko pàápàá. Wọ́n ní bí ọkàn yẹn yóò ṣe máa tún ayé wá láìmọye ìgbà nìyẹn.

Àlàyé tí àwọn wọ̀nyí ṣe nípa àtúnwáyé tẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́rùn, àmọ́ báwo la ṣe máa mọ̀ bóyá òótọ́ ni? Kí ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká wo ibi tí èrò yẹn ti bẹ̀rẹ̀.

Ibo Ni Ẹ̀kọ́ Àtúnwáyé Ti Bẹ̀rẹ̀?

Àwọn òpìtàn àti àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé àwọn ará ìlú Bábílónì ìgbàanì ló kọ́kọ́ gbà gbọ́ pé téèyàn bá kú, ohun kan tó jẹ́ ọkàn tí a ò lè fojú rí wà nínú èèyàn tí kì í kú, tó sì máa ń bá ìgbé ayé nìṣó. Wọ́n tẹ ìlú Bábílónì yìí dó ní èyí tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ọdún ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọ̀jọ̀gbọ́n Morris Jastrow Kékeré sọ nínú ìwé rẹ̀ kan pé: “Onírúurú èrò àti àbá ni àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní Bábílónì ń gbé kalẹ̀ ṣáá nípa àìleèkú ọkàn.” (The Religion of Babylonia and Assyria) Ó ṣàlàyé pé àwọn ará Bábílónì gbà pé “téèyàn bá kú, ṣe ló kàn fi ìgbé ayé tó wà sílẹ̀, tó sì bọ́ sí ìgbé ayé míì.” Ó wá ní: “Ó dájú pé àìfẹ́ gbà pé téèyàn bá ti kú gbogbo rẹ̀ ti parí síbẹ̀ náà nìyẹn, láìsí pé onítọ̀hún mọ nǹkan kan mọ́ láé, ló mú kí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní ìlú Bábílónì gbé àbá àìleèkú ọkàn kalẹ̀ láyé ìgbà yẹn.”

Bí ẹ̀kọ́ pé ọkàn kì í kú àti pé ṣe ló máa ń ṣípò pa dà látinú ara kan bọ́ sínú òmíràn, tó bẹ̀rẹ̀ ní Bábílónì ṣe di ohun tó gbilẹ̀ dé àwọn ibòmíì láyé ìgbà náà nìyẹn. Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ní ilẹ̀ Íńdíà sì wá gbé oríṣiríṣi ìlànà ẹ̀sìn kalẹ̀ nípa bí ọkàn ṣe máa ń ṣípò pa dà látinú ara kan bọ́ sínú òmíràn. Wọ́n gbé ìlànà wọn karí òfin àṣesílẹ̀ làbọ̀wábá, pé irú ìgbé ayé téèyàn bá gbé ló máa pinnu irú ara tó máa ní tó bá máa tún ayé wá. Bí àwọn gbajúmọ̀ onímọ̀ ọgbọ́n orí ní ilẹ̀ Gíríìsì sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ẹ̀kọ́ àtúnwáyé yìí lárugẹ, ó di èyí tó gbilẹ̀ láàárín àwọn èèyàn.

Láyé òde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ilẹ̀ Yúróòpù àti ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti Àríwá àti ti Gúúsù ti wá nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ àtúnwáyé gan-an. Àwọn èrò àti àṣà àwọn ẹ̀sìn ilẹ̀ Éṣíà ti wá gba àwọn gbajúgbajà èèyàn àti àwọn tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ dàgbà lọ́jọ́ orí lọ́kàn. Ọ̀pọ̀ ìwé àti ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì rẹpẹtẹ ló wà lóde òní, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn èèyàn gbà pé ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn nígbà ayé ìṣáájú tí wọ́n sọ pé àwọn ti gbé rí. Ní báyìí, àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sọ́dọ̀ àwọn kan tí wọ́n ní àwọn ń lo ìlànà ìtọ́jú kan tí wọ́n pè ní fífi ìmọ̀ nípa ìgbésí ayé ẹni nígbà ayé ìṣáájú tọ́jú ẹni. Àwọn tó dá a sílẹ̀ sọ pé àwọn máa ń lo ìlànà ìmúniníyè láti fi ṣe ìwádìí nípa ohun tí wọ́n pè ní ìgbé ayé ẹni nígbà ayé ìṣáájú, kí àwọn lè mọ ohun tó fa ipò ìlera rẹ̀ àti ìwà rẹ̀ láyé ìsinsìnyí.

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Èèyàn Máa Ń Tún Ayé Wá?

Lóòótọ́, ọjọ́ ti pẹ́ tí àwọn èèyàn ti ní ìgbàgbọ́ nínú àtúnwáyé, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì kéèyàn mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí: Ṣé èèyàn máa ń tún ayé wá lóòótọ́? Àwa Kristẹni máa fẹ́ mọ̀ bóyá ó bá ẹ̀kọ́ Bíbélì tí a gbà gbọ́ mu láti máa sọ pé èèyàn ń tún ayé wá. (Jòhánù 17:17) Jèhófà Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa ló dá gbogbo ohun alààyè, òun sì ni “Olùṣí àwọn àṣírí payá,” ó sì ti sọ àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìyè àti ikú, èyí tó jẹ́ pé ọmọ aráyé ì bá má lè mọ̀ rárá. Ó dájú pé tí a bá wo inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a ó rí ìdáhùn ìbéèrè tí a bá ní nípa ìwàláàyè àti ikú.—Dáníẹ́lì 2:28; Ìṣe 17:28.

Tí a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Bíbélì a ó rí ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tí èèyàn bá kú. Bí àpẹẹrẹ, nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:19 a rí ohun tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí i. Ọlọ́run sọ pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” Ekuru ilẹ̀ ni Ọlọ́run fi dá Ádámù. Nígbà tó sì kú, inú ilẹ̀ ló pa dà sí. Ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere tí Ọlọ́run sọ lórí kókó yìí nìyẹn. Torí náà, téèyàn bá kú, kì í tún pa dà wá sáyé mọ́ kí wọ́n tún un bí, ńṣe ni onítọ̀hún kò sí mọ́ rárá. * Bí ohun gbígbóná ṣe jẹ́ òdì kejì ohun tútù, tí ìmọ́lẹ̀ sì jẹ́ òdì kejì òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe jẹ́ òdì kejì ìyè. Àwọn òkú ti kú fin-ín fin-ín, wọn ò sí láàyè níbì kankan! Kò sí ohun tó lọ́jú pọ̀ rárá nínú ìyẹn, ó sì bọ́gbọ́n mu.

A jẹ́ pé nǹkan míì ló máa fà á tí àwọn kan fi ń rò pé àwọn ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn nígbà ayé tí àwọn ti gbé rí. Ohun kan ni pé àwa èèyàn kò tíì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa gbogbo bí ọpọlọ èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́, títí kan ìgbà tí ọpọlọ wa máa ń dá ṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀ láìjẹ́ pé a fọkàn sí i. A ò tíì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa bí àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tí a ń gbà àti bí ìdààmú tó ń bá wa ṣe máa ń nípa lórí wa. Ọpọlọ wa máa ń kó ọ̀kẹ́ àìmọye ìsọfúnni tí a ń gbọ́ àti èyí tí a ń fojú rí pa mọ́. Tí ọpọlọ wa bá ti wá mú kí á fi òmíràn lára wọn lá àlá, tàbí kí á bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa wọn, kí á máa fojú inú yàwòrán wọn bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́, nǹkan wọ̀nyẹn lé ṣe kedere lọ́kàn wa débi tó fi máa dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Láwọn ìgbà míì, àwọn ẹ̀mí èṣù lè lo agbára wọn láti fi gbé àwọn nǹkan tó jẹ́ irọ́ yọ lọ́nà tó fi máa dà bí òótọ́ lójú wa.—1 Sámúẹ́lì 28:7-19.

Ìfẹ́ ọkàn àwa èèyàn ni pé ká máa wà láàyè nìṣó, a sì máa ń fẹ́ mọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí. Ṣùgbọ́n kí ló jẹ́ ká fẹ́ máa wà láàyè nìṣó? Ṣé ẹ rí i, ohun tí Bíbélì sọ nípa Ẹlẹ́dàá wa ni pé: “Ó fi ayérayé sí wọn ní ọkàn.” (Oníwàásù 3:11, Bíbélì Mímọ́) Ohun tó fà á nìyẹn tó fi jẹ́ pé ṣe ni àwa èèyàn máa ń fẹ́ wà láàyè títí lọ gbére.

Níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa ti gbìn ín sí àwa èèyàn lọ́kàn pé ká fẹ́ láti wà láàyè títí láé, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé yóò jẹ́ ká mọ ohun tí a máa ṣe tí a ó fi lè máa wà láàyè nìṣó. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa ní in lọ́kàn láti fi ìyè ayérayé jíǹkí àwọn èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn, tí wọn yóò máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run mí sí Dáfídì Ọba láti kọ ọ́ sínú ìwé Sáàmù pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Àjíǹde àwọn òkú jẹ́ ara ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ inú Bíbélì, ó sì wé mọ́ ètè ayérayé tí Ọlọ́run ní.—Ìṣe 24:15; 1 Kọ́ríńtì 15:16-19.

Àjíǹde Ni Ìrètí Dídájú Tó Wà fún Àwọn Òkú

Bíbélì sọ fún wa nípa àjíǹde oríṣi mẹ́jọ tí àwọn èèyàn fojú rí pé ó ṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé. * Ṣe ni àwọn yẹn jíǹde o, èyí yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀rọ̀ ti pé àwọn èèyàn kan pa dà tún ayé wá. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni tẹbí-tọ̀rẹ́ àwọn òkú tí wọ́n jí dìde yìí sì dá wọn mọ̀ pé èèyàn wọn tó ti kú náà ni. Kò sí ìkankan nínú wọn tó jẹ́ pé ṣe ni àwọn ẹbí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò káàkiri láàárín àwọn ọmọ jòjòló tó wà nítòsí tàbí lọ́nà jíjìn láti fi mọ̀ bóyá ọkàn ẹni tó kú náà ti para dà di ọ̀kan lára àwọn ìkókó tí wọ́n bí.—Jòhánù 11:43-45.

Bíbélì sọ ohun kan tó tuni nínú pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ti kú ni yóò jíǹde nígbà àjíǹde àwọn òkú nínú ayé tuntun Ọlọ́run tó máa tó rọ́pò ayé burúkú tí a ń gbé yìí. (2 Pétérù 3:13, 14) Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run ń fi gbogbo bí àwọn ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti ń gbé láyé yìí ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn sọ́kàn. Kò sì lè gbàgbé èyíkéyìí lára wọn torí agbára ìrántí rẹ̀ kò ní ààlà. Kódà Bíbélì sọ pé ó máa ń rántí orúkọ gbogbo ìràwọ̀ ojú ọ̀run pátá! (Sáàmù 147:4; Ìṣípayá 20:13) Nígbà tó bá ń jí àwọn òkú dìde ní ìran-ìran wọn, kálukú á wá mọ gbogbo àtìrandíran rẹ̀. Áà, ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà máa jẹ́!

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 6 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àkòrí rẹ̀ ni “Ibo Làwọn Òkú Wà?” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ Àkọsílẹ̀ oríṣi àjíǹde mẹ́jọ náà wà nínú 1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37; 13:20, 21; Lúùkù 7:11-17; 8:40-56; Jòhánù 11:38-44; Ìṣe 9:36-42; 20:7-12. Bí ó ṣe ń ka àwọn ìtàn yìí, kíyè sí bó ṣe jẹ́ pé ìṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn ni àwọn àjíǹde náà ti wáyé. Ìtàn àjíǹde kẹsàn-án ni ti Jésù Kristi.—Jòhánù 20:1-18.