Ohun Ti Bibeli So
Ǹjẹ́ gbogbo ayé lè wà lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo?
Fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí tí gbogbo ayé bá wà lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo. Inú ayé tí ìyà ti ń jẹ́ àwọn tálákà, táwọn olówó sì ń gbádùn lọ ràì là ń gbé. Àmọ́ tí gbogbo ayé bá wà lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo tó fẹ́ràn àwọn aráàlú, ńṣe ni gbogbo èèyàn máa ní ohun tí wọ́n ń fẹ́. Ǹjẹ́ o rò pé àwa èèyàn lè pawọ́pọ̀ ṣètò irú ìjọba bẹ́ẹ̀?—Ka Jeremáyà 10:23.
Ká sòótọ́, ìjákulẹ̀ ló ti gbẹ̀yìn gbogbo ìjọba táráyé gbé kalẹ̀. Wọn ò rí tàwọn mẹ̀kúnnù rò rárá, kódà àwọn ìjọba kan tiẹ̀ máa ń dìídì ni àwọn èèyàn lára. (Oníwàásù 4:1; 8:9) Àmọ́, Ọlọ́run Olódùmarè ṣèlérí fún wa pé òun máa fi ìjọba kan rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn. Ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọba tí òun ti yàn máa tọ́jú wa dáadáa.—Ka Aísáyà 11:4; Dáníẹ́lì 2:44.
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa gbé ṣe?
Jèhófà Ọlọ́run ti yan ẹni tó tóótun láti ṣàkóso ayé yìí, ẹni náà ni Jésù Ọmọ rẹ̀. (Lúùkù 1:31-33) Jésù ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso lóòótọ́ torí pé nígbà tó wà láyé, ó fẹ́ràn àtimáa rán àwọn èèyàn lọ́wọ́. Láìpẹ́, Jésù máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ́ wa, á sì mú kí gbogbo ayé wà ní ìṣọ̀kan.—Ka Sáàmù 72:8, 12-14.
Ṣé gbogbo èèyàn ló ti gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Alákòóso wọn? Rárá o. Àmọ́, Jèhófà ṣì ń mú sùúrù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. (2 Pétérù 3:9) Ó fẹ́ kí wọ́n tún èrò wọn pa, kí wọ́n sì gba Jésù ni alákòóso tàbí adarí. Torí pé láìpẹ́, Jésù máa pa àwọn èèyàn burúkú run, á sì mú kí àlàáfíà gbilẹ̀ kárí ayé.—Ka Míkà 4:3, 4.