Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká 2019-2020​—Tí Alábòójútó Àyíká Máa Bá Wa Ṣe

Wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká yìí, kó o sì máa fọkàn bá a lọ. Àkòrí àpéjọ yìí ni “Ìfẹ́ Ń Gbéni Ró.”

“Ìfẹ́ Ń Gbéni Ró”

Ìpàdé yìí máa jẹ́ ká mọ ìdí tí ìfẹ́ fi ṣe pàtàkì ju ìmọ̀ lọ àti bá a ṣe lè fi ìfẹ́ ṣe gbogbo ohun tá à ń ṣe.

Wá Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Yìí

A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nígbà tí àpéjọ náà bá ń lọ lọ́wọ́.