APÁ KẸTA
Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Yanjú Ìṣòro
“Ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”
Onírúurú ìṣòro ló máa ń yọjú bí tọkọtaya bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọ gbé. Ó lè jẹ́ nítorí ìyàtọ̀ tó wà nínú bí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ṣe ń ronú, bí nǹkan ṣe ń rí lára yín tàbí ọ̀nà tí ẹ ń gbà ṣe nǹkan. Àwọn ẹlòmíì tàbí ohun kan tí ẹ kò rò tẹ́lẹ̀ sì tún lè fa ìṣòro.
Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o má ṣe sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà, àmọ́ Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe gbójú fo ìṣòro wa. (Mátíù 5:
1 Ẹ JỌ SỌ̀RỌ̀ NÍPA ÌṢÒRO NÁÀ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: ‘Ìgbà sísọ̀rọ̀ wà.’ (Oníwàásù 3:
Kódà, bí o kò bá fara mọ́ èrò ẹnì kejì rẹ, má ṣe sọ̀rọ̀ tí kò dáa. Máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ, kí o sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (Kólósè 4:6) Ẹ tètè máa yanjú ọ̀rọ̀ tó bá yọjú, ẹ má sì ṣe bára yín yodì.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Wá àyè sígbà tó máa rọrùn fún ẹ̀yin méjèèjì láti jọ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà
-
Fetí sílẹ̀, má ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọkọ tàbí aya rẹ lẹ́nu nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́. Ìwọ náà ṣì máa sọ tìẹ
2 FETÍ SÍLẸ̀ KÍ O SÌ LÓYE Ọ̀RỌ̀ NÁÀ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Bí o ṣe ń fetí sílẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Gbìyànjú láti mọ èrò ẹnì kejì rẹ, kí o lo ‘ojú àánú àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.’ (1 Pétérù 3:8; Jákọ́bù 1:
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Rí i dájú pé ò ń fọkàn sí ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ bá ń sọ, kódà bí ohun tí ò ń gbọ́ kò bá tẹ́ ọ lọ́rùn
-
Ohun tó ní lọ́kàn gan-an ni kí o fọkàn sí, kì í wulẹ̀ ṣe bó ṣe sọ̀rọ̀. Máa kíyè sí ohùn rẹ̀, ìṣesí rẹ̀ àti ìrísí ojú rẹ̀
3 Ẹ MÁA ṢIṢẸ́ LÓRÍ OHUN TÍ Ẹ JỌ SỌ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Nípasẹ̀ onírúurú làálàá gbogbo ni àǹfààní fi máa ń wà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ [ẹnu] lásán-làsàn máa ń [já] sí àìní.” (Òwe 14:23) Ẹ má wulẹ̀ fi ọ̀rọ̀ mọ sí wíwá ojútùú nìkan. Ó yẹ kí ẹ máa ṣiṣẹ́ lórí ohun tí ẹ bá jọ pinnu. Èyí lè gba pé kí ẹ ṣiṣẹ́ kára, kí ẹ sì sapá gan-an, àmọ́ ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Òwe 10:4) Tí ẹ bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ohun gbogbo, ẹ máa “ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára” yín.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Ẹ pinnu ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín máa ṣe kí ẹ lè yanjú ìṣòro náà
-
Ẹ máa ṣàyẹ̀wò àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe látìgbàdégbà