Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ KÌÍNÍ

Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ràn Yín Lọ́wọ́ Kí Ẹ Lè Jẹ́ Tọkọtaya Aláyọ̀

Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ràn Yín Lọ́wọ́ Kí Ẹ Lè Jẹ́ Tọkọtaya Aláyọ̀

“Ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo.”Mátíù 19:4

Jèhófà * Ọlọ́run ló so tọkọtaya àkọ́kọ́ pọ̀. Bíbélì sọ fún wa pé nígbà tí Ọlọ́run dá obìnrin àkọ́kọ́, ó “mú un wá fún ọkùnrin náà.” Inú Ádámù dùn gan-an tó fi sọ pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:22, 23) Jèhófà ṣì fẹ́ kí inú àwọn tọkọtaya máa dùn.

Nígbà tí o ṣègbéyàwó, o lè ronú pé kò ní sí ìṣòro kankan. Ká sòótọ́, àwọn tọkọtaya tó fẹ́ràn ara wọn dénú pàápàá máa ń ní ìṣòro tiwọn. (1 Kọ́ríńtì 7:28) Tí o bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tó wà nínú ìwé yìí, ó máa jẹ́ kí ìdílé rẹ ní ayọ̀.Sáàmù 19:8-11.

1 MÁA ṢE OJÚṢE TÍ JÈHÓFÀ GBÉ LÉ Ọ LỌ́WỌ́

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Ọkọ ni olórí ìdílé.Éfésù 5:23.

Tí o bá jẹ́ ọkọ, Jèhófà retí pé kí o máa ṣìkẹ́ aya rẹ. (1 ­Pétérù 3:7) Olùrànlọ́wọ́ ni Jèhófà fi aya rẹ ṣe fún ọ, ó sì fẹ́ kí o máa buyì kún un kí o sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) O gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ débi pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní láti jẹ ọ́ lógún ju ti ara rẹ lọ.Éfésù 5:25-29.

Tí o bá jẹ́ aya, Jèhófà retí pé kí o máa bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ, kí o sì máa ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣe ojúṣe rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:33) Máa kọ́wọ́ ti ìpinnu tó bá ṣe, kí o sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ tinútinú. (Kólósè 3:18) Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o máa rẹwà lójú ọkọ rẹ àti lójú Jèhófà.1 Pétérù 3:1-6.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Béèrè ohun tí o lè ṣe lọ́wọ́ ọkọ tàbí aya rẹ kí o lè túbọ̀ jẹ́ ọkọ rere tàbí aya àtàtà. Fetí sílẹ̀ dáadáa, kí o sì ṣe ohun tí o bá lè ṣe láti sunwọ̀n sí i

  • Ní sùúrù. Ó máa pẹ́ díẹ̀ kí ẹ̀yin méjèèjì tó mọ ohun tí ẹ lè máa ṣe láti mú inú ara yín dùn

2 MÁA KA Ọ̀RỌ̀ ẸNÌ KEJÌ RẸ SÍ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ máa jẹ ọ́ lógún. (Fílípì 2:3, 4) Máa fi hàn pé ọkọ tàbí aya rẹ ṣeyebíye lójú rẹ, kí o máa rántí pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ “ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.” (2 Tímótì 2:24) ‘Sísọ̀rọ̀ láìronú dà bí idà tí ń gúnni, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n, ìlera ni.’ Torí náà, máa fara balẹ̀ ronú kí o tó sọ̀rọ̀. (Òwe 12:18, Bíbélì Mímọ́) Ẹ̀mí Jèhófà yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí inúure àti ìfẹ́ lè máa hàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ.Gálátíà 5:22, 23; Kólósè 4:6.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè máa fara balẹ̀ kí o sì lè máa ronú bó ṣe yẹ nígbà tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan pàtàkì

  • Máa ronú dáadáa nípa ohun tí o fẹ́ sọ àti bí o ṣe fẹ́ sọ ọ́

3 Ẹ JỌ MÁA RONÚ OHUN TÍ Ẹ FẸ́ ṢE

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Tí o bá ti ṣe ìgbéyàwó, o ti di “ara kan” náà pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ nìyẹn. (Mátíù 19:5) Àmọ́ ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹ ṣì jẹ́, ìrònú yín sì lè yàtọ̀ síra. Torí náà ó yẹ kí ẹ kọ́ bí ẹ ó ṣe máa jẹ́ kí ìrònú yín ṣọ̀kan títí kan bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára yín. (Fílípì 2:2) Ó ṣe pàtàkì pé kí èrò yín máa ṣọ̀kan nígbà tí ẹ bá ń ṣe ìpinnu. Bíbélì sọ pé: “Ìmọ̀ràn ni a fi ń fìdí àwọn ìwéwèé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Òwe 20:18) Ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tí ẹ bá jọ ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì.Òwe 8:32, 33.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Máa jẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ, kì í kàn ṣe ohun tí o fẹ́ ṣe tàbí èrò rẹ

  • Máa fi ọ̀rọ̀ lọ ọkọ tàbí aya rẹ kí o tó ṣàdéhùn

^ ìpínrọ̀ 4 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.