Ẹ̀KỌ́ 17
Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Àyíká Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa Bánábà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, wọ́n sì ń bẹ àwọn ìjọ wò nígbà yẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ àwọn ará tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run jẹ wọ́n lógún gan-an. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun fẹ́ “pa dà lọ bẹ àwọn ará wò” kí òun lè rí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí. Ó múra tán láti rin ìrìn àjò ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà kó lè lọ fún wọn ní ìṣírí. (Ìṣe 15:36) Ohun kan náà tí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò wa ń ṣe lónìí nìyẹn.
Wọ́n ń bẹ̀ wá wò kí wọ́n lè fún wa níṣìírí. Alábòójútó àyíká máa ń bẹ nǹkan bí ogún (20) ìjọ wò, ó sì máa ń lo ọ̀sẹ̀ kan ní ìjọ kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ látinú ìrírí àwọn arákùnrin yìí àti ti ìyàwó wọn, tí wọ́n bá ní ìyàwó. Wọ́n máa ń sapá láti mọ tèwe tàgbà, a jọ máa ń lọ wàásù, a sì jọ máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn alábòójútó yìí àtàwọn alàgbà jọ máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n sì máa ń sọ àwọn àsọyé tó ń gbéni ró láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.—Ìṣe 15:35.
Wọ́n ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn. Àwọn alábòójútó àyíká máa ń wá bí ìjọ ṣe máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ṣàyẹ̀wò bí ìjọ ṣe ń ṣe dáadáa sí, wọ́n sì máa ń fún wọn ní ìmọ̀ràn tó wúlò lórí bí wọ́n ṣe lè bójú tó iṣẹ́ wọn. Wọ́n máa ń ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣeyọrí, wọ́n tún máa ń fẹ́ mọ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé àti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí ló ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú, “a sì jọ ń ṣiṣẹ́ fún ire [wa].” (2 Kọ́ríńtì 8:23) Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsin wọn sí Ọlọ́run.—Hébérù 13:7.
-
Kí nìdí tí àwọn alábòójútó àyíká fi máa ń bẹ àwọn ìjọ wò?
-
Kí lo lè ṣe láti jàǹfààní látinú ìbẹ̀wò wọn?